ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ìgbà Wo Ló Yẹ Ká Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà?
Ásà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà táwọn ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an dojú kọ ọ́, ìyẹn sì jẹ́ kó ṣẹ́gun (2Kr 14:9-12; w21.03 5 ¶12)
Àmọ́ nígbà tó yá, Ásà wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Síríà nígbà táwọn ọmọ ogun tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ wá gbógun jà á (2Kr 16:1-3; w21.03 5 ¶13)
Inú Jèhófà ò dùn sí Ásà torí pé kò gbẹ́kẹ̀ lé e mọ́ (2Kr 16:7-9)
A máa gbára lé Jèhófà tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu tó ṣe pàtàkì. Àmọ́ tá a bá fẹ́ ṣe àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ńkọ́? Ó yẹ ká máa gbára lé Jèhófà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe.—Owe 3:5, 6; w21.03 6 ¶14.