Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JW LANGUAGE

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—JW Language (Lórí iOS)

Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè​—JW Language (Lórí iOS)

Àwọn èdè kan, bí èdè Thai, ní àwọn àmì orí ọ̀rọ̀ àti ọmọ ìdí ọ̀rọ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ níbi álífábẹ́ẹ̀tì wọn. Irú ẹ̀ lè má hàn dáadá lórí àwọn fóònù iOS.

 

JW Language máa ṣiṣẹ́ lórí àwọn fóònù Android yìí:

  • Fóònù iPhone 4S sókè (tó jẹ́ iOS 8.0 sókè)

  • iPod Touch 5th generation sókè (tó jẹ́ iOS 8.0 sókè)

  • iPad 2 sókè (tó jẹ́ iOS 8.0 sókè)

  • iPad Mini 2 sókè (tó jẹ́ iOS 8.0 sókè)

  • iPad Pro (tó jẹ́ iOS 9.0 sókè)

Ó lè má ṣiṣẹ́ lórí àwọn fóònù yìí:

  • iPad 1

  • iPhone 4 sísàlẹ̀

 

  • Lórí àwọn JW Language tá a ti ṣe tẹ́lẹ̀, tí fóònù ò bá ti dún jáde nígbà tí ìpè bá wọlé, àtẹ́tísí orí JW Language náà ò ní sọ̀rọ̀. Jọ̀ọ́, wa JW Language tá a tún ṣe jáde sórí fóònù ẹ, kó o lè ní èyí tó dé kẹ́yìn.

  • Wo inú ètò ìṣiṣẹ́ yẹn kó o lè mọ̀ bóyá ìwọ lo tẹ bọ́tìnì tí wọ́n fi ń pa ọ̀rọ̀ mọ́ àtẹ́tísí lẹ́nu. Tó bá jẹ́ ìwọ ni, kó o tún un ṣe.

  • Rí i pé o yí fóònù ẹ sókè pátápátá.

 

Níbi ìbẹ̀rẹ̀, tẹ Settings, kó o wá tẹ bọ́tìnì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Global Playback Speed kó o lè mú kí àtẹ́tísí yára tàbí falẹ̀ tó bó o ṣe fẹ́.

 

Apá text-to-speech (TTS) orí fóònù ẹ ló ń pinnu bí àtẹ́tísí tó wà nínú ìsọ̀rí Grammar ṣe máa rí. Àtẹ́tísí tí iléeṣẹ́ tó ń ṣe àwọn fóònù iOS ṣe sí apá text-to-speech (TTS) ò fi bẹ́ẹ̀ dáa tó. O lè ṣe é tí àtẹ́tísí TTS orí fóònù ẹ á fi dáa sí i. Lọ sí Settings lórí fóònù ẹ, kó o wá lọ sí General > Accessibility > VoiceOver > Speech. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, lọ síhttps://support.apple.com/en-us/HT202362.

 

Primary language ni èdè tó o gbọ́. Tó o bá ti ń ṣètò JW Language sórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà ẹ, tẹ Primary Language kó o lè yan èdè tó o gbọ́.

Tún wo: Báwo ni mo ṣe lè yí primary language mi pa dà?

 

Tẹ Settings níbi ìbẹ̀rẹ̀, kó o wá yí èdè primary language rẹ pa dà níbi bọ́tìnì Primary Language.

 

Èdè tó o fẹ́ kọ́ là ń pè ní target language. Tó o bá ti ń sètò JW Language sórí fóònù ẹ, ó máa ní kó o yan èdè tó o fẹ́ kọ́.

Tún wo: Báwo ni mo ṣe lè yí target language mi pa dà?

 

Yan target language míì níbi tó o ti ń yan èdè.

Tún wo: Ṣé mo lè ní target language tó ju ẹyọ kan lọ?

 

Bẹ́ẹ̀ ni, o lè ní target language, ìyẹn èdè tó o fẹ́ kọ́, tó ju ẹyọ kan lọ. Tẹ bọ́tìnì tí wọ́n fi ń yan èdè, kó o wá yan èdè míì tó o fẹ́ kọ́.

See also: Báwo ni mo ṣe lè yí target language mi pa dà?

 

Tẹ àmì tó-tò-tó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán kan, kó o wá tẹ Add to Collection. Tẹ Create New Collection kó o lè ní ibi tí wàá máa kó nǹkan sí, o sì lè fún un lórúkọ tó o fẹ́. Tó o bá fi ọ̀rọ̀ kún àkójọ ẹ nígbà tó ò ń lo íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́wọ́, ó máa wa àtẹ́tísí rẹ̀ jáde sórí fóònù ẹ kó o lè lò ó tí ò bá sí íńtánẹ́ẹ̀tì mọ́.

 

Tẹ bọ́tìnì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwòrán tàbí ọ̀rọ̀ kan kó o lè ṣe ẹ̀dà ẹ̀ tàbí kó o yọ ọ́ kúrò. O lè fi mouse tàbí ìka fa àwọn àwòrán tàbí ọ̀rọ̀ tó o kó jọ kó o lè tún un tò.

 

Níbi tó o kó ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán jọ sí, tẹ Start Activity kó o lè rí àwọn ìdánrawò tó o lè ṣe:

  • Look: Yan ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó gbé wá tó jẹ́ ìtúmọ̀ ìbéèrè tó bi ẹ́

  • Match: Yan àwọn ọ̀rọ̀ àti àwòrán tó bára mu, tàbí àwọn ọ̀rọ̀ àti ìtúmọ̀ tó bára mu

  • Listen: Tẹ àtẹ́tísí ọ̀rọ̀ kan, kó o wá yan ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ ẹ̀

  • Flash Cards: Wò ó bóyá o mọ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ kan kó o tó ní kó gbé ìdáhùn wá. O lè ṣe é kó yára sọ̀rọ̀ tàbí kó falẹ̀. Tẹ àmì àtẹ́tísí kó o lè pa ohùn náà tàbí kó o tàn án.

  • Audio Lessons: Tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ kan. Tẹ Edit kí kọ̀ǹpútà lè bá ẹ to àwọn ọ̀rọ̀ náà tàbí kó o tò ó fúnra ẹ.

 

Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ Settings níbi ìbẹ̀rẹ̀, kó o wá tẹ bọ́tìnì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Show Romanization, kò ní fi álífábẹ́ẹ̀tì òde òní kọ ọ̀rọ̀ mọ́.

 

Kò sígbà tó ò lè wo ọ̀rọ̀ lórí JW Language, yálà íńtánẹ́ẹ̀tì wà àbí kò sí. Àmọ́ tó o bá ń lo íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́wọ́, tẹ ọ̀rọ̀ kan kó lè gbé àtẹ́tísí rẹ̀ jáde. Tó o bá fẹ́ wa àtẹ́tísí àti fídíò jáde kó o lè máa lò ó tí ò bá sí íńtánẹ́ẹ̀tì, tẹ bọ́tìnì tí wọ́n fi ń wa nǹkan jáde. Tó o bá fẹ́ wa gbogbo àtẹ́tísí àti fídíò tó wà ní èdè tó ò ń kọ́ jáde, lọ síbi tó o ti yan èdè, kó o wá tẹ bọ́tìnì Download All tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ target language.

 

Bẹ́ẹ̀ ni, o lè tọ́jú àwọn ìsọfúnni tó o kó jọ àti ìsọfúnni nípa àwọn ohun tó o fi ètò ìṣiṣẹ́ náà ṣe. Níbi Settings, yan ohun tó o fẹ́ lábẹ́ Back Up and Restore. Tó bá jẹ́ pé o ti tọ́jú ìsọfúnni tẹ́lẹ̀, o lè wà á jáde pa dà nígbàkigbà. Tó bá jẹ́ orúkọ tó o sọ àwọn ìsọfúnni tó o kó jọ sórí fóònù ẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ náà lo so èyí tó o ti tọ́jú tẹ́lẹ̀, tó o bá fẹ́ wa èyí tó o tọ́jú tẹ́lẹ̀ jáde, ṣe ló máa fi rọ́pò èyí tó ti wà lórí fóònù ẹ.

 

Ọ̀rẹ́ ẹ kan tó mọwọ́ JW Language lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó ò bá wá rẹ́ni ràn ẹ́ lọ́wọ́, kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù wa lórí ìkànnì,kó o sì fi ránṣẹ́.