Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú bí Jésù Ti Ṣe

Máa Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú bí Jésù Ti Ṣe

Máa Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú bí Jésù Ti Ṣe

LÁSÁRÙ tó ń gbé ní Bẹ́tánì ń ṣàìsàn gan-an. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin, Màtá àti Màríà sì rán àwọn ońṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ Jésù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́. Àmọ́, àìsàn náà pa Lásárù. Lẹ́yìn tí wọ́n ti tẹ́ ẹ sí ibojì, àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn aládùúgbò wọn ń wá sọ́dọ̀ Màtá àti Màríà “láti tù wọ́n nínú.” (Jòhánù 11:19) Níkẹyìn, Jésù dé Bẹ́tánì, ó sì lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtàtà. Tá a bá ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó sọ àtohun tó ṣe níbẹ̀, a lè rí ohun kan kọ́ nípa béèyàn ṣe lè tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú.

Lílọ Síbẹ̀ Fi Hàn Pé O Bìkítà

Kí Jésù tó lè dé Bẹ́tánì, ó máa rìnrìn àjò nǹkan bí ọjọ́ méjì gba Odò Jọ́dánì kọjá, á sì rìn gba ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè tó rí kọ́lọkọ̀lọ tó wá láti Jẹ́ríkò. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù wọ abúlé náà, Màtá tètè lọ pàdé rẹ̀ láti kí i káàbọ̀. Nígbà tó yá tí Màríà gbọ́ pé Jésù ti dé, òun náà yára lọ rí i. (Jòhánù 10:40-42; 11:6, 17-20, 28, 29) Wíwá tí Jésù wá jẹ́ ìtùnú fún àwọn ẹ̀gbọ́n Lásárù tí ìbànújẹ́ ti bá.

Bákan náà lónìí, bí a bá lọ kí àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀,ìtùnú ló máa jẹ́ fún wọn. Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Scott àti Lydia, tí Theo ọmọ wọn ọmọ ọdún mẹ́fà kú nínú jàǹbá ọkọ̀, sọ pé: “À ń fẹ́ ìtìlẹ́yìn àwọn ará ilé àtàwọn ọ̀rẹ́ wa. Wọ́n wá bá wa nílé ìwòsàn láàárín òru.” Kí ni àwọn tọkọtaya yìí sọ? Wọ́n ní: “A kò nílò ọ̀rọ̀ kankan ní àkókò yẹn. Wíwá tí wọ́n wá fi hàn pé wọ́n bìkítà nípa wa.”

Bíbélì sọ pé nígbà tí Jésù rí àwọn tí wọ́n ń sunkún nítorí pé Lásárù kú, ó “dààmú” ó sì “da omijé.” (Jòhánù 11:33-35, 38) Jésù kò ka dída omijé níṣojú àwọn èèyàn sí pé òun ba ọkùnrin jẹ́. Ó lóye bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára wọn, ó sì bá wọn kẹ́dùn. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́? Nígbà tá a bá lọ kí àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀, kò yẹ kí ojú máa tì wá láti sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún. (Róòmù 12:15) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, má ṣe gbìyànjú ẹ̀ pé kí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ máa sunkún. Ó lè jẹ́ pé ìkọ̀kọ̀ làwọn kan á ti fẹ́ sunkún.

Tẹ́tí Sílẹ̀ Tàánútàánú

Ó ṣeé ṣe kí Jésù ti ní ọ̀rọ̀ ìṣírí lọ́kàn láti sọ fún Màtá àti Màríà, àmọ́, ó hàn kedere pé ó jẹ́ kí wọ́n kọ́kọ́ sọ̀rọ̀. (Jòhánù 11:20, 21, 32) Nígbà tó sì bá Màtá sọ̀rọ̀, ó béèrè ìbéèrè, lẹ́yìn náà, ó tẹ́tí sílẹ̀.—Jòhánù 11:25-27.

Téèyàn bá ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa, ó máa fi hàn pé lóòótọ́ ni èèyàn ń gba tẹni rò. Kéèyàn tó lè tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú, èèyàn ní láti tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. A lè fi hàn pé à ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa tá a bá ń béèrè ìbéèrè tó máa mú kí ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀ túbọ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Àmọ́, ṣọ́ra o, má ṣe fipá mú wọn tí wọn kò bá fẹ́ sọ̀rọ̀. Ó lè jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, tí wọ́n sì fẹ́ sinmi.

Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ kàn lè máa wò suu nígbà míì, wọ́n sì lè máa sọ ọ̀rọ̀ kan ní àsọtúnsọ. Àmọ́ àwọn míì máa ń sọ bí ọ̀ràn ṣe rí lára wọn. Màríà àti Màtá sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ká ní o ti wà níhìn-ín ni, arákùnrin mi kì bá kú.” (Jòhánù 11:21, 32) Kí ni Jésù ṣe? Ó mú sùúrù fún wọn, ó sì tẹ́tí sí wọn tàánútàánú. Jésù kò wá máa sọ fún wọn pé báyìí ló ṣe yẹ kí wọ́n sọ̀rọ̀, báyìí ni kò ṣe yẹ. Láìsí àní-àní, ó mọ bí ìrora ṣe máa ń rí lára àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀.

Tí o kò bá mọ ohun tó o lè sọ nígbà tó o bá lọ sọ́dọ̀ ẹni tó ń ṣọ̀fọ̀, o lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa sísọ pé, “Ẹ pẹ̀lẹ́ o.” Lẹ́yìn náà, kó o fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n bá ń sọ. Bákan náà, fọkàn sí ohun tí wọ́n ń sọ. Máa wo ẹni náà bó ṣe ń sọ̀rọ̀, kó o sì gbìyànjú láti lóye bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀.

Kì í rọrùn láti lóye bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. Lydia ṣàlàyé pé, “Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wa máa ń yí pa dà. Nígbà míì, kò sọ́gbọ́n tá a lè dá sí i, ẹkún la kàn máa ń sun ṣáá níwájú àwọn àlejò. Ohun tá à ń fẹ́ ni pé káwọn èèyàn lóye wa. Àwọn ọ̀rẹ́ wa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti lóye bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wa.”

Jésù mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn dáadáa. Ó mọ̀ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ní “ìyọnu àjàkálẹ̀ tirẹ̀ àti ìrora tirẹ̀.” (2 Kíróníkà 6:29) Ìṣarasíhùwà Màríà àti Màtá ló pinnu èsì tí Jésù fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ní ti Màtá, ó ń sọ̀rọ̀, nítorí náà, Jésù bá a sọ̀rọ̀. Àmọ́ kò bá Màríà sọ̀rọ̀ pẹ́ nítorí pé Màríà ń sunkún. (Jòhánù 11:20-28, 32-35) Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù? Á dára gan-an kí á jẹ́ kí àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa sọ̀rọ̀ ká tó sọ̀rọ̀. Tó o bá múra tán láti tẹ́tí sílẹ̀ bí wọ́n ti ń sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn, ìyẹn lè tù wọ́n nínú gan-an.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Ń Mú Ara Ẹni Yá Gágá

Nígbà tí Màríà àti Màtá sọ fún Jésù pé: “Ká ní o ti wà níhìn-ín ni,” kò dá wọn lẹ́bi tàbí kó bínú. Ó fèsì tó fi Màtá lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.” (Jòhánù 11:23) Jésù fi ọ̀rọ̀ ṣókí yẹn ràn án lọ́wọ́ pé kó má banú jẹ́, ó sì rán an létí pé ìrètí ń bẹ.

Nígbà tó o bá ń bá àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ sọ̀rọ̀, rántí pé àwọn ọ̀rọ̀ tó ti ọkàn wá, bó ti wù kí wọ́n kéré mọ, lè gbéni ró, wọ́n sì lè ṣe bẹbẹ! A lè sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú náà tàbí kí á kọ ọ́ sórí ìwé. Nítorí pé àwọn lẹ́tà àti àwọn káàdì ṣeé kà lákàtúnkà, wọ́n lè fúnni ní ìtùnú fún àkókò gígùn. Lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn-án tí Bob ọkọ Kath kú, Kath tún gbogbo káàdì tó rí gbà kà. Ó sọ pé: “Mo rí i pé wọ́n ti túbọ̀ ràn mí lọ́wọ́ àní ní àkókò yẹn. Ìgbà yẹn gan-an ni mo rí ìtùnú gbà.”

Àwọn nǹkan wo lo lè kọ sínú ìwé ìtùnú kékeré tó o fẹ́ kọ sáwọn èèyàn? O lè kọ́ ìrírí kan tí ìwọ àti olóògbé náà jọ ní tàbí ìwà kan tó o mọyì lára rẹ̀. Kath sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ amọ́kànyọ̀ tí wọ́n sọ nípa Bob àti ìwà rẹ̀ mú kí n fẹ́ rẹ́rìn-ín kí n sì tún fẹ́ sunkún. Àwọn ọ̀rọ̀ tó ń pani lẹ́rìn-ín nípa ọkọ́ mi máa ń mú kí n rẹ́rìn-ín, ó sì ń mú kí n rántí ìgbésí ayé aláyọ̀ tá a lò pa pọ̀. Ọ̀pọ̀ káàdì tí mo mọyì gan-an báyìí ló ní àwọn ẹsẹ Bíbélì.”

Bá Wọn Ṣe Àwọn Nǹkan

Láti lè ran ìdílé Lásárù lọ́wọ́, Jésù ṣe ohun tí àwa kò lè ṣe. Ó jí Lásárù dìde. (Jòhánù 11:43, 44) Àmọ́ a lè bá wọn ṣe àwọn nǹkan tí agbára wá ká, irú bíi síse oúnjẹ, pípèsè ibi tí àwọn àlejò tó wá kí ẹni náà máa dé sí, bíbá wọn fọ aṣọ, bíbá wọn bójú tó àwọn ọmọ, lílọ́ bá wọn ra nǹkan, tàbí ká fi ọkọ̀ gbé wọn lọ síbi tí wọ́n bá fẹ́ lọ. Láìsí àní-àní, àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ máa mọrírì àwọn ohun tá a bá fìfẹ́ ṣe látọkàn wá.

Àmọ́ ṣá o, nígbà míì, àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lè fẹ́ láti dá wà. Síbẹ̀, o lè lo ìdánúṣe tó yẹ láti máa kàn sí wọn. Ìyá kan tó ń ṣọ̀fọ̀ sọ pé, “Kò sí bá a ṣe lè díwọ̀n ìgbà tó yẹ kéèyàn fi ṣọ̀fọ̀, kò sì sí pé ìgbà báyìí ni ara ẹni náà máa kọ́fẹ.” Àwọn kan máa ń gbìyànjú láti rántí àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ní àwọn ọjọ́ pàtàkì bí àyájọ́ ọjọ́ ìgbéyàwó wọn tàbí ọjọ́ tí olóògbé náà kú. Tó o bá lọ sọ́dọ̀ ẹni náà ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, wàá di alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ ní àkókò ìṣòro.—Òwe 17:17.

Ara ọ̀rọ̀ ìtùnú tí Jésù sọ ni ìrètí tó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i kúrò lójú oorun.” (Jòhánù 11:11) Jésù mú un dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé àjíǹde àwọn òkú yóò wà. Jésù bi Màtá pé: “Ìwọ ha gba èyí gbọ́ bí?” Ó dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa.”—Jòhánù 11:24-27.

Ṣé o gbà gbọ́ pé Jésù yóò jí àwọn òkú dìde? Tó o bá gbà gbọ́, sọ ìrètí tó ṣeyebíye yìí fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀. Máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ yóò tù wọ́n nínú dé ìwọ̀n àyè kan.—1 Jòhánù 3:18.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 9]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

PÈRÍÀ

Odò Jọ́dánì

Jẹ́ríkò

Bẹ́tánì

Òkun Iyọ̀

Jerúsálẹ́mù

SAMÁRÍÀ