Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LIBRARY

Pinnu Bó O Ṣe Fẹ́ Kí Ìwé Tó Ò Ń Kà Rí​—Lórí iOS

Pinnu Bó O Ṣe Fẹ́ Kí Ìwé Tó Ò Ń Kà Rí​—Lórí iOS

Àwọn ohun mélòó kàn wà nínú JW Library tó máa jẹ́ kó o lè pinnu bó o ṣe fẹ́ kí ìwé tó ò ń kà rí. Wàá rí wọn lápá òkè lójú fóònù ẹ tó o bá ń ka orí ìwé kan tàbí àpilẹ̀kọ kan.

Ó lè gba pé kó o tẹ More kó o lè rí díẹ̀ lára wọn.

Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí kó o lè pinnu bó o ṣe fẹ́ kí ìwé tó ò ń kà rí:

 Yí Èdè Pa Dà

O lè yí èdè orí ìwé tàbí àpilẹ̀kọ tó ò ń kà lọ́wọ́ pa dà.

  • Tẹ àmì Languages kó o lè rí gbogbo èdè tí ojú ìwé tó ò ń kà wà. Àwọn èdè tó ò ń lò jù ló máa wà lókè pátápátá. Àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tó rọrùn náà máa hàn níbí. O tún lè wá èdè kan tó o bá fi orúkọ èdè náà wá a.

  • Wàá rí àmì òfúrufú lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìwé tó ò tíì wà jáde. Tẹ ìwé kan kó o lè wà á jáde. Tí ìwé náà bá ti dórí fóònù ẹ, o ò ní rí àmì òfúrufú yẹn níbẹ̀ mọ́. Tún tẹ ìwé náà kó o lè kà á.

 Mú Kí Ọ̀rọ̀ Tóbi Tàbí Kó Kéré

O lè mú kí ọ̀rọ̀ tóbi tàbí kó kéré bó bá ṣe rò ẹ́ lọ́rùn kó o lè rí i kà.

Tẹ Text Settings, kó o wá fa ìlà tó o rí kó o lè mú kí ọ̀rọ̀ tóbi tàbí kó kéré. Bí ọ̀rọ̀ bá ṣe tóbi tó níbẹ̀ ló ṣe máa rí nínú gbogbo ìwé tó wà lórí JW Library.

 Ṣe É ní Àwòrán Tàbí Ọ̀rọ̀

Àwọn àpilẹ̀kọ kan wà tó o lè ṣe kó rí bí àwòrán tàbí ọ̀rọ̀. Tẹ èyí tó o bá fẹ́, kó o sì yí i pa dà nígbàkigbà tó o bá fẹ́.

  • View Image: Èyí máa jẹ́ kí àpilẹ̀kọ náà rí bó ṣe máa rí lọ́rí ìwé gangan. Bí àwọn kan ṣe máa ń fẹ́ kó rí nìyẹn tí wọ́n bá ń lo àwọn ìwé bí ìwé orin. Tí wọ́n bá ṣe é ní àwòrán, wọ́n máa rí àwọn àmì orin.

  • View Text: Èyí máa jẹ́ kí àwọn ẹsẹ Bíbélì ní ìlujá tó ṣeé tẹ̀, ọ̀rọ̀ sì máa tóbi tàbí kéré bó o bá ṣe fẹ́ kó rí.

 Ṣí I ní. . .

Apá tá a pè ní Open in . . . máa jẹ́ kó o lè wo àwọn ohun tó wà lórí JW Library níbòmíì.

Tẹ Open in . . . kó o lè rí àwọn ibi tó o ti lè wò ó. Bí àpẹẹrẹ, o lè tẹ Open in Online Library kó o lè ṣí ibi tó ò ń kà lọ́wọ́lọ́wọ́ lórí Watchtower ONLINE LIBRARY.

 To Bíbélì Lọ́nà Tó O Fẹ́

Tó o bá tẹ ẹsẹ Bíbélì kan nínú ìtẹ̀jáde kan, ó máa gbé e wá. Tẹ Customize tó wà nísàlẹ̀ pátápátá ẹsẹ Bíbélì yẹn kó o lè yan àwọn Bíbélì tó o ti wà jáde tẹ́lẹ̀ tó o máa fẹ́ kó hàn nígbàkigbà tó o bá tẹ ẹsẹ Bíbélì kan.

Tẹ Add tàbí Remove kó o lè yọ àwọn Bíbélì kan kúrò tàbí kó o fi kún un. O lè fa àwọn Bíbélì náà sókè tàbí sísàlẹ̀ kó o lè tún wọn tò bó o ṣe fẹ́.

Wo “Bó O Ṣe Lè Wa Bíbélì Jáde Kó O sì Máa Lò Ó​—Lórí iOS” kó o lè mọ bó o ṣe lè wa àwọn Bíbélì míì jáde lórí JW Library.

February 2015 la gbé àwọn àtúnṣe yìí jáde, ó bá JW Library 1.4 wá. Ó máa ṣiṣẹ́ lórí iOS 6.0 sókè. Tó ò bá rí i lórí fóònù ẹ, jọ̀ọ́ tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ “Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Lo JW Library​—Lórí iOS,” lábẹ́ Rí Àwọn Ohun Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé.