Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́ Kó O Lè Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n

Máa Ka Bíbélì Lójoojúmọ́ Kó O Lè Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n

Ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ṣeyebíye bí ìṣúra tó fara sin. (Owe 2:1-6) Ọgbọ́n máa ń jẹ́ ká lè fòye mọ nǹkan ká sì ṣe ìpinnu tó dáa, ó tún máa ń dáàbò bò wá. Torí náà, ọgbọ́n ni “ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ.” (Owe 4:5-7) Ó gba ìsapá ká tó lè rí àwọn ìṣúra tó fara sin tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó máa gba pé ká máa ka Bíbélì “tọ̀sántòru” ìyẹn lójoojúmọ́. (Joṣ 1:8) Wo àwọn àbá tó lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé ká sì máa gbádùn ẹ̀.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ TÓ KỌ́ BÍ WỌ́N ṢE LÈ NÍFẸ̀Ẹ́ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Kí ló jẹ́ kó ṣòro fáwọn ọ̀dọ́ yìí láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kí ló sì ràn wọ́n lọ́wọ́?

  • Melanie

  • Samuel

  • Celine

  • Raphaello

ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ BÍBÉLÌ KÍKÀ MI: