Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Eyín Ìgbín Limpet Ṣe Rí

Bí Eyín Ìgbín Limpet Ṣe Rí

 Limpet jẹ́ ìgbín inú òkun tó ní ìkarahun ṣóńṣó àti eyín tó lágbára lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Eyín rẹ̀ ní èròjà kan tá a mọ̀ sí goethite, èròjà yìí ní àwọn okùn tín-ń-rín tó dì mọ́ra wọn pinpin, ó sì wà lábẹ́ èròjà purotéènì tó ń mú nǹkan rọ̀.

 Rò ó wò ná: Ohun kan tó rí bí ahọ́n ló bo eyín ìgbín limpet tó rí kọrọdọ, díẹ̀ sì ni eyín rẹ̀ kọ̀ọ̀kan fi gùn ju orí abẹ́rẹ́ lọ (íǹṣì 3/⁠64). Eyín rẹ̀ kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ lágbára gan-an kó tó lè gé ewé tó fẹ́ jẹ lára àpáta.

 Àwọn olùṣèwádìí lo awò ọ̀nà jíjìn kan tó lágbára láti mọ bí eyín yìí ṣe lágbára tó. Wọ́n wá rí i pé nínú gbogbo ìwádìí tí wọ́n ti ń ṣe nínú ẹ̀yà ara, eyín ìgbín limpet ló lágbára jù lọ, ó tiẹ̀ tún lágbára ju okùn aláǹtakùn lọ. Olùṣèwádìí àgbà kan sọ pé: “Ó yẹ ká gbìyànjú láti ṣe ohun èlò tó rí bí eyín ìgbín limpet.”

 Àwọn olùṣèwádìí gbà pé táwọn bá ṣe ohun èlò tó rí bí eyín ìgbín limpet, wọ́n lè fi ṣe ọkọ̀, ọkọ̀ ojú omi, ọkọ̀ òfúrufú, kódà wọ́n lè fi ṣe eyín èèyàn pàápàá.

 Kí lèrò rẹ? Ṣé eyín ìgbín limpet tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí kan ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?