Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Bó O Ṣe Lè Sàmì sí Ìwé​—Lórí iOS

Bó O Ṣe Lè Sàmì sí Ìwé​—Lórí iOS

Ohun tó o lè fi sàmì sí ìwé lórí JW Library máa jẹ́ kó o mọ ibi tó o kàwé dé, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ kan tàbí bírò há ibi téèyàn kàwé dé. Lórí JW Library, ibi mẹ́wàá lo lè sàmì sí nínú ìwé kọ̀ọ̀kan.

Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè sàmì sí ìwé:

 Sàmì sí Ìwé

O lè sàmì sí àpilẹ̀kọ kan tàbí orí kan nínú ìwé, tàbí kó o sàmì sí ìsọ̀rí kan àbí ẹsẹ Bíbélì kan.

Tó o bá fẹ́ sàmì sí àpilẹ̀kọ kan tàbí orí kan, tẹ àmì Bookmark. Á to àwọn àmì tó o lè fi síwèé náà. Wá tẹ àmì tó ò tíì lò kó o lè sàmì sí àpilẹ̀kọ tàbí orí tó ò ń kà lọ́wọ́lọ́wọ́.

Tó o bá fẹ́ sàmì sí ìpínrọ̀ kan tàbí ẹsẹ Bíbélì kan, kọ́kọ́ tẹ nọ́ńbà tó wà níwájú ẹsẹ yẹn tàbí ìpínrọ̀ yẹn, kó o wá tẹ àmì Bookmark.

 Lọ Síbi Tó O Sàmì Sí

Tó o bá fẹ́ lọ síbi tó o sàmì sí nínú ìwé kan, ṣí ìwé tí àmì náà wà, kó o wá tẹ àmì Bookmark. Yan èyí tó o bá fẹ́ rí.

 Yọ Ọ́ Kúrò Tàbí Kó O Rọ́pò Rẹ̀

Tó o bá ti sàmì síbì kan nínú ìwé, o lè yọ ọ́ kúrò tàbí kó o rọ́pò rẹ̀.

  • Tó o bá fẹ́ yọ àmì kan kúrò, tẹ Bookmark, fìka fa àmì tó o fẹ́ yọ kúrò. Kó o wá tẹ Delete.

  • Tó o bá fẹ́ rọ́pò àmì kan, tẹ Bookmark, kó o wá fìka tẹ àmì tó o fẹ́ rọ́pò. Tẹ Replace. Á wá fi ibi tó ò ń kà lọ́wọ́ rọ́pò ibi tó o ti sàmì sí tẹ́lẹ̀. O lè máa ṣe irú nǹkan yìí tó o bá fẹ́ máa mọ ibi tó o ka ìwé kan dé. Bí àpẹẹrẹ, o lè máa fìyẹn sàmì sí ibi tó o ka Bíbélì dé lójoojúmọ́.

May 2014 la gbé àwọn àtúnṣe yìí jáde, ó bá JW Library 1.2 wá. Ó máa ṣiṣẹ́ lórí iOS 6.0 sókè. Tó ò bá rí i lórí fóònù ẹ, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Lórí iOS,” lábẹ́ Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé.