Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Todd Aki/Moment Open via Getty Images

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Asẹ́ Tó Wà Lẹ́nu Ẹja Àpátámàjà Ṣe Ń Ṣiṣẹ́

Bí Asẹ́ Tó Wà Lẹ́nu Ẹja Àpátámàjà Ṣe Ń Ṣiṣẹ́

 Bí ẹja Àpátámàjà tí wọ́n ń pè ní Manta ray ṣe máa ń jẹun ni pé, ó máa la ẹnu ẹ̀ tó bá ń wẹ̀ nínú òkun, omi àtàwọn ẹja wẹ́wẹ́, edé, akàn àtàwọn nǹkan tíntìntín míì máa wá wọ ẹnu ẹ̀. Asẹ́ kan wà ní ẹnu ẹja yìí tó máa ń sẹ́ àwọn nǹkan tó wọ ẹnu ẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Asẹ́ yìí máa jẹ́ kí àwọn ẹja tíntìntín tó wọ ẹnu ẹ̀ lọ sí ọ̀nà ọ̀fun ẹ̀ kó lè jẹ ẹ́. Àmọ́ asẹ́ náà máa jẹ́ kí omi tó wọ ẹnu ẹ̀ gba ihá tó wà ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹja náà jáde. Ohun kan tó gbàfiyèsí ni pé asẹ́ ẹnu ẹja àpátámàjà lè sẹ́ àwọn ẹja tó kéré gan-an tó yẹ kó bá omi jáde láti ihá ẹ̀, á sì gbé e lọ sí ọ̀nà ọ̀fun ẹ̀ kó lè jẹ wọ́n. Ed Yong tó jẹ́ oníròyìn nipa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé “bí asẹ́ náà ṣe ń sẹ́ àwọn ẹja tíntìntín láìjẹ́ kí wọ́n bómi lọ jọni lójú gan-an.”

 Rò ó wò ná: Asẹ́ ẹnu ẹja àpátámàjà yìí dà bí kóńbù tí wọ́n fi ń yarun tó ní ẹnu lọ́nà méjì. Èyí jẹ́ kó ṣeé ṣe fún asẹ́ ẹnu ẹja náà láti lọ sọ́tùn-ún sósì. Asẹ́ tó wà lẹ́nu ẹja náà máa pín omi tó ń wọ ẹnu ẹja yìí sọ́nà méjì, ọ̀kan á lọ sókè, èkejì á sì lọ sísàlẹ̀. Ìyẹn á wá mú kí omi náà máa yípo lẹ́nu ẹ̀.

 Bí omi ṣe ń yípo lẹ́nu ẹja yìí, gbogbo àwọn ẹja kékèké náà á máa ta sókè sódò títí wọ́n á fi kó sí ọ̀fun ẹja náà, á sì gbé wọn mì. Bí omi yìí ṣe ń yípo lọ́nà tó lágbára lẹ́nu ẹja yìí ni ò ní jẹ́ kí àwọn ẹja tíntìntín tó fẹ́ bá omi pa dà sínú òkun lè kọjá. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni agbára ìyípo omi ẹnu ẹja náà máa tì wọ́n pa dà sọ́fun ẹja yìí.

 Ohun míì ni pé, asẹ́ tó wà lẹ́nu ẹja yìí kì í jẹ́ kí ìdọ̀tí lè dúró lẹ́nu ẹ̀, ó sì tún máa ń fọ ẹnu ẹja náà láìka bí ẹja náà ṣe ń sáré nínú omi tó tàbí bí ohun tó kó sẹ́nu ṣe pọ̀ tó.

 Torí náà, ó wu àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti ṣe asẹ́ kan tó jọ bí asẹ́ ẹnu ẹja àpátámàjà ṣe ń ṣiṣẹ́, tó máa lè sẹ́ ìdọ̀tí àti oríṣiríṣi nǹkan tó lè pani lára tó wà nínú omi, kó lè ṣe é mu.

 Kí lèrò rẹ: Ṣé bí asẹ́ ẹnu ẹja àpátámàjà ṣe ń ṣiṣẹ́ kàn ṣàdédé wà ni, àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?