Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Dájú Pé Ọjọ́ Ọ̀la Ẹnì Kan Á Dáa Tó Bá Ṣáà Ti Ń Hùwà Tó Dáa?

Ṣó Dájú Pé Ọjọ́ Ọ̀la Ẹnì Kan Á Dáa Tó Bá Ṣáà Ti Ń Hùwà Tó Dáa?

Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti gbà pé téèyàn bá ṣáà ti ń hùwà rere, ó dájú pé ọkàn ẹ̀ máa balẹ̀, ọjọ́ ọ̀la ẹ̀ á sì dáa. Àpẹẹrẹ kan ni ọ̀rọ̀ tí ọ̀jọ̀gbọ́n ọmọ ilẹ̀ Éṣíà kan tó ń jẹ́ Confucius tó gbé ayé ní 551 sí 479 Ṣ.S.K. sọ. Ó ní: “Ohun tí o kò bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí ọ, kí ìwọ náà má ṣe é sí wọn.” * Ọ̀pọ̀ èèyàn nílẹ̀ Éṣíà ló sì gbà pé ọ̀rọ̀ pàtàkì lohun tó sọ yẹn.

OHUN TỌ́PỌ̀ ÈÈYÀN GBÀ GBỌ́

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì gbà pé táwọn bá ń hùwà tó dáa, ọjọ́ ọ̀la àwọn máa dáa. Torí náà, wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fúnni, wọ́n máa ń ṣe ojúṣe wọn, wọ́n sì máa ń ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Vietnam sọ pé: “Èrò mi ni pé tí mo bá ṣáà ti jẹ́ olóòótọ́, tí mo sì ń finú kan bá àwọn èèyàn lò, ọ̀nà á máa là fún mi.”

Ohun táwọn kan kọ́ nínú ẹ̀sìn wọn ló ń mú kí wọ́n máa hùwà rere. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Hsu-Yun lórílẹ̀-èdè Taiwan sọ pé: “Àtikékeré ni wọ́n ti kọ́ mi pé téèyàn bá hùwà rere láyé inú ìgbádùn ló máa bọ́ sí lẹ́yìn tó bá kú, àmọ́ téèyàn bá hùwà burúkú inú ìyà àti ìnira ló máa bọ́ sí lẹ́yìn tó bá kú.”

ṢÉ ÌWÀ RERE MÁA Ń JẸ́ KÍ ỌKÀN ÈÈYÀN BALẸ̀ LÓÒÓTỌ́?

Òótọ́ ni pé èèyàn máa rí ọ̀pọ̀ àǹfààní tó bá ń hùwà tó dáa. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń hùwà tó dáa ló ti wá rí i pé pẹ̀lú gbogbo báwọn ṣe ń hùwà tó dáa sáwọn èèyàn ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ibi ni wọ́n fi ń san án fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ń jẹ́ Shiu Ping, tó ń gbé ní Hong Kong sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti jẹ́ kí n rí i pé gbogbo ìgbà téèyàn bá hùwà tó dáa kọ́ ló lè máa retí pé òun máa rí èrè níbẹ̀. Mo máa ń ṣe ojúṣe mi nínú ìdílé, mo sì máa ń hùwà tó dáa. Síbẹ̀, ọkọ mi pa èmi àti ọmọkùnrin mi tì, ìdílé mi sì tú ká.”

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá rí i pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run ló máa ń hùwà tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ń jẹ́ Etsuko lórílẹ̀-èdè Japan sọ pé: “Mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan tó máa ń ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ nílé ìjọsìn tí mo wà, mo sì di ọ̀kan lára àwọn aṣáájú nínú ẹgbẹ́ náà. Àmọ́, ó yà mí lẹ́nu nígbà tí mo rí báwọn ọmọ ìjọ náà ṣe ń ṣèṣekúṣe, tí wọ́n ń bára wọn du ipò, tí wọ́n sì ń ná owó ìjọ bó ṣe wù wọ́n.”

“Mo máa ń ṣe ojúṣe mi nínú ìdílé, mo sì máa ń hùwà tó dáa. Síbẹ̀, ọkọ mi pa èmi àti ọmọkùnrin mi tì, ìdílé mi sì tú ká.”​—SHIU PING, HONG KONG

Nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ń fìtara ṣe ẹ̀sìn tí wọ́n sì ń hùwà tó dáa, ó máa ń dùn wọ́n gan-an. Bí ọ̀rọ̀ obìnrin kan tó ń jẹ́ Van lórílẹ̀-èdè Vietnam ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni mo máa ń gbé èso, òdòdó àti oúnjẹ lọ sí ojúbọ láti tu àwọn baba ńlá mi tó ti kú lójú. Torí mo gbà pé ìyẹn á jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀, kí ọjọ́ ọ̀la mi sì dáa. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo bí mo ṣe ń hùwà tó dáa, tí mo sì fi ọ̀pọ̀ ọdún ṣe àwọn ètùtù tó yẹ kí n ṣe, àìsàn kan tó lágbára ṣe ọkọ mi. Nígbà tó yá, ọmọbìnrin mi tó lọ kàwé lókè òkun ṣàdédé kú.”

Tí ìwà rere nìkan ò bá tó láti fini lọ́kàn balẹ̀ pé ọjọ́ ọlà èèyàn á dáa, kí wá ló lè fini lọ́kàn balẹ̀? Tá a bá fẹ́ mọ ìdáhùn ìbéèrè yìí, àfi ká rí amọ̀nà kan tó ṣeé gbára lé. Ibo la ti lè rí amọ̀nà yẹn?

^ ìpínrọ̀ 2 Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí Confucius kọ́ni, wo orí 7, ìpínrọ̀ 31-35, nínú ìwé Mankind’s Search for God. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí, ó sì wà lórí ìkànnì www.isa4310.com.