Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Àwọn Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Lágbára?

Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Àwọn Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Lágbára?

 Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ ìmìtìtì ilẹ̀ ló ń wáyé kárí ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ le, àwọn kan máa ń fa jàǹbá, ìyà àti ikú fáwọn èèyàn. Láwọn ìgbà míì, ó máa ń fa àkúnya omi láwọn agbègbè tó wà létí òkun, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé nírú agbègbè bẹ́ẹ̀ ló sì ti pàdánù ẹ̀mí wọn. Ṣé Bíbélì tiẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé irú àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára bẹ́ẹ̀ máa wáyé?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí

 Ṣé Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmìtìtì ilẹ̀?

 Nínú Bíbélì, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ìmìtìtì ilẹ̀ wà lára àwọn nǹkan tá a máa ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí. Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn wà nínú ìwé Bíbélì mẹ́ta tó tẹ̀le yìí:

 “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ àti ìmìtìtì ilẹ̀ sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.”​—Mátíù 24:7.

 “Orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba; ìmìtìtì ilẹ̀ máa wà láti ibì kan dé ibòmíì; àìtó oúnjẹ náà máa wà.”​—Máàkù 13:8.

 Ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára máa wáyé, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.”​—Lúùkù 21:11.

 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé “ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára” máa wáyé “láti ibì kan dé ibòmíì” lásìkò kan náà tí ogun, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn bá ń ṣẹlẹ̀. Ńṣe làwọn nǹkan yìí jẹ́ àmì pé a ti wà ní àkókò kan tí Bíbélì pè ní “ìparí ètò àwọn nǹkan,” tàbí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (Mátíù 24:3; 2 Tímótì 3:1) Àwọn ìṣirò tá a ṣe látinú Bíbélì fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914, kò sì tíì dópin.

 Ṣé àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń wáyè lónìí mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn nǹkan tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé á máa ṣẹlẹ̀ títí kan èyí tó sọ nípa ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń wáyé lónìí. Látọdún 1914, àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méjì (1,950), èyí sì ti yọrí sí ikú àwọn èèyàn tó ju mílíọ̀nù méjì lọ. a Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí.

 2004​—Òkun Íńdíà. Ìmìtìtì ilẹ̀ tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 9.1 fa àkúnya omi tó dé orílè-èdè méjìlá, nǹkan bí ẹgbèrún lọ́nà igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ( 225,000) èèyàn ló sì kú.

 2008​—Ṣáínà. Ìmìtìtì ilẹ̀ tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 7.9 ba àwọn abúlé àti ìlú jẹ́ ní ilẹ̀ Ṣáínà, wọ́n sì fojú bù ú pé ó ṣeé ṣé kó jẹ́ pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn-ún (90,000) èèyàn ni àjálù náà pa, àwọn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé márùndínlọ́gọ́rin (375,000) ló fara pa, ó sì sọ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù di aláìnílé.

 2010​—Haiti. Ìmìtìtì ilẹ̀ tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 7.0 àtàwọn tó ṣẹlẹ̀ tẹ̀ le pa àwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000), ó sì sọ àwọn tó ju mílíọ̀nù kan di aláìnílé.

 2011​—Japan. Ìmìtìtì ilẹ̀ tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 9.0 àti àkúnya omi tó fà pa àwọn èèyàn tó ṣeé ṣe kó tó ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (18,500), ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló sì di aláìnílé. Àjálù yẹn ba iléeṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná tó ń lo agbára átọ́míìkì jẹ́ ní ìlú Fukushima, ó si mú kí afẹ́fẹ́ olóró tú jáde. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì èèyàn (40,000) ni kò tíì lè pa dà sí ilé wọn torí bí afẹ́fẹ́ olóró tó tú jáde nígbà yẹn ṣe lágbára tó.

 Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ìmìtìtì ilẹ̀ ṣe kàn wá?

 Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa ìmìtìtì ilẹ̀ jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Torí Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá rí i tí àwọn nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé.”​—Lúùkù 21:31.

 Bíbélì sọ pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba gidi kan táá máa ṣàkóso láti ọ̀run. Jésù Kristi ló máa jẹ́ Ọba ìjọba náà, ìjọba yìí sì ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún.​—Mátíù 6:10.

 Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso ayé, Ọlọ́run máa fòpin sí àwọn àjálù tó ń fa jàǹbá fáwa èèyàn títí kan ìmìtìtì ilẹ̀. (Àìsáyà 32:18) Bákan náà, ó má a mú ẹ̀dùn ọkàn àti aburu tí ìmìtìtì ilẹ̀ náà ti fà fáwọn èèyàn kúrò. (Àìsáyà 65:17; Ìfihàn 21:3, 4) Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Ṣe?

a A rí àwọn ìsọfúnni yìí gbà láti ọwọ́ Global Significant Earthquake Database tí àjọ United States National Geophysical Data Center ń bójú tó.