Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Nìdí Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fí Ṣe Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí?

Kí Nìdí Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fí Ṣe Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí?

 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí tórí a gbà pé Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ sí irú àwọn ayẹyẹ bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, kò síbí kankan tí Bíbélì ti sọ ní pàtó pé má ṣe ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àmọ́, Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti ronú lórí àwọn ohun tí ó dá lé àti irú ojú tí Ọlọ́run fí ń wò ó. Gbé àwọn kókó mẹ́rin yìí yẹ̀ wò àti àwọn ìlànà Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

  1.   Ọ̀dọ̀ àwọn kèfèrí ni ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ti ṣẹ̀ wá. Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè kan tó ń jẹ́ Funk & Wagnalls Standard Dictionary of Folklore, Mythology, and Legend ṣe sọ, ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí wá látinú ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn pé, lọ́jọ́ tí ẹni kan bá ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀, “àwọn ẹ̀mí òkùnkùn lè gbéjà ko ẹni náà àmọ́ torí àwọn ọ̀rẹ́ onítọ̀hún tó pésẹ̀ síbẹ̀ àti bí àwọn èèyàn ṣe ń kí i, èyí kò ní lè jẹ́ káwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn náà ṣe é ní jàǹbá.” Ìwé The Lore of Birthdays sọ pé láyé àtijọ́, “àwọn awòràwọ̀ máa ń lo àkọsílẹ̀ ọjọ́ tí wọ́n bí ẹni kan láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ẹni náà lọ́jọ́ iwájú.” Ìwé yìí tún sọ pé “ẹ̀mí òkùnkùn ti máa ń wà lára àbẹ́là tí wọ́n ń lò nígbà ayẹyẹ ọjọ́ ìbí kí nǹkan tí ẹni tó ń ṣe ayẹyẹ náà fẹ́ lè ṣẹ.”

     Bíbélì ka idán pípa, wíwo ìṣẹ́, bíbá ẹ̀mí lò tàbí ṣíṣe “ohunkóhun bí èyí” léèwọ̀. (Diutarónómì 18:14; Gálátíà 5:​19-​21) Kódà, ọ̀kan lára ìdí tí Ọlọ́run fi pa ìlú Bábílónì àtijọ́ run ni pé àwọn tó ń gbé níbẹ̀ máa ń wòràwọ̀ èyí tó jẹ́ apá kan iṣẹ́ wíwò. (Aísáyà 47:11-​15) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í jẹ́ kí ibi tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti ṣẹ̀ wá gbà wá lọ́kàn, síbẹ̀ a kì í dágunlá sí àwọn àmì tí ó bá jẹ mọ́ ọn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

  2.   Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé “àṣà kèfèrí làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ka ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ẹnikẹ́ni sí.” Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn àpọ́sítélì àti àwọn míì tí Jésù kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ fúnra rẹ̀ fi ìtọ́ni tí gbogbo àwọn Kristẹni á máa tẹ̀ lé lélẹ̀.​—2 Tẹsalóníkà 3:6.

  3.   Ìrántí ikú Jésù lọ́ yẹ kí àwa Kristẹni máa ṣe kì í ṣe ti ọjọ́ ìbí. (Lúùkù 22:17-​20) Èyí ò yà wá lẹ́nu torí Bíbélì sọ pé “ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.” (Oníwàásù 7:1) Láwọn ìgbà tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, ó ṣe orúkọ rere fúnra rẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, nípa jíjẹ́ kí ọjọ́ ikú rẹ̀ ṣe pàtàkì ju ọjọ́ ìbí rẹ̀ lọ.​—Hébérù 1:4.

  4.   Bíbélì ò sọ nípa ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí. Kì í ṣe pé ọkàn àwọn tó kọ Bíbélì fò ó torí pé wọn ṣàkọsílẹ̀ àwọn méjì tí kì í ṣe ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí. Àmọ́, kò sí èyí tó yọrí sí rere nínú àwọn ayẹyẹ méjèèjì.​—Jẹ́nẹ́sísì 40:20-22; Máàkù 6:21-29.

Ṣé àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wo bí wọn kì í ṣé ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí bíi pé wọ́n ń fi ohun rere dù àwọn?

 Gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí rere ṣe máa ń ṣe, gbogbo ìgbà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ wọn, wọ́n máa ń fún wọn lẹ́bùn wọ́n sì máa ń gbádùn àkókò aláyọ̀ pa pọ̀. Wọ́n máa ń gbìyànjú láti tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere Ọlọ́run, ẹni tó mọ bí ó ti ń fi àwọn ohun rere fún àwọn ọmọ rẹ̀. (Mátíù 7:​11) Ohun tí àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ fi hàn pé wọn kì í wò ó bíi pé wọ́n fi ohun rere du àwọn:

  •   “Inú mi máa ń dùn gan an tí mo bá gba ẹ̀bùn nígbà tí mi ò retí rẹ̀.”​—Tammy, ọmọ ọdún 12.

  •   “Bí mi ò ti ẹ̀ gba ẹ̀bùn lọ́jọ́ ìbí mi, àìmọye ìgbà làwọn òbí mi máa ń ra ẹ̀bùn fún mi. Mo sì nífẹ̀ẹ́ sí i bẹ́ẹ̀ torí ó máa ń yà mí lẹ́nu.”​—Gregory, ọmọ ọdún 11.

  •   “Ṣé àríyá náà la máa pe ìyẹn, kẹ́ ẹ jẹ́ kéèkì kéékèèké, kẹ́ ẹ kọrin, gbogbo ẹ̀ láàárín ìṣẹ́jú mẹ́wàá? Ẹ máa bọ̀ nílé wa kẹ́ ẹ wá wo nǹkan tí wọ́n ń pè ní àríyá!”​—Eric, ọmọ ọdún 6.