Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 20, 2019
SOUTH AFRICA

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun Jáde Lédè Kwanyama

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun Jáde Lédè Kwanyama

Ní August 16, 2019, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Kwanyama níbi àpéjọ agbègbè tó wáyé ní Ondangwa, lórílẹ̀-èdè Namibia. Arákùnrin Franco Dagostini, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè South Africa ló mú Bíbélì yìí jáde lọ́jọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ náà ní gbọ̀ngàn tó ń jẹ́ Ondangwa Trade Fair Hall.

Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ pé: “Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun yìí máa rọrùn fáwọn èèyàn láti kà, wọ́n á sì lóye àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere. Inú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa máa dùn láti rí orúkọ Jèhófà ní gbogbo ibi tó yẹ kó wà.”

Ní ìpínlẹ̀ tí Ẹ̀ka ọ́fíìsì South Africa ń bójú tó, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó dín mẹ́wàá (490) akéde ló ń sọ èdè Kwanyama. Wọ́n ń wàásù fún àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan àtààbọ̀ tó ń sọ èdè Kwanyama ní orílẹ̀-èdè Àǹgólà àti Nàmíbíà.

A ti mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lódindi tàbí lápá kan ní èdè mẹ́rìnlélọ́gọ́sàn-án (184), mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) lára rẹ̀ sì jẹ́ odindi Bíbélì tá a tún ṣe látinú ẹ̀dà tó jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2013. Inú wa dùn pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa máa lo Bíbélì yìí láti sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ èèyàn lédè Kwanyama.​—Ìṣe 2:37.