Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?

Kí Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé ìlànà ìjọsìn tí Jésù kọ́ wa, tí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ náà tẹ̀ lé. Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn ohun tí a gbà gbọ́.

  1.   Ọlọ́run. À ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ tó jẹ́ Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà. (Sáàmù 83:18; Ìṣípayá 4:​11) Òun ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Mósè àti Jésù.​—Ẹ́kísódù 3:6; 32:11; Jòhánù 20:17.

  2.   Bíbélì. A mọ̀ pé ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, tó wà fún àwa èèyàn ni Bíbélì. (Jòhánù 17:17; 2 Tímótì 3:​16) Orí gbogbo ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] inú Bíbélì, tó ní nínú “Májẹ̀mú Láéláé” àti “Májẹ̀mú Tuntun,” la gbé ìgbàgbọ́ wa kà. Ohun tí ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Jason D. BeDuhn kọ nípa wa nìyẹn, ó sọ nínú ìwé rẹ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé “ìgbàgbọ́ àti ìṣe wọn ka orí ohun tí Bíbélì sọ láì bomi là á, wọ́n sì fara mọ́ ohun yòówù kí wọ́n bá níbẹ̀.” a

     Ti pé a gba gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì gbọ́ kò túmọ̀ sí pé a jẹ́ agbẹ́sìnkarí. A mọ̀ pé kò yẹ ká lóye àwọn apá kan nínú Bíbélì bí wọ́n ṣe kọ wọ́n ní tààràtà torí pé wọ́n kọ wọ́n láti fi ṣe àpẹẹrẹ tàbí ṣàpèjúwe nǹkan kan ni.​—Ìṣípayá 1:1.

  3.   Jésù. A máa ń tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù Kristi fi kọ́ni àti àpẹẹrẹ tó fi lélẹ̀, a sì ń bọ̀wọ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà wa àti Ọmọ Ọlọ́run. (Mátíù 20:28; Ìṣe 5:​31) Torí náà, Kristẹni ni wá. (Ìṣe 11:26) Àmọ́, nígbà tá a kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a rí i pé Jésù kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè àti pé kò sí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan nínú Bíbélì.​—Jòhánù 14:28.

  4.   Ìjọba Ọlọrun. Ìjọba kan tó máa ṣàkóso láti ọ̀run ni Ìjọba Ọlọrun, kì í ṣe ohun tó wà nínú ọkàn wa. Ìjọba yìí máa rọ́pò gbogbo ìjọba èèyàn, yóò sì mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ láyé. (Dáníẹ́lì 2:​44; Mátíù 6:​9, 10) Kò ní pẹ́ mọ́ tí Ìjọba Ọlọ́run á ṣe àwọn ohun tá a sọ yìí, ìdí ni pé àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí.​—2 Tímótì 3:​1-5; Mátíù 24:​3-​14.

     Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ọdún 1914 ló sì ti bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀.​—Ìṣípayá 11:15.

  5.   Ìgbàlà. Ikú ìrúbọ Jésù ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Mátíù 20:28; Ìṣe 4:​12) Kí àwọn èèyàn tó lè jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà yìí, wọ́n gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, kí wọ́n yí ìgbésí ayé wọn pa dà, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. (Mátíù 28:19, 20; Jòhánù 3:​16; Ìṣe 3:​19, 20) Àwọn ohun tí ẹnì kan bá ṣe ló máa fi hàn bóyá ó nígbàgbọ́. (Jákọ́bù 2:​24, 26) Àmọ́, a kò lè dédé rí ìgbàlà, nípasẹ̀ “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run” la fi lè rí i.​—Gálátíà 2:​16, 21.

  6.   Ọ̀run. Ọ̀run ni Jèhófà Ọlọ́run, Jésù Kristi àti àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ń gbé. b (Sáàmù 103:19-​21; Ìṣe 7:​55) Àwọn èèyàn kéréje kan tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ni Ọlọrun máa jí dìde sí ọ̀run láti bá Jésù jọba nínú Ìjọba náà.​—Dáníẹ́lì 7:​27; 2 Tímótì 2:​12; Ìṣípayá 5:​9, 10; 14:​1, 3.

  7.   Ayé. Ọlọ́run dá ayé yìí kí àwa èèyàn lè máa gbé inú rẹ̀ títí láé. (Sáàmù 104:5; 115:16; Oníwàásù 1:4) Ọlọ́run máa fún àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn ní ìlera pípé àti ìyè ayérayé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé.​—Sáàmù 37:11, 34.

  8.   Ìwà ibi àti ìjìyà. Ìgbà tí ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run di ọlọ̀tẹ̀ ni ìwà ibi àti ìjìyà bẹ̀rẹ̀. (Jòhánù 8:​44) Áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yẹn ni Bíbélì pè ní “Sátánì” àti “Èṣù” lẹ́yìn tó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọrun. Ó ṣi àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ lọ́nà, àwọn náà sì di ọlọ̀tẹ̀. Èyí wá kó àwọn àtọmọdọ́mọ wọn sí wàhálà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:​1-6; Róòmù 5:​12) Kí ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ lè yanjú, Ọlọ́run fàyè gba ìwà ibi àti ìjìyà, àmọ́ kò ní jẹ́ kó máa bá a lọ bẹ́ẹ̀.

  9.   Ikú. Àwọn tó bá kú ti di aláìsí. (Sáàmù 146:4; Oníwàásù 9:​5, 10) Wọn ò joró nínú ọ̀run àpáàdì.

     Ọlọ́run máa jí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó ti kú dìde nípasẹ̀ àjíǹde. (Ìṣe 24:15) Àmọ́, lẹ́yìn tí àwọn òkú bá jíǹde, àwọn tó bá kọ̀ láti tẹ̀ lé ọ̀nà Ọlọ́run nínú wọn máa pa run títí láé láì sí ìrètí àjíǹde kankan mọ́.​—Ìṣípayá 20:14, 15.

  10.   Ìdílé. Ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ lórí ìgbéyàwó là ń tẹ̀ lé ìyẹn ni pé kí ọkùnrin àti obìnrin fẹ́ ara wọn, kí wọ́n má sì ṣe kọ ara wọn sílẹ̀ àyàfi tí ẹnì kan nínú wọn bá ṣe ìṣekúṣe. (Mátíù 19:​4-9) Ó dá wa lójú pé àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì máa jẹ́ kí ìdílé ṣàṣeyọrí.​—Éfésù 5:22–​6:1.

  11.   Bí a ṣe ń jọ́sìn. A kì í jọ́sìn àgbélébùú tàbí àwọn ère míì. (Diutarónómì 4:​15-​19; 1 Jòhánù 5:​21) Àwọn nǹkan pàtàkì tí à ń ṣe nínú ìjọsìn wa ni pé:

  12.   Bí a ṣe ṣètò ara wa. A ṣètò ara wa sí ìjọ-ìjọ, ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ló sì ń bójú tó ìjọ kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, àwọn alàgbà yìí kì í ṣe ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà, wọn kì í sì í gbowó oṣù. (Mátíù 10:8; 23:8) A kì í san tàbí gba ìdá mẹ́wàá, bákan náà a kì í gbé igbá ọrẹ ní àwọn ìpàdé wa. (2 Kọ́ríńtì 9:7) Ọrẹ àtinúwá la fi ń ṣètìlẹyìn fún gbogbo iṣẹ́ wa.

     Àwùjọ àwọn Kristẹni kéréje kan tí wọ́n ní ìrírí, tí à ń pè ní Ìgbìmọ̀ Olùdarí ni Jèhófà ń ló láti máa tọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ́nà kárí ayé.​—Mátíù 24:45.

  13.   Ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa. Ìgbàgbọ́ wa ṣọ̀kan kárí ayé. (1 Kọ́ríńtì 1:​10) A tún máa ń sapá láti má ṣe gbé ìran kan, ẹ̀yà kan ga ju òmíràn lọ, kò sí àyè fún kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tàbí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́. (Ìṣe 10:34, 35; Jákọ́bù 2:4) Ìmọ̀ wa tó ṣọ̀kan kò ní ká má ṣe àwọn ìpinnu ara ẹni. Olúkálukú wa ló máa ń ṣèpinnu níbàámu pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tá a fi Bíbélì dá lẹ́kọ̀ọ́.​—Róòmù 14:​1-4; Hébérù 5:​14.

  14.   Ìwà wa. A máa ń sapá láti má ṣe ní ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. (Jòhánù 13:34, 35) A máa ń yẹra fún àwọn ìwà tí Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ sí, èyí ní nínú lílo ẹ̀jẹ̀ ní ìlòkulò nípa fífa ẹ̀jẹ̀ sára. (Ìṣe 15:28, 29; Gálátíà 5:​19-​21) Èèyàn àlááfíà ni wá, a kì í lọ́wọ́ sí ogun. (Mátíù 5:9; Aísáyà 2:4) A bọ̀wọ̀ fún ìjọba àti àwọn àṣẹ tí ìjọba pa, tí kò bá ti ta ko òfin Ọlọ́run.​—Mátíù 22:21; Ìṣe 5:​29.

  15.   Àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Jésù pàṣẹ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” Ó tún sọ pé àwa Kristẹni “kì í ṣe apá kan ayé.” (Mátíù 22:39; Jòhánù 17:16) A máa ń gbìyànjú láti “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn,” síbẹ̀ a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, a kì í sì í bá àwọn ẹlẹ́sìn míì da nǹkan pọ̀. (Gálátíà 6:​10; 2 Kọ́ríńtì 6:​14) Àmọ́, a máa ń bọ̀wọ̀ fún ìpinnu àwọn ẹlòmíì lórí ọ̀rọ̀ yìí.​—Róòmù 14:12.

 Tó o bá ní ìbéèrè lórí ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́, o lè ka púpọ̀ sí i nípa wa lórí ìkànnì wa, o lè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ọ́fíìsì wa, o sì lè lọ sí ọ̀kan lára àwọn ìpàdé tí a máa ń ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tó bá sún mọ́ ẹ tàbí kó o bá ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ sọ̀rọ̀.

a Wo ìwé Truth in Translation, ojú ìwé 165.

b Wọ́n ti lé àwọn áńgẹ́lì burúkú kúrò lọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí.​—Ìṣípayá 12:​7-9.