Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo La Ṣe Máa Ṣẹ́gun Ikú?

Báwo La Ṣe Máa Ṣẹ́gun Ikú?

BÓ TIẸ̀ jẹ́ pé àìgbọràn àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà ti mú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wá sórí gbogbo aráyé, ìyẹn kò yí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé pa dà. Ọlọ́run tẹnu mọ́ ọn léraléra nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun kò ní yí ohun tí òun ní lọ́kàn pa dà.

  • “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”​Sáàmù 37:29.

  • “Ó máa gbé ikú mì títí láé, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sì máa nu omijé kúrò ní ojú gbogbo èèyàn.”​Àìsáyà 25:8.

  • “Ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn ni a ó sọ di asán.”​1 Kọ́ríńtì 15:26.

  • “Ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”​Ìfihàn 21:4.

Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa “gbé ikú mì” tàbí báwo ló ṣe máa sọ ikú “di asán”? Bá a ṣe mọ̀, Bíbélì sọ ní kedere pé: “Àwọn olódodo . . . yóò máa gbé títí láé.” Ó tún sọ pé “kò sí olódodo kankan láyé tó ń ṣe rere nígbà gbogbo tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” (Oníwàásù 7:20) Ṣé Ọlọ́run máa pa ìlànà rẹ̀ tì kó lè ṣẹ́gun ikú ni? Rárá o! Kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé, torí pé “Ọlọ́run . . . kò lè parọ́.” (Títù 1:2) Kí wá ni Ọlọ́run máa ṣe kí ohun tó ní lọ́kàn tó fi dá èèyàn lè ṣẹ?

ỌLỌ́RUN “MÁA GBÉ IKÚ MÌ TÍTÍ LÁÉ.”​—ÀÌSÁYÀ 25:8

ÌRÀPADÀ LÓ ṢẸ́GUN IKÚ

Jèhófà Ọlọ́run fìfẹ́ ṣètò láti ra aráyé pa dà kúrò lọ́wọ́ ikú. Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ìràpadà tó san. Ohun tí ìràpadà túmọ̀ sí ni pé kéèyàn san nǹkan pa dà láti fi kájú ohun tó ti bà jẹ́ tàbí láti ṣe ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu. Torí pé gbogbo èèyàn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí a sì ti gba ìdájọ́ ikú, Bíbélì sọ ní kedere pé: “Kò sí ìkankan nínú wọn tó lè ra arákùnrin kan pa dà tàbí tí ó lè fún Ọlọ́run ní ìràpadà nítorí rẹ̀, (Iye owó ìràpadà ẹ̀mí wọn ṣe iyebíye débi pé ó kọjá ohun tí ọwọ́ wọn lè tẹ̀).”​—Sáàmù 49:​7, 8.

Tí èèyàn aláìpé kan bá kú, ńṣe ló kàn san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ tiẹ̀ nìkan; onítọ̀hún kò lè ra ara rẹ̀ pa dà tàbí kó san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíì. (Róòmù 6:7) A nílò ẹni pípé, tí kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ láti fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, kì í ṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀ àmọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tiwa.​—Hébérù 10:​1-4.

Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni Ọlọ́run pèsè fún wa. Ó rán Jésù Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run wá sí ayé, a sì bí i ní ẹni pípé, tí kò lẹ́ṣẹ̀ kankan. (1 Pétérù 2:22) Jésù sọ pé òun wá láti “fi ẹ̀mí [òun] ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.” (Máàkù 10:45) Ó kú kó lè ṣẹ́gun ikú tó jẹ́ ọ̀tá wa, kí á lè ní ìyè.​—Jòhánù 3:16.

ÌGBÀ WO LA MÁA ṢẸ́GUN IKÚ?

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ‘àkókò kan ń bọ̀ tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira.’ A ti wà ní àkókò náà báyìí, èyí sì fi hàn pé a ti ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan búburú yìí. (2 Tímótì 3:1) Ọjọ́ ìkẹyìn máa parí sí “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn èèyàn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Pétérù 3:​3, 7) Àmọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa la ìparun náà já, wọ́n á sì gba ìbùkún “ìyè àìnípẹ̀kun.”​—Mátíù 25:46.

Jésù wá láti “fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.”​—Máàkù 10:45

Àìmọye èèyàn ló máa ní àǹfààní láti ní ìyè àìnípẹ̀kun nígbà tí wọ́n bá jí dìde. Nígbà tí Jésù lọ sí ìlú Náínì, ó jí ẹnì kan dìde. Opó kan ní ọmọkùnrin kan ṣoṣo, ọmọ náà sì kú. “Àánú rẹ̀ ṣe” Jésù, ó sì jí ọmọ náà dìde. (Lúùkù 7:​11-15) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ní ìrètí nínú Ọlọ́run . . . pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” Ìrètí tó dájú yìí jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ aráyé.​—Ìṣe 24:15.

Àìmọye èèyàn ló máa láǹfààní láti wà láàyè títí láé. Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.” (Sáàmù 37:29) Nígbà yẹn, inú wọn máa dùn torí pé wọ́n á lè sọ ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn, pé: “Ikú, ìṣẹ́gun rẹ dà? Ikú, oró rẹ dà?” (1 Kọ́ríńtì 15:55) Níkẹyìn, a máa ṣẹ́gun ìkú tó jẹ́ ọ̀tá burúkú tó ń bá aráyé fínra!