Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní, àmọ́ ọ̀rọ̀ àwọn tó ń ṣẹlẹ̀ sí máa ń ká Ọlọ́run lára. Àjálù wà lára àwọn ohun tó ń fìyà jẹ àwa èèyàn, tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú kúrò. Àmọ́ ní báyìí ná, Ọlọ́run ń tu àwọn tí àjálù ń ṣẹlẹ̀ sí nínú.​—2 Kọ́ríńtì 1:3.

 Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fi àwọn àjálù jẹ wá níyà?

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé láyé àtijọ́, Ọlọ́run ti lo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá láti ṣèdájọ́ àwọn olubi, àmọ́ ìyẹn yàtọ̀ sí àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní.

  •   Ẹnikẹ́ni làwọn àjálù lè pa tàbí kó sọ di aláàbọ̀ ara. Nígbà àtijọ́ tí Ọlọ́run lo ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá láti ṣèdájọ́, Bíbélì sọ pé àwọn ẹni burúkú nìkan ló pa run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọlọ́run pa ìlú Sódómù àti Gòmórà àtijọ́ run, ó dá Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ ẹni rere sí àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì. (Jẹ́nẹ́sísì 19:29, 30) Ọlọ́run rí ọkàn àwọn tó ń gbé láyé nígbà yẹn, torí ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé àwọn èèyàn burúkú nìkan ló pa run.​—Jẹ́nẹ́sísì 18:23-​32; 1 Sámúẹ́lì 16:7.

  •   Tí àjálù bá fẹ́ ṣẹlẹ̀, kì í sábà fu àwọn èèyàn lára. Nígbà tí Ọlọ́run fi ìṣẹ̀lẹ̀ àdáyébá ṣèdájọ́, ó kọ́kọ́ kìlọ̀ fáwọn ẹni burúkú kó tó pa wọ́n run. Àwọn tó gbọ́ ìkìlọ̀ nínú wọn ráyè mórí bọ́.​—Jẹ́nẹ́sísì 7:1-5; Mátíù 24:38, 39.

  •   Déwọ̀n àyè kan, àfọwọ́fà àwọn èèyàn ló máa ń fa àjálù. Lọ́nà wo? Àwọn èèyàn ń ba àyíká jẹ́, wọ́n ń kọ́lé síbi tí ilẹ̀ ti lè mì tìtì, wọ́n ń kọ́lé sétí omi àtàwọn ibòmíì tí ojú ọjọ́ ibẹ̀ ò dáa. (Ìfihàn 11:18) Ọlọ́run kọ́ la máa dá lẹ́bi tí ohun táwọn èèyàn yàn bá bẹ́yìn yọ, tó sì fa àjálù.​—Òwe 19:3.

 Ṣé àwọn àjálù wà lára àmì ọjọ́ ìkẹyìn?

 Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn àjálù á máa ṣẹlẹ̀ ní “ìparí ètò àwọn nǹkan,” tàbí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (Mátíù 24:3; 2 Tímótì 3:1) Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ nípa àkókò wa yìí pé: “Àìtó oúnjẹ àti ìmìtìtì ilẹ̀ sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.” (Mátíù 24:7) Láìpẹ́, Ọlọ́run máa fòpin sí gbogbo ohun tó ń fa ìrora àti ìyà láyé, títí kan àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀.​—Ìfihàn 21:3, 4.

 Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń ran àwọn tí àjálù ń ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́?

  •   Ọlọ́run ń fi Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ràn wọ́n lọ́wọ́. Bíbélì fi dá wa lójú pé ọ̀rọ̀ wa ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run, inú ẹ̀ kì í sì í dùn tá a bá ń jìyà. (Àìsáyà 63:9; 1 Pétérù 5:6, 7) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ṣèlérí ìgbà kan tí àjálù ò ní wáyé mọ́.​—Wo “ Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó lè tu àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí nínú.”

  •   Ọlọ́run máa ń lo àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ láti ran àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́. Ọlọ́run máa ń mú kí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tó wà láyé tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa tu “àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn” nínú pẹ̀lú “gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀.” (Àìsáyà 61:1, 2) Àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run náà máa ń sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀.​—Jòhánù 13:15.

     Ọlọ́run tún máa ń lo àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ láti pèsè oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí.​—Ìṣe 11:28-30; Gálátíà 6:10.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ìjì líle ṣèpalára fún ní Puerto Rico

 Ṣé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de àjálù?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe torí àtilè múra wa sílẹ̀ de àjálù ni Bíbélì ṣe wà, síbẹ̀, àwọn ìlànà tó wà nínú ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ:

  •   Múra ohun tó o máa ṣe sílẹ̀ ká sọ pé àjálù ṣẹlẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́.” (Òwe 22:3) Ìwà ọgbọ́n la hù tá a bá ti múra ohun tá a máa ṣe sílẹ̀ ṣáájú kí àjálù tó dé. Irú ìmúra bẹ́ẹ̀ lè gba pé ká ti di báàgì kan tó ní oríṣiríṣi ohun ìgbẹ̀mílà sílẹ̀, tá a kàn máa gbé tí ọ̀rọ̀ pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀, tàbí kí àwa àti ìdílé wa ti jọ sọ ọ́ pé ibi báyìí báyìí la ti máa pàdé tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.

  •   Gbà pé ẹ̀mí ṣe pàtàkì ju ohun ìní lọ. Bíbélì sọ pé: “A ò mú nǹkan kan wá sí ayé, a ò sì lè mú ohunkóhun jáde.” (1 Tímótì 6:7, 8) Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ó yẹ ká múra tán láti filé fọ̀nà wa sílẹ̀ ká lè sá fún ẹ̀mí wa. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ẹ̀mí wa ṣe pàtàkì ju ohun ìní èyíkéyìí lọ.​—Mátíù 6:25.