Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ILÉ ÌṢỌ́ No. 3 2021 | Kí Ló Lè Mú Kí Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Dáa?

Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la ẹ dáa? Tó o bá ka ìwé yìí, wàá rí oríṣiríṣi nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe torí pé wọ́n fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wọn dáa. Wàá tún rí ohun kan ṣoṣo tó lè mú kí ọjọ́ ọ̀la ẹ dáa.

 

Gbogbo Èèyàn Ló Fẹ́ Kí Ọjọ́ Ọ̀la Wọn Dáa

Táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan bá mú kí nǹkan ṣàdédé dojú rú, ibo lo ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó dáa jù lọ?

Kí Ló Máa Ń Pinnu Bí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ṣe Máa Rí?

Èrò ọ̀pọ̀ àwọn tó gbà gbọ́ nínú wíwo ìràwọ̀, feng shui tàbí ìjọsìn àwọn baba ńlá títí kan àtúnwáyé ni pé agbára abàmì kan ló ń pinnu bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí.

Ṣó Dájú Pé Ọjọ́ Ọ̀la Ẹnì Kan Á Dáa Tó Bá Kàwé Dáadáa Tó Sì Lówó Rẹpẹtẹ?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí i pé bẹ́nì kan bá tiẹ̀ kàwé dáadáa tó sì lówó rẹpẹtẹ, ìyẹn ò sọ pé ọjọ́ ọ̀la ẹni náà á dáa.

Ṣó Dájú Pé Ọjọ́ Ọ̀la Ẹnì Kan Á Dáa Tó Bá Ṣáà Ti Ń Hùwà Tó Dáa?

Ó dáa kéèyàn máa hùwà rere lóòótọ́, àmọ́ ti pé ẹnì kan ń hùwà rere ò túmọ̀ sí pé ọkàn ẹ̀ máa balẹ̀ tàbí pé ọjọ́ ọ̀la ẹ̀ máa dáa.

Amọ̀nà Tó Ṣeé Gbára Lé Nípa Bí Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ṣe Máa Dáa

Tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, a sábà máa ń fẹ́ gba ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ ẹni tó dàgbà tó sì tún gbọ́n jù wá lọ. Lọ́nà kan náà, a lè rí ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé nípa bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí.

Ohun Tó Lè Mú Kí Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ Dáa

Kí ló lè mú kí ọjọ́ ọ̀la rẹ dáa?