Ohun Téèyàn Lè Ṣe Tí Owó Tó Ń Wọlé Fúnni Bá Dín Kù
Ohun Téèyàn Lè Ṣe Tí Owó Tó Ń Wọlé Fúnni Bá Dín Kù
BÀBÁ ọlọ́mọ méjì ni Óbédì jẹ́. Ọdún mẹ́wàá ló fi ṣiṣẹ́ ní òtẹ́ẹ̀lì olówó ńlá kan ní ìlú ńlá kan nílẹ̀ Áfíríkà, ó sì lówó lọ́wọ́ débi pé ó fi gbogbo nǹkan tẹ́ ìdílé rẹ̀ lọ́rùn. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń wáyè láti kó ìdílé rẹ̀ rìnrìn àjò lọ gbafẹ́ nínú igbó àwọn ẹranko tí ìjọba yà sọ́tọ̀ ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Gbogbo èyí ni kò lè ṣe mọ́ nígbà tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí pé òtẹ́ẹ̀lì wọn kò fi bẹ́ẹ̀ rí àwọn oníbàárà mọ́.
Ó lé ní ọdún méjìlélógún tí Stephen fi ṣiṣẹ́ ní báńkì ńlá kan, ó sì dé ipò ọ̀gá níbẹ̀. Lára ohun tí wọ́n ṣe fún un torí ipò rẹ̀ ni pé, wọ́n pèsè ilé ńlá kan fún un tó ń gbé àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan àti àwọn ìránṣẹ́ tó ń tọ́jú ilé, wọ́n sì fi àwọn ọmọ rẹ̀ sí ilé ìwé àwọn ọmọ olówó. Ìgbà tí báńkì yẹn wá ń ṣe àwọn àyípadà kan ní ilé iṣẹ́ wọn, ni wọ́n ṣàdédé dáa dúró lẹ́nu iṣẹ́. Stephen sọ pé: “Ìbànújẹ́ ńlá bá èmi àti ìdílé mi. Jìnnìjìnnì bò mí, ọkàn mi gbọgbẹ́, ìrònú sì bá mi.”
Àwọn èèyàn yìí nìkan kọ́ ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí o. Ọrọ̀ ajé tó ti dẹnu kọlẹ̀ lágbàáyé ti sọ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn di aláìníṣẹ́ lọ́wọ́ mọ́. Àwọn tó bá sì jàjà ríṣẹ́ ṣe, owó táṣẹ́rẹ́ ni wọ́n ń san fún wọn, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ṣe ni gbogbo nǹkan túbọ̀ ń wọ́n gógó, tí ṣiṣẹ́-ṣiṣẹ́ fi wá dà bí ọ̀lẹ. Kò sí orílẹ̀-èdè tó bọ́ lọ́wọ́ ìyà òun ìṣẹ́ tí ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ ń fà, yálà orílẹ̀-èdè náà ti gòkè àgbà o tàbí kò tíì gòkè àgbà.
Ó Gba Ọgbọ́n
Bí owó tó ń wọlé fúnni bá dín kù tàbí tí iṣẹ́ bá bọ́ mọ́ni lọ́wọ́, kíá ni èròkérò lè gbani lọ́kàn. Lóòótọ́, kò sí bí èèyàn kò ṣe ní máa jáyà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ó ṣe tán, àìlówó-lọ́wọ́ baba ìjayà. Àmọ́ nígbà kan, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” (Òwe 24:10) Dípò téèyàn á fi jẹ́ kí jìnnìjìnnì bo òun nígbà tí ọrọ̀ ajé kò bá lọ déédéé, ṣe ló yẹ ká ṣe bí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe gbà wá nímọ̀ràn. Ó ní: “To ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ jọ.”—Òwe 2:7.
Lóòótọ́, Bíbélì kì í ṣe ìwé atọ́nà lórí ọ̀rọ̀ ìṣúnná owó, síbẹ̀ ìmọ̀ràn rẹ̀ tó wúlò ti ṣe ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé láǹfààní gan-an. Jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò nínú àwọn ìlànà tí Bíbélì fún wa.
Gbéṣirò lé ohun tó o fẹ́ ṣe. Nínú ìwé Lúùkù 14:28, Jésù sọ pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?” Tá a bá tẹ̀ lé ìlànà yìí, a ó ṣe ètò ìnáwó wa sílẹ̀, a ó sì máa tẹ̀ lé e. Ṣùgbọ́n bí Óbédì ṣe sọ, èyí kò rọrùn láti ṣe. Óbédì ní: “Nígbà tí iṣẹ́ kò tíì bọ́ lọ́wọ́ mi, tá a bá dé ilé ìtajà ṣe la máa ń ra tibí ra tọ̀hún, yálà a nílò rẹ̀ tàbí a kò nílò rẹ̀. A kò ní ètò ìnáwó kankan torí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tó wù wá láti rà tí a kò ní lè rà.” Àmọ́ tí ètò ìnáwó bá ti wà, ìyẹn á jẹ́ kí ẹ lè pinnu bí ẹ ṣe máa ná ìwọ̀nba owó tó bá wà sórí àwọn nǹkan pàtàkì tí ìdílé nílò.
Ṣe àyípadà tó bá yẹ. Kì í sábà rọrùn pé kéèyàn fara mọ́ gbígbé ìgbé ayé tó rẹlẹ̀ sí ti tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tó yẹ kéèyàn ṣe nìyẹn. Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Ọlọgbọn eniyan ti ri ibi tẹlẹ̀, o si pa ara rẹ̀ mọ.” (Òwe 22:3, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Stephen sọ pé: “Láti dín ìnáwó kù, ṣe ni èmi àti ìdílé mi kó lọ sí ilé wa tá a kọ́, tó kéré sí ilé tí báńkì fún wa láti máa gbé tẹ́lẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kò tíì parí iṣẹ́ inú àwọn yàrá rẹ̀. Àwọn ọmọ wa ní láti kúrò ní ilé ìwé tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí èyí tí owó rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ àmọ́ tí wọ́n ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ gidi.”
Ó ṣe pàtàkì pé kí ìdílé jọ máa jíròrò pọ̀ dáadáa kí àyípadà tí wọ́n ń ṣe láti máa gbé ìgbé ayé tó rẹlẹ̀ sí ti tẹ́lẹ̀ lè kẹ́sẹ járí. Ọ̀gbẹ́ni Austin, tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́sàn-án tó ti ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ kan tí iṣẹ́ wọn jẹ mọ́ ètò ọ̀rọ̀ ajé, sọ pé: “Èmi àti aya mi jọ jókòó a sì kọ àwọn nǹkan tó jẹ́ kòṣeémánìí fún wa sílẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ. A wá dín bí a ṣe ń náwó lórí àwọn oúnjẹ tó gbówó lórí kù àti bí a ṣe ń náwó lórí ìrìn àjò afẹ́ àti bí a ṣe ń ra aṣọ tuntun tí kò pọn dandan. Inú mi sì dùn pé ìdílé mi bá mi fọwọ́ sowọ́ pọ̀ bí a ṣe ń ṣe àwọn àyípadà náà.” Lóòótọ́, àwọn ọmọdé lè má fi bẹ́ẹ̀ rí ìdí tó fi yẹ kí irú àwọn àyípadà bẹ́ẹ̀ wáyé, àmọ́ ẹ̀yin òbí lẹ máa fara balẹ̀ ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn.
Múra tán láti ṣe oríṣi iṣẹ́ míì. Tó bá jẹ́ iṣẹ́ alákọ̀wé ló mọ́ ọ lára, ó lè máà yá ọ lára láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́. Ọ̀gbẹ́ni Austin sọ pé: “Ó ṣòro fún mi gan-an láti dẹni tó ń ṣe iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, torí ọ̀gá ni mo jẹ́ tẹ́lẹ̀ ní ilé iṣẹ́ ńlá kan.” Èyí kò sì yani lẹ́nu, torí ìwé Òwe 29:25 sọ pé: “Wíwárìrì nítorí ènìyàn ni ohun tí ń dẹ ìdẹkùn.” Tó bá jẹ́ pé ojú tí àwọn èèyàn lè máa fi wò ọ́ lo fẹ́ fi pinnu irú iṣẹ́ tó o máa ṣe, ṣe ni wàá kàn febi pa ìdílé rẹ. Kí lo máa ṣe tí irú èròkerò bẹ́ẹ̀ kò fi ní gbà ọ́ lọ́kàn?
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ló yẹ kó o ní. Nígbà tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Óbédì ní òtẹ́ẹ̀lì tó ti ń ṣiṣẹ́, ẹni tí wọ́n jọ jẹ́ òṣìṣẹ́ níbì kan tẹ́lẹ̀ rí, sọ pé kó jẹ́ kí àwọn jọ máa ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ mẹkáníìkì òun. Iṣẹ́ náà gba pé kó máa fẹsẹ̀ rin ọ̀nà jíjìn káàkiri ìgboro eléruku láti máa ra ọ̀dà àti ẹ̀yà ara mọ́tò tí wọ́n máa lò níbi iṣẹ́. Óbédì sọ pé: “Mi ò fẹ́ràn iṣẹ́ yìí rárá, àmọ́ kò sí ọ̀nà míì tí mo tún lè gbé e gbà. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ló jẹ́ kí n lè ṣe irú iṣẹ́ yìí tí mo ti ń gba owó tí kò tó ìdá mẹ́rin owó oṣù mi ti tẹ́lẹ̀ àmọ́ tó jẹ́ pé ó tó mi gbọ́ bùkátà ìdílé mi.” Ǹjẹ́ ìwọ náà lè ní irú ẹ̀mí dáadáa tó ní yìí?
Ní ìtẹ́lọ́rùn. Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ẹni tó bá ní ìtẹ́lọ́rùn “máa ń láyọ̀, ọkàn rẹ̀ sì máa ń balẹ̀ déwọ̀n àyè kan nínú ipò tó wà àti bí nǹkan ṣe ń lọ fún un.” Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe lójú ẹni tí owó ń jẹ níyà. Àmọ́, wo ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ míṣọ́nnárì tó mọ bí ipò àìní ṣe máa ń rí lára sọ, ó ní: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́, nínú àwọn ipò yòówù tí mo bá wà, láti máa ní ẹ̀mí ohun-moní-tómi. Ní tòótọ́, mo mọ bí a ṣe ń wà pẹ̀lú àwọn ìpèsè bín-ín-tín, ní tòótọ́ mo mọ bí a ṣe ń ní ọ̀pọ̀ yanturu.”—Fílípì 4:11, 12.
Ipò tiwa lè má le tó èyí tá a sọ yìí, àmọ́ lásìkò tí ọrọ̀ ajé ń ṣe ségesège yìí, nǹkan lè burú ju bá a ṣe rò lọ. Ṣùgbọ́n, ohun tó máa dáa ni pé ká fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Láìsí àní-àní, ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí kò túmọ̀ sí pé ká wá ya ọ̀lẹ kalẹ̀ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló kàn ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fi àwọn nǹkan ti ara sí ipò tó yẹ kí wọ́n wà.—1 Tímótì 6:6, 8.
Orísun Ayọ̀ Tòótọ́
Kì í ṣe kíkó ọrọ̀ jọ tàbí gbígbé ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì ló máa ń jẹ́ kí èèyàn ní ojúlówó ayọ̀. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” Ní tòdodo, èèyàn máa ń rí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn nínú lílo ohun tó bá ní láti máa fi ṣe àwọn ẹlòmíì lóore, kéèyàn sì tún jẹ́ ẹni tó ń fún àwọn èèyàn ní ìṣírí.—Ìṣe 20:35.
Jèhófà Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wa mọ gbogbo ohun tá a nílò pátápátá. Ó sì ti pèsè àwọn ìmọ̀ràn tó yanranntí sínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wa, èyí tó ti mú kí ìgbé ayé ọ̀pọ̀ èèyàn sunwọ̀n, kí wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ ìdààmú ọkàn tí kò nídìí. Lóòótọ́, téèyàn bá ń fi irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ sílò kò túmọ̀ sí pé èèyàn á kàn ṣàdédé di olówó. Ṣùgbọ́n Jésù fi dá àwọn tó bá ń bá a nìṣó ní “wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́” lójú pé wọ́n á máa rí gbogbo nǹkan kòṣeémánìí tí wọ́n nílò fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan gbà.—Mátíù 6:33.