Ǹjẹ́ Bíbélì Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì Òde òní?
Ǹjẹ́ Bíbélì Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì Òde òní?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn kárí ayé lónìí ń bẹ̀rù nítorí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àárín gbùngbùn Ìwọ Oòrùn ayé. Àwọn nǹkan tó ń wáyé níbẹ̀ ni, fífi ọkọ̀ ogun òfúrufú gbéjà kóni, ìjà pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ àti bí àwọn apániláyà ṣe ń fi bọ́ǹbù pani tí wọ́n sì ń ba nǹkan jẹ́. Yàtọ̀ sí gbogbo àgbákò yìí, ó tún ṣeé ṣe kí wọ́n lo àwọn ohun ìjà runlérùnnà. Abájọ táwọn èèyàn níbi gbogbo fi ń bẹ̀rù!
Bákan náà, ní May ọdún 1948, ńṣe làwọn èèyàn ń fi ìháragàgà wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àárín gbùngbùn Ìwọ Oòrùn ayé. Lákòókò yẹn, ìyẹn ọgọ́ta ọdún ó lé méjì [62] sẹ́yìn, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fẹ́ gbé àṣẹ tó ní lórí ilẹ̀ Palẹ́sìnì lé ilẹ̀ Ísírẹ́lì lọ́wọ́, nítorí èyí, ogun rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Ní ọdún kan ṣáájú ìgbà yẹn, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti pàṣẹ pé kí wọ́n dá orílẹ̀-èdè Júù sílẹ̀ láwọn àgbègbè tí wọ́n wà. Àwọn ará Arébíà tó wà láyìíká wọn sì ti sọ pé ohun tó bá gbà làwọn máa fún un, àwọn kò ní jẹ́ kó ṣeé ṣe. Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Arébíà tiẹ̀ kìlọ̀ pé, “Ìgbà gbogbo ni ìjà àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ á máa wáyé láwọn ààlà tó wà láàárín wa.”
Aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ti lù ní ọjọ́ Friday May 14, ọdún 1948. Àṣẹ tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní lórí Palẹ́sínì máa tó dópin ní wákàtí díẹ̀ sí i. Ní Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ní ìlú Tel Aviv, àwọn àádọ́ta dín ní irínwó [350] èèyàn tí wọ́n fìwé pè ní bòókẹ́lẹ́ ń retí ìkéde tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí wọ́n ti ń wọ̀nà fún pé, Ísírẹ́lì òde òní ti di orílẹ̀-èdè. Àwọn ọmọ ogun ẹ̀ṣọ́ wà káàkiri kí àwọn ọ̀tá orílẹ̀-èdè tuntun yìí má bàa ṣèdíwọ́ fún ìkéde náà.
Ọ̀gbẹ́ni David Ben-Gurion tó jẹ́ aṣáájú Ìgbìmọ̀ Àpapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Ísírẹ́lì, ka Ìkéde Tí Wọ́n Fi Dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì Sílẹ̀. Apá kan lára rẹ̀ kà pé: “Àwa Ìgbìmọ̀ Àwọn Èèyàn, tó ń ṣojú fún Àgbájọ Àwọn Èèyàn Ilẹ̀ Ísírẹ́lì . . . lọ́lá ẹ̀tọ́ wa gẹ́gẹ́ bí onílẹ̀ àti Ìpinnu tí Àpéjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe, kéde ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì [Palẹ́sìnì] pé o di orílẹ̀-èdè kan.”
Ṣé Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Ló Ní Ìmúṣẹ?
Èrò àwọn kan nínú ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì Ajíhìnrere ni pé, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ní ìmúṣẹ nígbà tí ilẹ̀ Ísírẹ́lì Aísáyà 66:8.) . . . Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó tíì gbàfiyèsí jù lọ lèyí jẹ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún yìí. Ẹ̀rí tó ṣe kedere lèyí jẹ́ fún gbogbo èèyàn láti mọ̀ pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì ṣì wà láàyè síbẹ̀.”
òde òní di orílẹ̀-èdè kan. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa Jerúsálẹ́mù, ìyẹn Jerusalem Countdown, àlùfáà kan tó ń jẹ́ John Hagee sọ pé: “Wòlíì Aísáyà ti ṣàkọsílẹ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí, ó ní, ‘A bí orílẹ̀-èdè kan ní ọjọ́ kan.’ (WoṢé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí? Ǹjẹ́ ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì òde òní ni Aísáyà 66:8 ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀? Ṣé òótọ́ ni pé May 14, ọdún 1948, ni “àsọtẹ́lẹ̀ tó tíì gbàfiyèsí jù lọ ní ìmúṣẹ ní ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún yìí”? Tó bá jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì òde òní ṣì jẹ́ àyànfẹ́ Ọlọ́run, tó sì jẹ́ pé Ọlọ́run ṣì ń lò ó láti mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ, ó dájú pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi gbogbo á fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀.
Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sọ pé: “Ta ni ó ti gbọ́ irú èyí rí? Ta ni ó ti rí irú nǹkan báwọ̀nyí rí? A ha lè bí ilẹ̀ kan pẹ̀lú ìrora ìrọbí ní ọjọ́ kan? Tàbí kẹ̀, a ha lè bí orílẹ̀-èdè kan ní ìgbà kan? Nítorí pé Síónì ti wọnú ìrora ìrọbí, ó sì ti bí àwọn ọmọ rẹ̀.” (Aísáyà 66:8) Ẹsẹ yẹn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìbí orílẹ̀-èdè yẹn lódindi láìrò tẹ́lẹ̀, bíi pé ní ọjọ́ kan. Àmọ́ ta ló máa jẹ́ kí ìbí yìí ṣeé ṣe? Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e jẹ́ ká mọ̀, ó ní: “‘Ní tèmi, èmi yóò ha fa yíya, kí n má sì fa bíbímọ?’ ni Jèhófà wí. ‘Tàbí kẹ̀, èmi yóò ha fa bíbímọ, kí n sì fa títìpa ní tòótọ́?’ ni Ọlọ́run rẹ wí.” Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ kó hàn kedere pé òun lẹni tó máa mú kí ìbí orílẹ̀-èdè náà ṣeé ṣe láìrò tẹ́lẹ̀.
Ìjọba tiwa-n-tiwa tí kò fi ẹ̀rí hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run Bíbélì ló ń ṣàkóso Ísírẹ́lì. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́dún 1948 gbà pé Jèhófà Ọlọ́run ló jẹ́ kí ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè wọn ṣeé ṣe? Rárá, wọn kò gbà. Wọn kò dá orúkọ Ọlọ́run tàbí mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ náà, “Ọlọ́run” níbikíbi nínú ọ̀rọ̀ ìkéde náà. Ìwé kan tó sọ nípa àwọn Júù, ìyẹn Great Moments in Jewish History sọ ohun kan nípa ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ kẹ́yìn pé àwọn máa fi ṣe ìkéde náà, ó ní: “Àní títí di aago kan ọ̀sán ọjọ́ náà nígbà tí Ìgbìmọ̀ Àpapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Ísírẹ́lì pàdé pọ̀, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn kò lè fohùn ṣọ̀kan lórí ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa lò fún ìkéde ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè náà. . . . Àwọn Júù alákìíyèsí fẹ́ kí wọn lo, ‘Ọlọ́run Ísírẹ́lì,’ nínú ọ̀rọ̀ ìkéde náà. Àmọ́, àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀ràn ìsìn kò gbà. Ọ̀gbẹ́ni Ben-Gurion fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó sì pinnu pé kí wọ́n lo ‘Àpáta’ dípò ‘Ọlọ́run.’”
Títí dòní, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì òde òní sọ pé, ìpinnu Àpéjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti ẹ̀tọ́ àwọn gẹ́gẹ́ bí onílẹ̀ ló jẹ́ kí ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè àwọn ṣeé ṣe. Ṣé ó bọ́gbọ́n mu láti retí pé Ọlọ́run Bíbélì á ṣe iṣẹ́ ìyanu tá a ti sọ tẹ́lẹ̀ tó gbàfiyèsí jù lọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún yìí nítorí àwọn èèyàn tí kò fògo fún un?
Kí Ni Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ìdásílẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Ísírẹ́lì Òde Òní àti Ti Àtijọ́?
Ìṣesí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì òde òní yàtọ̀ gan-an sí ti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà yẹn, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì di ‘àtúnbí’ bíi pé ní ọjọ́ kan lẹ́yìn tí àwọn ará Bábílónì ti ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́, tí wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn lọ ní àádọ́rin ọdún ṣáájú ìgbà yẹn. Lákòókò yẹn, Aísáyà 66:8 ní ìmúṣẹ lọ́nà tó gbàfiyèsí nígbà tí Kírúsì Ńlá ará Páṣíà tó ṣẹ́gun ìlú Bábílónì pàṣẹ pé kí àwọn Júù pa dà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn.—Ẹ́sírà 1:2.
Kírúsì Ọba Páṣíà gbà pé ọwọ́ Jèhófà wà nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn tó sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù náà lọ nítorí àṣẹ náà pé kí wọ́n lọ bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run pa dà, kí wọ́n sì tún tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́. Kò sí ìgbà kankan tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì òde òní kéde pé àwọn fẹ́ ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tàbí ní irú èrò bẹ́ẹ̀.
Ṣé Àyànfẹ́ Ọlọ́run Ṣì Ni Orílẹ̀-Èdè Náà?
Ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Ísírẹ́lì pàdánù àǹfààní jíjẹ́ orílẹ̀-èdè àyànfẹ́ nígbà tí wọ́n kọ Mèsáyà tó jẹ́ Ọmọ Jèhófà Ọlọ́run sílẹ̀. Mèsáyà fúnra rẹ̀ sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: Mátíù 23:37, 38) Ọ̀rọ̀ Jésù yìí ṣẹ ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni nígbà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run títí kan ètò àlùfáà rẹ̀. Àmọ́ kí ló máa jẹ́ àbájáde ìfẹ́ Ọlọ́run láti ní “àkànṣe dúkìá . . . nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù, . . . ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́”?—Ẹ́kísódù 19:5, 6.
“Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, olùpa àwọn wòlíì àti olùsọ àwọn tí a rán sí i lókùúta . . . Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.” (Àpọ́sítélì Pétérù tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ Júù dáhùn ìbéèrè yẹn nínú lẹ́tà kan tó kọ sáwọn Kèfèrí àtàwọn Júù tí wọ́n jẹ́ Kristẹni. Ó ní: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní,’ . . . nítorí ẹ kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run; ẹ̀yin ni àwọn tí a kò ti fi àánú hàn sí tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ jẹ́ àwọn tí a ti fi àánú hàn sí.”—1 Pétérù 2:7-10.
Àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn jẹ́ orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, kì í ṣe ìgbà tí wọ́n bí wọn tàbí ibi tí wọ́n bí wọn sí ló pinnu èyí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà báyìí pé: “Nítorí ìdádọ̀dọ́ tàbí àìdádọ̀dọ́ kò jámọ́ ohunkóhun, ṣùgbọ́n ìṣẹ̀dá tuntun ni ó jámọ́ nǹkan kan. Gbogbo àwọn tí yóò sì máa rìn létòletò nípasẹ̀ ìlànà àfilélẹ̀ fún ìwà híhù yìí, kí àlàáfíà àti àánú wà lórí wọn, àní lórí Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Gálátíà 6:15, 16.
Nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì òde òní máa ń fún àwọn tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Júù tàbí ẹni ti wọ́n sọ di Júù ní ẹ̀tọ́ jíjẹ́ ọmọ ìbílẹ̀, jíjẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” tí Bíbélì ń sọ ní ibi yìí wà fún àwọn ‘onígbọràn, tá a fi ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi wọ́n.’ (1 Pétérù 1:1, 2) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run tàbí àwọn Júù tẹ̀mí yìí, ó ní: “Òun kì í ṣe Júù ẹni tí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní òde ara, bẹ́ẹ̀ ni ìdádọ̀dọ́ kì í ṣe èyí tí ó wà ní òde ara. Ṣùgbọ́n òun jẹ́ Júù ẹni tí ó jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní inú, ìdádọ̀dọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ti ọkàn-àyà nípasẹ̀ ẹ̀mí, kì í sì í ṣe nípasẹ̀ àkójọ òfin tí a kọ sílẹ̀. Ìyìn ẹni yẹn kò wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—Róòmù 2:28, 29.
Ẹsẹ yẹn jẹ́ ká lóye ọ̀rọ̀ tó lè fa awuyewuye tí Pọ́ọ̀lù sọ. Nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Róòmù, ó ṣàlàyé pé, àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Júù tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ dà bí ẹ̀ka igi ólífì ìṣàpẹẹrẹ tí a ṣẹ́ kúrò, kí á lè lọ́ “àwọn ẹ̀ka” ólífì “ìgbẹ́,” ìyẹn àwọn Kèfèrí sáàárín wọn. (Róòmù 11:17-21) Ó wá parí àpèjúwe náà báyìí pé: “Ìpòkúdu agbára ìmòye ti ṣẹlẹ̀ lápá kan sí Ísírẹ́lì títí di ìgbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè bá ti wọlé, àti pé lọ́nà yìí ni a ó gba gbogbo Ísírẹ́lì là.” (Róòmù 11:25, 26) Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé, gbogbo àwọn Júù máa yí pa dà bìrí di Kristẹni? Ó dájú pé irú ìyípadà yìí kò tíì ṣẹlẹ̀.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé “gbogbo Ísírẹ́lì,” àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ìyẹn àwọn Kristẹni tá a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn ló ní lọ́kàn. Ohun tó ń sọ ni pé, kíkọ̀ táwọn ọmọ ìbílẹ̀ Júù kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba Mèsáyà kò ní dí Ọlọ́run lọ́wọ́ mímú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ láti ní àwọn ẹ̀ka ‘igi ólífì’ tẹ̀mí tó ń so èso. Èyí sì bá àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ara rẹ̀ mu, pé òun jẹ́ àjàrà tí wọ́n máa ṣẹ́ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí kò so èso dà nù. Jésù sọ pé: “Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni aroko. Gbogbo ẹ̀ka tí ń bẹ nínú mi tí kì í so èso ni ó ń mú kúrò, gbogbo èyí tí ó sì ń so èso ni ó ń wẹ̀ mọ́, kí ó lè so èso púpọ̀ sí i.”—Jòhánù 15:1, 2.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì òde òní, ó sọ nípa ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tẹ̀mí! Tó o bá mọ orílẹ̀-èdè tẹ̀mí yìí, tó o sì dara pọ̀ mọ́ ọn, wàá rí ìbùkún ayérayé gbà.—Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18; Gálátíà 3:8, 9.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]
Kí ni àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù ṣe nípa igi ólífì túmọ̀ sí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ọ̀gbẹ́ni David Ben-Gurion, ní May 14, ọdún 1948
[Credit Line]
Ilé Iṣẹ́ Ìròyìn Ìjọba ilẹ̀ Ísírẹ́lì, Ayàwòrán: Kluger Zoltan
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 27]
Todd Bolen/Bible Places.com