Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Lèrò Rẹ?

Kí Lèrò Rẹ?

Ṣé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

ÀWỌN KAN GBÀ PÉ . . .

àwọn ò lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run torí wọ́n rò pé aláìmọ́ àti ẹlẹ́ṣẹ̀ ni àwọn. Àwọn míì sọ pé Ọlọ́run ò rí ti àwa èèyàn rò. Kí lèrò rẹ?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ [Ọlọ́run] wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.” (Òwe 3:32) A máa di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tí a bá ń ṣègbọràn sí i.

KÍ LÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÍ BÍBÉLÌ SỌ?

  • Ọlọ́run fẹ́ di Ọ̀rẹ́ wa.​—Jákọ́bù 4:8.

  • Torí pé Ọlọ́run jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa, ó múra tán láti ràn wá lọ́wọ́ kó sì dárí jì wá.​—Sáàmù 86:5.

  • Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run máa ń nífẹ̀ẹ́ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, wọ́n sì máa ń kórìíra ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́.​—Róòmù 12:9.