Ǹjẹ́ o Mọ̀?
Ǹjẹ́ o Mọ̀?
Kí nìdí tí àwọn Júù fi ka ìtàn ìlà ìdílé wọn sí nǹkan pàtàkì?
▪ Àkọsílẹ̀ ìtàn ìlà ìdílé ṣe pàtàkì, torí òun ni wọ́n ń lò láti fi fìdí ẹ̀rí ẹ̀yà tàbí ìdílé tí ẹnì kan ti wá múlẹ̀. Wọ́n tún máa ń lò ó láti fi pinnu ohun tó jẹ́ ogún tàbí ilẹ̀ ẹnì kan. Èyí tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù ni ìtàn ìlà ìdílé tí Mèsáyà ti Ọlọ́run ṣèlérí ti máa wá. Àwọn Júù mọ̀ pé Ẹni yìí gbọ́dọ̀ wá láti ìlà ìdílé Dáfídì ní ẹ̀yà Júdà.—Jòhánù 7:42.
Bákan náà, ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Joachim Jeremias sọ pé: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ó ní ìlà ìdílé àwọn tó máa ń jẹ́ àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì . . . ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí ìran wọn máa bá a lọ bẹ́ẹ̀ láìjẹ́ kí àwọn èèyàn ẹ̀yà míì dà pọ̀ mọ́ wọn.” Obìnrin ọmọ Ísírẹ́lì tó bá máa fẹ́ ẹnikẹ́ni nínú ìdílé àlùfáà gbọ́dọ̀ fi ẹ̀rí hàn pé ìdílé àlùfáà ni òun náà ti wá, kí ìdílé àwọn àlùfáà má bàa di “irú-wá ògìrì-wá.” Nígbà ayé Nehemáyà, wọ́n tiẹ̀ yọ odindi àwọn ìdílé kan lára àwọn ọmọ Léfì nípò nígbà tí wọ́n “wá àkọsílẹ̀ orúkọ wọn, láti fi ìdí ìtàn ìlà ìdílé wọn múlẹ̀ ní gbangba, [tí wọn] kò sì rí i.”—Nehemáyà 7:61-65.
Láfikún sí èyí, Òfin Mósè sọ ọ́ ní pàtó pé “ọmọ àlè kankan” tàbí “ọmọ Ámónì tàbí ọmọ Móábù kankan kò gbọ́dọ̀ wá sínú ìjọ Jèhófà.” (Diutarónómì 23:2, 3) Ọ̀gbẹ́ni Jeremias wá sọ pé, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé “èèyàn gbọ́dọ̀ lè fìdí ìran tó ti wá múlẹ̀ kí ọwọ́ rẹ̀ tó lè tẹ àwọn ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ ọmọ ìlú, ìyẹn sì fi hàn pé òótọ́ ni ohun tá a sọ, pé . . . kódà púrúǹtù nínú ọmọ Ísírẹ́lì mọ àwọn àtìrandíran rẹ̀, á sì lè sọ ẹ̀yà tó ti wá nínú ẹ̀yà méjèèjìlá.”
Báwo ni àwọn Júù ṣe ń ṣàkójọ ìtàn ìlà ìdílé wọn, báwo ni wọ́n sì ṣe ń pa á mọ́?
▪ Ìwé Ìhìn Rere ti Mátíù àti Lúùkù sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn àwọn tó jẹ́ baba ńlá Jésù. (Mátíù 1:1-16; Lúùkù 3:23-38) Àwọn Júù míì náà sì ní àkọsílẹ̀ ìtàn ìlà ìdílé tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé àlàyé lórí Bíbélì, èyí tí àwọn Júù ṣe, tí wọ́n ń pè ní midrash, sọ̀rọ̀ nípa rábì kan nígbà ayé Jésù tó ń jẹ́ Hílẹ́lì, pé: “Wọ́n rí àkájọ ìwé ìtàn ìlà ìdílé kan ní Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n kọ sínú rẹ̀ pé Hílẹ́lì jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì.” Òpìtàn Flavius Josephus tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní sọ nínú ìwé rẹ̀ kan tó ń jẹ́ The Life, pé àlùfáà ni àwọn baba ńlá òun àti pé “ọmọ ọba ni òun láti ìdílé ìyá òun.” Ó ní inú “ìwé àkọsílẹ̀ ti ìlú” ni òun ti rí i bẹ́ẹ̀.
Nígbà tí òpìtàn Josephus ń sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń pa àkọsílẹ̀ ìdílé àwọn àlùfáà mọ́ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Against Apion, ó sọ pé “àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ jù” ní orílẹ̀-èdè òun ni wọ́n fa iṣẹ́ yẹn lé lọ́wọ́. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The Jewish Encyclopedia sọ pé: “Ó jọ pé ìkáwọ́ ọ̀gá kan tí wọ́n dìídì yàn ni àwọn àkọsílẹ̀ náà máa ń wà, wọ́n sì sọ pé wọ́n gbé ilé ẹjọ́ kan kalẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìtàn ìlà ìdílé.” Ní ti àwọn Júù tí kì í ṣe ara ìdílé àlùfáà, wọ́n máa ń lọ fi orúkọ sílẹ̀ ní ìlú bàbá wọn. (Lúùkù 2:1-5) Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere lọ ṣèwádìí nínú irú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ tó jẹ́ ti ìlú. Bákan náà, ó jọ pé ìdílé kọ̀ọ̀kan máa ń ní ìwé ìtàn ìlà ìdílé tirẹ̀.