Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jẹ́ Káwọn Òbí Mi Fọkàn Tán Mi?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jẹ́ Káwọn Òbí Mi Fọkàn Tán Mi?

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

 Irú ẹni tó o bá fi han àwọn òbí ẹ pé o jẹ́ ló máa pinnu bí wọ́n á ṣe fọkàn tán ẹ tó. Tó o bá ń ṣe ohun táwọn òbí ẹ ní kó o ṣe, ṣe ló dà bí ìgbà tó o san gbèsè tó o jẹ ní báǹkì. Tó o bá ṣe ń san owó tó o yá ní báǹkì ni àwọn òṣìṣẹ́ báǹkì á máa fọkàn tán ẹ, wọ́n á sì tún lè yá ẹ lówó sí i. Lọ́nà kan náà, ó yẹ kó o máa gbọ́ tàwọn òbí ẹ, bó o bá sì ṣe ń gbọ́ tiwọn ni wọ́n á túbọ̀ máa fọkàn tán ẹ, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ kó o túbọ̀ lómìnira. Àmọ́ tó o bá ti ń ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ẹ, má jẹ́ kó yà ẹ lẹ́nu pé wọ́n lè dín òmìnira tó o ní kù.

 Ó máa gba àkókò kí wọ́n tó lè fọkàn tán ẹ. Kí àwọn òbí ẹ tó lè túbọ̀ fún ẹ lómìnira, ó yẹ kí wọ́n mọ̀ ẹ́ mọ ìwà ọmọlúàbí.

 OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ ẸNÌ KAN: “Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mo mọ ohun táwọn òbí mi máa ń fẹ́ kí n ṣe gan-an, màá wá máa díbọ́n pé mò ń ṣe ohun tí wọ́n fẹ́, bẹ́ẹ̀ ojú ayé ni mò ń ṣe, mò ń yọ́ tinú mi ṣe ní kọ̀rọ̀. Ìyẹn jẹ́ kó ṣòro fáwọn òbí mi láti fọkàn tán mi. Nígbà tó yá, mo rí i pé kò sí àbùjá lọ́rùn ọ̀pẹ. Tó o bá fẹ́ káwọn òbí ẹ fún ẹ lómìnira sí i, àfi kó o máa ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fọkàn tán ẹ. Kò sọ́gbọ́n míì tó o lè dá.”​—Craig.

 Ohun tó o lè ṣe

 Máa sòótọ́, kódà bí ohun tó o ṣe bá tiẹ̀ dùn ẹ́. Kò sẹ́ni tí kì í ṣàṣìṣe, àmọ́ tó o bá ń bo irọ́ mọ́lẹ̀ (tàbí tó ò ń fi àwọn òótọ́ kan pa mọ́), ṣe ló máa ba ìgbẹ́kẹ̀lé táwọn òbí ẹ ní nínú ẹ jẹ́. Ṣùgbọ́n tó o bá máa ń sòótọ́, táwọn òbí ẹ sì ti mọ̀ ẹ́ mọ́ ọn, wọ́n máa rí i pé o ti gbọ́n tó láti máa gba ẹ̀bi ẹ lẹ́bi. Irú ẹni tó sì ṣeé fọkàn tán nìyẹn.

 “Ti pé ò ń ṣe àṣìṣe ò ní kí wọ́n má fọkàn tán ẹ mọ́, ohun tí ò ní jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán ẹ mọ́ ni tó o bá ń bo àṣìṣe ẹ mọ́lẹ̀.”​—Anna.

 Bíbélì sọ pé: “A . . . dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”​—Hébérù 13:18.

  •   Rò ó wò ná: Táwọn òbí ẹ bá bi ẹ́ léèrè ibi tó ò ń lọ àtohun tó o fẹ́ lọ ṣe, ṣé o máa ń sòótọ́ fún wọn délẹ̀délẹ̀? Àbí táwọn òbí ẹ bá bi ẹ́ léèrè ibi tó o lọ àtohun tó o lọ ṣe, ṣé o máa ń bomi la àlàyé tó yẹ kó o ṣe fún wọn?

 Máa hùwà ọmọlúàbí. Gbogbo òfin tí wọ́n bá ṣe nínú ilé ni kó o máa tẹ̀ lé. Tètè máa ṣiṣẹ́ tí wọ́n bá ní kó o ṣe. Tí ìwọ àti ẹnì kan bá ní àdéhùn, má máa pẹ́ débẹ̀. Fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ iléèwé rẹ. Aago tí wọ́n bá ní kó o wọlé náà ni kó o máa wọlé.

 “Táwọn òbí ẹ bá gbà kí ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ ṣeré jáde, àmọ́ tí wọ́n sọ fún ẹ pé aago mẹ́sàn-án alẹ́ ò gbọ́dọ̀ lù bá ẹ níta, tó o bá lọ délé ní aago mẹ́wàá ààbọ̀, má retí pé wọ́n á jẹ́ kó o bá àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ṣeré jáde lọ́jọ́ míì!”​—Ryan.

 Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.”​—Gálátíà 6:5.

  •   Rò ó wò ná: Kí làwọn òbí ẹ mọ̀ ẹ́ mọ́ tó bá dọ̀rọ̀ pípẹ́ lẹ́yìn, ṣíṣe iṣẹ́ ilé àti títẹ̀lé òfin tí wọ́n ṣe nínú ilé, ì báà tiẹ̀ jẹ́ òfin tó ò gba tiẹ̀?

 Máa ní sùúrù. Tó o bá ti ṣohun tí ò jẹ́ káwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ mọ́, ó máa gba àkókò kí wọ́n tó tún lè pa dà fọkàn tán ẹ. Àfi kó o ṣe sùúrù.

 “Nígbà tí mo dàgbà sí i, inú máa ń bí mi pé àwọn òbí mi kì í jẹ́ kí n ṣe àwọn nǹkan kan. Mi ò tètè mọ̀ pé àgbà ò kan ọgbọ́n, èèyàn lè dàgbà kó má danú. Mo wá ní káwọn òbí mi fún mi láǹfààní kí n lè jẹ́ kí wọ́n rí i pé wọ́n lè fọkàn tán mi. Ó gba àkókò díẹ̀ o, àmọ́ ó ṣiṣẹ́. Mo wá rí i pé ti pé èèyàn dàgbà kọ́ ló ń jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán an, ohun tó bá ń ṣe ló máa jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán an.”​—Rachel.

 Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.”​—2 Kọ́ríńtì 13:5.

  •   Rò ó wò ná: Tó o bá fẹ́ káwọn òbí ẹ fọkàn tán ẹ, kí làwọn ohun tó o lè ṣe láti fi irú ẹni tó o “jẹ́” hàn?

 ÀBÁ: Fi ṣe àfojúsùn ẹ pé o ò fẹ́ máa pẹ́ lẹ́yìn, tàbí pé o fẹ́ tètè máa parí iṣẹ́ ilé tàbí pé o ò fẹ́ máa kọjá aago táwọn òbí ẹ bá ni kó o wọlé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Jẹ́ káwọn òbí ẹ mọ ohun tó o ti pinnu lọ́kàn ẹ, kó o sì bi wọ́n ní ohun tí wọ́n retí kó o máa ṣe kí wọ́n lè fọkàn tán ẹ. Kó o wá sapá láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì pé: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé.” (Éfésù 4:​22) Bó pẹ́ bó yá, àwọn òbí ẹ máa rí pé nǹkan ti yàtọ̀!