Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì Wúlò Lóde Òní?

Ṣé Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì Wúlò Lóde Òní?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ RÁRÁ. Ọkùnrin kan tó jẹ́ dókítà sọ pé ẹni tó bá ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì dà bí olùkọ́ tó ń fi ìwé sáyẹ́ǹsì tí wọ́n ti ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kọ́ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀. Kódà ẹnì kan tí ò gba Bíbélì gbọ́ lè béèrè lọ́wọ́ ẹ bóyá ìtọ́ni nípa bí o ṣe lè lo kọ̀ǹpútà tí wọ́n ṣe láyé àtijọ́ ni wàá tẹ̀ lé tó o bá fẹ́ mọ bí wàá ṣe lo kọ̀ǹpútà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohun táwọn kan rò ni pé Bíbélì ò wúlò rárá lóde òní.

Kí nìdí téèyàn á fi máa tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ inú ìwé àtijọ́ bíi ti Bíbélì níbi táyé lajú dé yìí táwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé sì ti wà lóríṣiríṣi? Ó ṣe tán àìmọye ìkànnì àtàwọn ìwé ìròyìn orí íńtánẹ́ẹ̀tì ló wà, tó láwọn ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni tuntun táwọn èèyàn lè tẹ̀ lé. Wọ́n máa ń gbé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá, àwọn tó mọ̀ nípa béèyàn ṣe ń gbé ìgbésí ayé àtàwọn òǹṣèwé lóríṣiríṣi jáde lórí tẹlifíṣọ̀n, kí wọ́n lè fún àwọn èèyàn ní ìmọ̀ràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ló wà táwọn èèyàn lè rà, tó sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè yanjú ìṣòro wọn, èyí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ tó ń ṣe ìwé jáde túbọ̀ pọ̀ sí i.

Kí wá ni ìwúlò Bíbélì tó ti wà láti nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] ṣẹ́yìn, nígbà téèyàn lè rí àwọn ìsọfúnni lóríṣiríṣi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? Ṣé kì í ṣe òótọ́ làwọn tí ò gba Bíbélì gbọ́ sọ pé téèyàn bá ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń lo ìwé sáyẹ́ǹsì tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tàbí ìtọ́ni kọ̀ǹpútà ayé àtijọ́? Àmọ́, ohun tí wọ́n sọ yẹn kì í ṣe òótọ́. Gbogbo ìgbà ni àyípadà ń bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, àmọ́ ṣé àyípadà ti dé bá àwọn ohun tó ṣe pàtàkì ní ìgbésí ayé àwa èèyàn? Ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì fẹ́ mọ bí wọ́n ṣe lè gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀, kí wọ́n ní ayọ̀, ìfọ̀kànbalẹ̀, ìdílé aláyọ̀ àtàwọn ọ̀rẹ́ tó ṣeé fọkàn tán.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ti pẹ́, síbẹ̀ ó sọ bá a ṣe lè ní àwọn ohun tó ṣe pàtàkì yìí ní ìgbésí ayé wa àtàwọn nǹkan míì. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá ló mí sí ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀. Ó máa ń tọ́ wa sọ́nà ní gbogbo ọ̀nà ìgbésí ayé wa, ó sì máa ń jẹ́ ká lè kojú àwọn ìṣòro tó bá yọjú. (2 Tímótì 3:​16, 17) Láfikún sí i, ó fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó máa ń bágbà mu lọ́jọ́kọ́jọ́! Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè.”​—Hébérù 4:12.

Ṣé òótọ́ ni gbogbo ohun tí Bíbélì sọ yìí? Ṣé ìwé tí kò bá àkókò wa yìí mu ni Bíbélì tàbí ìwé tó wúlò jù lọ ní àkókò wa, ìyẹn ìwé tí ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ wúlò nígbàkigbà? A tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí jáde tó jẹ́ àkọ́kọ́ lára àkànṣe irú rẹ̀ tá a máa tẹ̀ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí.