Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kárí Ayé

Italy

  • Venice, Italy​—Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ìṣírí tó wà nínú Bíbélì fún ẹni kan

Ìsọfúnni Ṣókí—Italy

  • 58,851,000—Iye àwọn èèyàn
  • 250,193—Iye àwọn òjíṣẹ́ tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
  • 2,804—Iye àwọn ìjọ
  • 236—Iye èèyàn tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa wàásù fún

ÌRÒYÌN

Lórílẹ̀-Èdè Ítálì, Wọ́n Ṣí Aṣọ Lójú Àmì Tó Ń Ránni Létí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí Ẹgbẹ́ Òṣèlú Násì àti Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ Ṣe Inúnibíni Sí

Ètò kan wáyé ní abúlé Risiera di San Sabba ní ìlú Trieste, lórílẹ̀-èdè Ítálì, ní ìrántí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣenúnibíni sí jákèjádò ilẹ̀ Yúróòpù.

ÌRÒYÌN

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Ítálì Fọwọ́ Sí I Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Yan Ìtọ́jú Ìṣègùn Tó Wù Wọ́n

Wọ́n dájọ́ kan láìpẹ́ yìí tó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ará wa lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu irú ìtọ́jú tí wọ́n fẹ́

ÌRÒYÌN

Ọ̀pọ̀ Dókítà Nífẹ̀ẹ́ sí Títọ́jú Aláìsàn Láìlo Ẹ̀jẹ̀ Níbi Àpérò Pàtàkì Méjì Táwọn Onímọ̀ Ìṣègùn Ṣe Lórílẹ̀-Èdè Ítálì

A lo ìbi àpérò méjì láti pèsè ìsọfúnni tuntun nípa ìtọ́jú ìṣègùn láìlo ẹ̀jẹ̀ fún àwọn dókítà akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Lẹ́yìn náà, àwọn dókítà tó ń fún èèyàn láwọn oògùn tó ń dín ìrora kù àtàwọn oníṣẹ́ abẹ sọ ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n tọ́jú àwọn aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.