Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì 15:1-58

  • Àjíǹde Kristi (1-11)

  • Àjíǹde jẹ́ ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ (12-19)

  • Àjíǹde Kristi jẹ́ àmì ìdánilójú (20-34)

  • Ara ìyára àti ara tẹ̀mí (35-49)

  • Àìkú àti àìdíbàjẹ́ (50-57)

  • Ẹ ní ohun púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa (58)

15  Ní báyìí, ẹ̀yin ará, mò ń rán yín létí ìhìn rere tí mo kéde fún yín,+ èyí tí ẹ gbà, tí ẹ ò sì yà kúrò nínú rẹ̀.  Ipasẹ̀ rẹ̀ ni ẹ tún máa fi rí ìgbàlà, tí ẹ bá di ìhìn rere tí mo kéde fún yín mú ṣinṣin, àfi tó bá jẹ́ pé lásán lẹ di onígbàgbọ́.  Nítorí lára àwọn ohun tí mo kọ́kọ́ fi lé yín lọ́wọ́ ni ohun tí èmi náà gbà, pé Kristi kú nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ;+  àti pé a sin ín,+ bẹ́ẹ̀ ni, pé a jí i dìde+ ní ọjọ́ kẹta+ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ;+  àti pé ó fara han Kéfà,*+ lẹ́yìn náà, àwọn Méjìlá náà.+  Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han èyí tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo,+ púpọ̀ nínú wọn ṣì wà pẹ̀lú wa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn díẹ̀ ti sùn nínú ikú.  Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han Jémíìsì,+ lẹ́yìn náà, gbogbo àpọ́sítélì.+  Àmọ́ ní paríparí rẹ̀, ó fara han èmi náà+ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó.  Nítorí èmi ló kéré jù nínú àwọn àpọ́sítélì, mi ò sì yẹ lẹ́ni tí à ń pè ní àpọ́sítélì, torí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run.+ 10  Àmọ́ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́. Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ lórí mi kò já sí asán, àmọ́ mo ṣiṣẹ́ ju gbogbo wọn lọ; síbẹ̀ kì í ṣe èmi, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tó wà pẹ̀lú mi ni. 11  Torí náà, ì báà jẹ́ èmi tàbí àwọn, bí a ṣe ń wàásù nìyí, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ ṣe gbà gbọ́. 12  Ní báyìí, tí a bá ń wàásù pé a ti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú,+ kí nìdí tí àwọn kan láàárín yín fi ń sọ pé kò sí àjíǹde àwọn òkú? 13  Tó bá jẹ́ òótọ́ ni pé kò sí àjíǹde àwọn òkú, á jẹ́ pé a kò tíì gbé Kristi dìde. 14  Àmọ́ tí a ò bá tíì gbé Kristi dìde, ó dájú pé asán ni ìwàásù wa, asán sì ni ìgbàgbọ́ yín. 15  Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á mú wa ní ẹlẹ́rìí èké sí Ọlọ́run,+ torí a ti jẹ́rìí èké pé Ọlọ́run gbé Kristi dìde,+ ẹni tí kò gbé dìde tó bá jẹ́ pé a ò ní gbé àwọn òkú dìde lóòótọ́. 16  Nítorí tí a ò bá ní gbé àwọn òkú dìde, á jẹ́ pé a kò tíì gbé Kristi dìde. 17  Láfikún sí i, bí a ò bá tíì gbé Kristi dìde, ìgbàgbọ́ yín kò wúlò; ẹ ṣì wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.+ 18  Bákan náà, àwọn tó ti sun oorun ikú nínú Kristi ti ṣègbé.+ 19  Tó bá jẹ́ pé inú ìgbésí ayé yìí nìkan la ti ní ìrètí nínú Kristi, àwa ló yẹ kí wọ́n káàánú jù lọ nínú gbogbo èèyàn. 20  Àmọ́ ní báyìí, a ti gbé Kristi dìde kúrò nínú ikú, àkọ́so nínú àwọn tó ti sùn nínú ikú.+ 21  Nítorí bí ikú ṣe wá nípasẹ̀ ẹnì kan,+ àjíǹde òkú náà wá nípasẹ̀ ẹnì kan.+ 22  Nítorí bí gbogbo èèyàn ṣe ń kú nínú Ádámù,+ bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ gbogbo èèyàn di ààyè nínú Kristi.+ 23  Àmọ́ kálukú wà ní àyè rẹ̀: Kristi àkọ́so,+ lẹ́yìn náà àwọn tó jẹ́ ti Kristi nígbà tó bá wà níhìn-ín.+ 24  Ẹ̀yìn ìyẹn ni òpin, nígbà tó bá fi Ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́, lẹ́yìn tó ti sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo àṣẹ àti agbára di asán.+ 25  Torí ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọba tí á máa ṣàkóso títí Ọlọ́run á fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.+ 26  Ikú tó jẹ́ ọ̀tá ìkẹyìn ni a ó sọ di asán.+ 27  Nítorí Ọlọ́run “fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”+ Àmọ́ nígbà tí a sọ pé ‘a ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀,’+ ó ṣe kedere pé Ẹni tó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ kò sí lára wọn.+ 28  Àmọ́ nígbà tí a bá ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ tán, ìgbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ á fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀,+ kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún kálukú.+ 29  Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ni àwọn tí à ń batisí kí wọ́n lè jẹ́ òkú máa ṣe?+ Tí a ò bá ní gbé àwọn òkú dìde rárá, kí nìdí tí a fi ń batisí wọn kí wọ́n lè jíǹde? 30  Kí nìdí tí a fi ń wà nínú ewu ní wákàtí-wákàtí?*+ 31  Ẹ̀yin ará, ojoojúmọ́ ni mò ń dojú kọ ikú. Èyí dájú bí ayọ̀ tí mo ní lórí yín ṣe dájú, èyí tí mo ní nínú Kristi Jésù Olúwa wa. 32  Tó bá jẹ́ pé bíi tàwọn yòókù,* mo ti bá àwọn ẹranko jà ní Éfésù,+ àǹfààní wo ló máa ṣe mí? Tí a ò bá ní gbé àwọn òkú dìde, “ẹ jẹ́ ká máa jẹ, ká sì máa mu, torí ọ̀la la máa kú.”+ 33  Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere* jẹ́.+ 34  Ẹ jẹ́ kí orí yín pé lọ́nà òdodo, ẹ má sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà, nítorí àwọn kan ò ní ìmọ̀ Ọlọ́run. Mò ń sọ̀rọ̀ kí ojú lè tì yín. 35  Síbẹ̀, ẹnì kan á sọ pé: “Báwo ni àwọn òkú ṣe máa jíǹde? Bẹ́ẹ̀ ni, irú ara wo ni wọ́n ń gbé bọ̀?”+ 36  Ìwọ aláìnírònú! Tí ohun tí o gbìn ò bá kọ́kọ́ kú, ṣé ó lè hù* ni? 37  Ní ti ohun tí o gbìn, kì í ṣe ara tó máa dàgbà lo gbìn, hóró kan péré ni, ì báà jẹ́ ti àlìkámà* tàbí ti irúgbìn míì; 38  àmọ́ Ọlọ́run ń fún un ní ara bí ó ṣe wù ú, ó sì ń fún irúgbìn kọ̀ọ̀kan ní ara tirẹ̀. 39  Gbogbo ẹran ara kì í ṣe oríṣi kan náà, ti aráyé wà, ti ẹran ọ̀sìn wà, ti àwọn ẹyẹ wà, ti ẹja sì wà. 40  Àwọn ohun tó wà ní ọ̀run ní ara tiwọn,+ àwọn tó wà ní ayé sì ní tiwọn;+ ògo àwọn ohun tó wà ní ọ̀run jẹ́ oríṣi kan, ti àwọn tó wà ní ayé sì jẹ́ oríṣi míì. 41  Ògo oòrùn jẹ́ oríṣi kan, ògo òṣùpá jẹ́ oríṣi míì,+ ògo àwọn ìràwọ̀ sì jẹ́ oríṣi míì; kódà, ògo ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra. 42  Bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí pẹ̀lú àjíǹde àwọn òkú. A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́; a gbé e dìde ní àìdíbàjẹ́.+ 43  A gbìn ín ní àbùkù; a gbé e dìde ní ògo.+ A gbìn ín ní àìlera; a gbé e dìde ní agbára.+ 44  A gbìn ín ní ara ìyára; a gbé e dìde ní ara tẹ̀mí. Bí ara ìyára bá wà, ti ẹ̀mí náà wà. 45  Ìdí nìyẹn tó fi wà lákọsílẹ̀ pé: “Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ di alààyè.”*+ Ádámù ìkẹyìn di ẹ̀mí tó ń fúnni ní ìyè.+ 46  Síbẹ̀, èyí tó jẹ́ ti ẹ̀mí kọ́ ni àkọ́kọ́. Èyí tó jẹ́ ti ara ni àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà ni èyí tó jẹ́ ti ẹ̀mí. 47  Ọkùnrin àkọ́kọ́ wá láti ayé, erùpẹ̀ sì ni a fi dá a;+ ọkùnrin kejì wá láti ọ̀run.+ 48  Bí ẹni tí a fi erùpẹ̀ dá ṣe rí ni àwọn tí a fi erùpẹ̀ dá náà rí; bí ẹni ti ọ̀run ṣe rí ni àwọn tí wọ́n jẹ́ ti ọ̀run náà rí.+ 49  Bí a ṣe gbé àwòrán ẹni tí a fi erùpẹ̀ dá wọ̀,+ bẹ́ẹ̀ náà ni a máa gbé àwòrán ẹni ti ọ̀run wọ̀.+ 50  Àmọ́ mo sọ fún yín, ẹ̀yin ará, pé ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún Ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kì í jogún àìdíbàjẹ́. 51  Ẹ wò ó! Àṣírí mímọ́ ni mò ń sọ fún yín: Kì í ṣe gbogbo wa ló máa sùn nínú ikú, àmọ́ a máa yí gbogbo wa pa dà,+ 52  ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́, nígbà kàkàkí ìkẹyìn. Nítorí kàkàkí máa dún,+ a máa gbé àwọn òkú dìde ní àìlèdíbàjẹ́, a sì máa yí wa pa dà. 53  Nítorí èyí tó lè bà jẹ́ gbọ́dọ̀ gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀,+ èyí tó lè kú sì gbọ́dọ̀ gbé àìkú wọ̀.+ 54  Àmọ́ nígbà tí èyí tó lè bà jẹ́ bá gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, tí èyí tó lè kú sì gbé àìkú wọ̀, ìgbà náà ni ọ̀rọ̀ tó ti wà lákọsílẹ̀ máa ṣẹ pé: “A ti gbé ikú mì títí láé.”+ 55  “Ikú, ìṣẹ́gun rẹ dà? Ikú, oró rẹ dà?”+ 56  Ẹ̀ṣẹ̀ ni oró tó ń mú ikú wá,+ inú Òfin sì ni agbára ẹ̀ṣẹ̀ ti ń wá.*+ 57  Àmọ́ ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, nítorí ó ń ṣẹ́gun fún wa nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi!+ 58  Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ dúró gbọn-in,+ ẹ má yẹsẹ̀,* kí ẹ máa ní ohun púpọ̀ láti ṣe+ nínú iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, kí ẹ sì mọ̀ pé làálàá yín kò ní já sí asán+ nínú Olúwa.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.
Tàbí “ní gbogbo ìgbà?”
Tàbí kó jẹ́, “lójú ti èèyàn.”
Tàbí “ìwà ọmọlúwàbí.”
Tàbí “yè.”
Tàbí “wíìtì.”
Tàbí “alààyè ọkàn.”
Tàbí “Òfin ló ń fún ẹ̀ṣẹ̀ ní agbára.”
Tàbí “ẹ di aláìṣeéṣínípò.”