Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JỌ́JÍÀ

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Jọ́jíà

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Jọ́jíà

Àtọdún 1953 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ẹ̀sìn wọn lórílẹ̀-ède Jọ́jíà. Wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì ń ṣe ẹ̀sìn wọn láìsí ìdíwọ́. Àmọ́ àwọn ìṣòro kan ṣì wà tí wọ́n ń kojú, torí àwọn èèyàn máa ń ṣe ẹ̀tanú ẹ̀sìn wọn nígbà míì.

Láàárín ọdún 1999 sí 2003, àwọn agbawèrèmẹ́sìn gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gidigidi, wọ́n ṣe wọ́n bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú láìmọye ìgbà. Ohun tó sì ń fún àwọn alátakò yìí lágbára ni pé àwọn agbófinró ò fìyà jẹ wọ́n. Nígbà yẹn, agbawèrèmẹ́sìn kan tó wà lára ìgbìmọ̀ aṣòfin kọ́kọ́ rí sí i pé wọ́n yọ orúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò lábẹ́ òfin, ni ìwà ipá tí wọ́n ń hù sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá tún pọ̀ sí i. Ìwé mẹ́fà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ìyẹn ilé ẹjọ́ ECHR) kí wọ́n lè bá wọn yanjú ọ̀rọ̀ yìí. Lọ́dún 2007 àti 2014, ilé ẹjọ́ ECHR fẹnu kò, wọ́n sì dá ìjọba lẹ́bi pé wọn ò tètè gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lórí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń hùwà ọ̀daràn, tó sì jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́sìn kan ló ń rúná sí i. Wọ́n tún dá ìjọba lẹ́bi pé wọ́n ṣe ojúsàájú sáwọn tọ́rọ̀ kàn. Nígbà tó di ọdún 2015, ìjọba gbà pé àwọn jẹ̀bi báwọn ṣe yọ orúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò lábẹ́ òfin lọ́dún 2001, ilé ẹjọ́ ECHR sì fọwọ́ sí ohun tí wọ́n sọ.

Látọdún 2004, ìwà ipá táwọn èèyàn ń hù sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dín kù gan-an. Wọ́n ti wá ń bá iṣẹ́ wọn lọ ní pẹrẹu, wọ́n sì ti lè kọ́ ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àmọ́, àwọn jàǹdùkú ṣì máa ń yọ wọ́n lẹ́nu nígbà míì, bẹ́ẹ̀, àwọn ẹlẹ́sìn kan ló wà nídìí ẹ̀. Nígbà táwọn aláṣẹ sì ti kọ̀ láti wá nǹkan ṣe sí ìwà ọ̀daràn táwọn èèyàn ń hù yìí, ṣe nìyẹn ń dá kún ìṣòro náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí ń retí pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè Jọ́jíà tẹ̀ lé gbogbo ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ECHR ṣe, kí wọ́n máa tètè gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ táwọn èèyàn bá hùwà ipá sí ẹnikẹ́ni, kí wọ́n sì pe àwọn tó bá wà nídìí ẹ̀ lẹ́jọ́.