Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Owó Ná?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Owó Ná?

 “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo lọ wo àwọn nǹkan tí wọ́n ń tà ní ilé ìtajà kan. Nígbà tí mo fi máa kúrò níbẹ̀, mo ti ra ọjà kan tó wọ́n gan-an tí mi ò sì ní lọ́kàn láti rà nígbà tí mo kọ́kọ́ wọlé!”​—Colin.

 Colin sọ pé òun ò mọ bí òun ṣe lè máa ṣọ́wó ná. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tìẹ náà rí, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

 Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa ṣọ́wó ná?

 Èrò òdì: Oò ní lómìnira tó o bá ń ṣọ́wó ná.

 Òótọ́ ọ̀rọ̀: Tó o bá ń ṣọ́wó ná, òmìnira tó o ní máa pọ̀ sí i, kò ní dín kù. Ìwé kan tó ń jẹ́ I’m Broke! The Money Handbook sọ pé: “Bó o bá ṣe túbọ̀ mọ̀ sí i nípa owó ni wàá ní owó fún àwọn nǹkan tó o fẹ́ nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.”

 Rò ó wò ná: Tó o bá ń ṣọ́wó ná . . .

  •   Wàá rí owó ṣe ohun tó o fẹ́ ṣe. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Inez sọ pé: “Mo fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí South America tó bá di ọjọ́ iwájú, mo máa ń fi àfojúsùn mi yìí sọ́kàn tí mo bá fẹ́ tọ́jú owó.”

  •   Gbèsè díẹ̀ ló máa wà lọ́rùn ẹ, o sì lè má jẹ gbèsè rárá. Bíbélì sọ pé: ‘ayá-nǹkan ni ìránṣẹ́ awínni.’ (Owe 22:7) Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Anna sọ pé: “Gbèsè kì í jẹ́ kéèyàn ráyè ara ẹ̀, àmọ́ tí kò bá sí gbèsè lọ́rùn ẹ, wàá lè gbájú mọ́ àwọn àfojúsùn tó o ní.”

  •   Wàá fi hàn pé o kìí ṣe ọmọdé mọ́. Àwọn tó bá ń ṣọ́wó ná ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Jean tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún sọ pé: “Mò ń gbìyànjú láti ṣọ́wó ná, ẹ̀kọ́ ńlá ló sì jẹ́ fún mi. Torí pé tí mo bá ti mọ bí mo ṣe lè máa ṣọ́ owó ná, ìyẹn máa ràn mí lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú tí mo bá ti ń dá gbé.”

 Òótọ́ ọ̀rọ̀: Ìwé kan tó ń jẹ́ The Complete Guide to Personal Finance: For Teenagers and College Students sọ pé: “Tó o bá mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná, tó o sì ń ṣọ́wó ná, ṣe lò ń fi hàn pé o lè dá ṣe nǹkan fúnra rẹ. Tó o bá ti mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná báyìí, jálẹ̀ ayé rẹ̀ ló máa ṣe ọ́ láǹfààní.”

 Bó o ṣe lè ṣe é

 Mọ ibi tó o kù sí. Tó o bá kíyè sí pé owó kì í pẹ́ tán lọ́wọ́ ẹ, kọ́kọ́ wádìí ohun tó ò ń náwó lé lórí. Fún àwọn kan, ọjà tí wọ́n ń rà lórí íńtánẹ́ẹ̀tì ló ń gbọ́n owó wọn gbẹ. Ìṣòro táwọn míì ní ni pé, wọn kì í yé ra nǹkan. Tó bá fi máa di ìparí oṣù, àpò wọn á ti gbẹ!

 “Díẹ̀ díẹ̀ lowó máa ń tán. Mo rí tibí mo rà á, mo rí tọ̀hún mo rà á, tó bá di ìparí oṣù màá máa wò ó pé kí ni mo fi owó ṣe!”​—Hailey.

 Kọ àwọn nǹkan tó o fẹ́ náwó lé sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” (Owe 21:5) Tó o bá ń kọ àwọn nǹkan tó o fẹ́ náwó lé sílẹ̀, tó o sì kọ iye tó o fẹ́ ná lórí wọn, oò ní ná kọjá owó tó ń wọlé fún ẹ.

 “Tó o bá kíyèsí pé ò ń ná kọjá iye owó tó ń wọlé fún ẹ, kọ́kọ́ wádìí ohun tó ò ń náwó lé, lẹ́yìn náà, yéé náwó lórí àwọn nǹkan tóò nílò. Dín àwọn nǹkan tó ò ń náwó lé lórí kù títí tí owó tó ń wọlé fún ẹ fi máa pọ̀ ju iye tó ò ń ná lọ.”​—Danielle.

 Ríi pé o ṣe ohun tó o sọ. Ọ̀pọ̀ nǹkan wà tó o lè ṣe tí wàá fi máa ṣọ́wó ná, tóò sì ní máa náwó ní ìnákúnàá. Àwọn ọ̀dọ́ kan ti gbìyànjú àwọn àbá yìí, nǹkan sì ti yàtọ̀ fún wọn:

  •  “Gbàrà tí mo bá ti gba owó ni mo máa ń lọ fi sí báǹkì, torí mo mọ̀ pé ó máa ṣòro fún mi láti ná a níbi tó wà yẹn.”​—David.

  •  “Tí mo bá fẹ́ lọ rajà, iye tí mo fẹ́ ná ni mo máa ń mú dání. Ìyẹn ni mi ò fi ní ná kọjá ohun tí mo ní lọ́kàn.”​—Ellen.

  •  “Mó máa ń ní sùúrù kí ń tó ra nǹkan. Àsìkò tí mo fi dúró yẹn máa ń jẹ́ kí ń ronú bóyá mo nílò nǹkan yẹn lóòótọ́.”​—Jesiah.

  •  “Kì í ṣe gbogbo òde tí wọ́n bá pè mí sí ni máa lọ! Tí mi ò bá lówó lọ́wọ́, máa sọ pé mi ò ní lè wá, kò sóun tó burú nínú ìyẹn.”​—Jennifer.

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Kò rọrùn láti ṣọ́wó ná. Colin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà gbà bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Tí mo bá máa di olórí ìdílé lọ́jọ́ iwájú, kò yẹ kí ń máa náwó ní ìnákúnàá. Tí mi ò bá mọ bí mo ṣe lè ṣówó ná nísìnyí, ìṣòro ńlá nìyẹn máa fà tí mo bá gbéyàwó.”

Àbá: “Sọ ohun tó o fẹ́ fowó ṣe fún ẹnì kan, sọ pé kẹ́ni yẹn máa bi ẹ́ pé báwo lo ṣe ń ṣe àwọn nǹkan yẹn sí. Ohun tó dáa ni tó o bá lẹ́ni tó o máa ń ṣàlàyé bó o ṣe náwó fún!”​—Vanessa.