Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Tí Wíwo Ohun Tó Ń Mú Ọkàn Èèyàn Fà sí Ìṣekúṣe Bá Ti Mọ́ Mi Lára Ńkọ́?

Tí Wíwo Ohun Tó Ń Mú Ọkàn Èèyàn Fà sí Ìṣekúṣe Bá Ti Mọ́ Mi Lára Ńkọ́?

Ohun tó o lè ṣe

 Ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe kò dára. Ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe ń tàbùkù ohun tí Ọlọ́run dá lọ́nà iyì. Tó bá yé ẹ pé bí ohun tó ń mọ́kàn èèyàn fà sí ìṣékúṣe ṣe burú tó nìyí, ó máa jẹ́ kó o “kórìíra ohun búburú.”—Sáàmù 97:10.

 Wo àwọn ohun tó máa yọrí sí. Ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe má ń sọ àwọn tó wà nínú rẹ̀ di ẹni àbùkù. Ó máa ń sọ àwọn tó ń wò ó dìdàkudà. Ìdí pàtàkì nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.”—Òwe 22:3.

 Ṣe ìpinnu. Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ náà sọ pé: “Èmi ti bá ojú mi dá májẹ̀mú. Nítorí náà, èmi yóò ha ṣe tẹjú mọ́ wúńdíá?” (Jóòbù 31:1) Àwọn “májẹ̀mú” tí o lè dá nìyí:

  •  Mi ò ní lo Íńtánẹ́ẹ̀tì nígbà tí mo bá dá wà.

  •  Tí àwòrán oníhòhò bá fara hàn lójijì tàbí tí mo bá dé ibi tí àwòrán oníhòòhò wà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni màá gbé e kúrò.

  •  Màá bá ọ̀rẹ́ mi kan tó sún mọ́ Ọlọ́run dáadáa sọ̀rọ̀ tó bá ṣẹlẹ̀ pé mo tún wo ohun tó ń mọ́kàn fà sí ìṣekúṣe.

Ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe máa ń di bárakú, bó o ṣe ń wò ó léraléra tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa ṣòro tó láti jáwọ́ ń bẹ̀

 Gbàdúrà nípa rẹ̀. Onísáàmù bẹ Jèhófà Ọlọ́run pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.” (Sáàmù 119:37) Ọlọ́run fẹ́ kó o ṣàṣeyọrí, tó o bá gbàdúrà sí i, á fún ẹ lókun láti ṣe ohun tó tọ́!—Fílípì 4:13.

 Bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. Ohun pàtàkì kan tó lè mú kó o bọ́ lọ́wọ́ ìwà náà ni kó o yan ẹni kan tí wàá finú hàn.—Òwe 17:17.

 Rántí: Ìgbàkigbà tó o bá ti yẹra fún ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, àṣeyọrí kan lo ṣe yẹn. Sọ fún Jèhófà nípa àṣeyọrí náà, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún okun tó fún ẹ. Tó o bá yẹra fún ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, wàá mọ́kàn rẹ̀ yọ̀!—Òwe 27:11.