Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Fídíò Tó Nasẹ̀ Ìwé Bíbélì

Àwọn fídíò kéékèèké yìí máa jẹ́ kó o rí àwọn ìsọfúnni pàtàkì nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó wà nínú àwọn ìwé Bíbélì. Lo àwọn fídíò yìí kó o lè túbọ̀ gbádùn Bíbélì tó o bá ń kà á, tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

Ìwé Jẹ́nẹ́sísì fún wa ní àwọn ìsọfúnni pàtàkì nípa àwọn tó kọ́kọ́ gbé láyé àti ohun tó fà á tá a fi ń jìyà tá a sì ń kú.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

Ọlọ́run gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì, ó sí sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

Wàá rí bí ìwé Léfítíkù ṣe sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ mímọ́ àti ìdí tó fi ṣe pàtàkì káwa náà jẹ́ mímọ́.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

Wàá rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe àti bá a ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún àwọn tó ń múpò iwájú.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

Wàá rí bí Òfin tí Jèhófà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jóṣúà

Wàá rí bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ́gun àwọn tó wà ní Ilẹ̀ Ìlérí àti bí wọ́n ṣe pín ilẹ̀ náà fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àwọn Onídàájọ́

Ìwé yìí sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin onígboyà tí Jèhófà lò láti gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Rúùtù

Ìwé Rúùtù sọ̀rọ̀ nípa bí ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ opó ṣe nífẹ̀ẹ́ ìyá ọkọ rẹ̀ tóun náà jẹ́ opó. Ó sì sọ bí Jèhófà ṣe bù kún àwọn méjèèjì.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sámúẹ́lì Kìíní

Wàá rí bí Jèhófà ṣe fàyè gba kí àwọn ọba máa ṣàkóso àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dípò àwọn onídàájọ́ tó ń lò tẹ́lẹ̀.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́sírà

Jèhófà mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa dá àwọn èèyàn òun sílẹ̀ kúrò nígbèkùn ní Bábílónì àti pé òun á mú kí ìjọsìn tòótọ́ pa dà fìdí múlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nehemáyà

Ìwé Nehemáyà kọ́ gbogbo àwọn tó ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì lóde òní.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́sítérì

Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Ẹ́sítérì máa mú kó o túbọ̀ nígbàgbọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run lágbára láti gbà àwa èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ nígbà ìṣòrò.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jóòbù

Gbogbo àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni Èṣù máa dán wò. Ìtàn Jóòbù jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè pa ìwà títọ́ wa mọ́ ká sì gbé ipò ọba aláṣẹ Jèhófà lárugẹ.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sáàmù

Ìwé Sáàmù ti ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run lẹ́yìn, ó ń ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ tó Jèhófà lọ́wọ́, ó sì ń tù wọ́n nínú, ó tú sọ bí ìjọba Ọlọ́run ṣe máa tún ayé ṣe.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Òwe

Wà á rí ọ̀nà ọgbọ́n tó o lè gbà ṣe nǹkan ní ìgbésí ayé rẹ látori iṣẹ́ oúnjẹ ọ̀jọ́ títí kan ọ̀rọ̀ ìdílé.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù

Ọba Sólómọ́nì sọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé ẹ̀dá, ó sì fi wọ́n wéra pẹ̀lú àwọn ohun tó lòdì sí ọgbọ́n Ọlọ́run.

Ohun Tó Wà Nínú Orin Sólómọ́nì

Bíbélì pe ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì ní sí ọ̀dọ́kùnrin olùṣọ́ àgùntàn kan ní “ọwọ́ iná Jáà.” Kí nìdí?

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Aísáyà

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó jóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ ló wà nínú ìwé Aísáyà, ó sì mú ká túbọ̀ fọkàn balẹ̀ pé gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ló máa ṣẹ, ó sì máa gbà wá là.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jeremáyà kojú ìṣòro tó lágbára gan-an, kò kúrò nídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un. Ronú nípa bí àwa Kristẹni ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ lóde òní.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìdárò

Wòlíì Jeremáyà ló kọ ìwé Ìdárò, ó kédàárò nítorí ìparun Jerúsálẹ́mù, ó sì tún jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run máa ń ṣàánú àwọn ẹlẹ́sẹ̀ tó bá ronú pìwà dà.

Ohun Tó wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

Ìsíkíẹ́lì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì máa ń fi ìgboyà ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí Jèhófà bá gbé fún un, láìka bí iṣẹ́ náà ṣe nira tó. Àpẹẹrẹ àtàtà ló jẹ́ fún wa lónìí.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Dáníẹ́lì

Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà. Àpẹẹrẹ wọn àti bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà ṣe ní ìmúṣẹ lè ṣe àwa tá a wà láyé ní àkókò òpin yìí láǹfààní.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Hóséà

A lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà lóde òní. Ó sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa ń ṣàánú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà àti irú ìjọsìn tó tẹ́wọ́ gbà.

Ohun Tó wà Nínú Ìwé Jóẹ́lì

Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa “ọjọ́ Jèhófà” tó máa tó dé àti àwọn ohun tá a lè ṣe láti là á já. Ó túbọ̀ ṣe pàtàkì gan-an lóde òní pé ká fi àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ́kàn.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ámósì

Jèhófà gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fún ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ yìí. Ohun pàtàkì wo la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Ámósì?

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ọbadáyà

Ìwé yìí ló kéré jù nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tàbí Májẹ̀mú Láéláé. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń fúnni nírètí, ó sì ń fini lọ́kàn balẹ̀ pé ìṣàkóso Jèhófà ló máa lékè

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jónà

Wolíì náà gba ìbáwí, ó ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún un ní àṣeyanjú, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti àánú Ọlọ́run. Ìtàn Jónà máa wọ̀ ẹ́ lọ́kàn gan-an.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Míkà

Àsọtélẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí á jẹ́ kí ọkàn rẹ túbọ̀ balẹ̀ pé àwọn nǹkan tí Jèhófà sọ pé ká máa ṣe kì í ṣe ohun tó pọ̀ ju agbára wa lọ, àǹfààní wa ni wọ́n sì wà fún.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Náhúmù

Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ò ní lọ láìṣẹ àti pé ó máa ń tu àwọn tó ń wá àláàfíà àti ìgbàlà lábẹ́ Ìjọba rẹ̀ nínú.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Hábákúkù

Ọkàn wa balẹ̀ pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà mọ àkókò tó dáa jù àti ọ̀nà tó dáa jù láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sefanáyà

Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra, ká má ṣe máa ronú pé ọjọ́ Jèhófà ò ní dé?

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Hágáì

Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú àwọn nǹkan ti ara wa.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sekaráyà

Ọ̀pọ̀ ìran àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí fún àwọn èèyàn Ọlọ́run lókun nígbà àtijọ́. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣì ń fi àwa èèyàn Jèhófà lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà wà lẹ́yìn wà lóde òní.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Málákì

Ó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí ìlànà, àánú, àti ìfẹ́ Jèhófà. Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wúlò gan-an fún wa lóde òní tún wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Mátíù

Wàá gbádùn àwọn nǹkan pàtàkì tó wà nínú ìwé Mátíù tó jẹ́ àkọ́kọ́ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Máàkù

Ìwé Máàkù ló kéré jù lára àwọn ìwé Ìhìn Rere, ó sì jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí Jésù máa gbé ṣe tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Lúùkù

Àwọn ìsọfúnni wo ló wà nínú ìhìn rere Lúùkù to mú kó ṣàrà ọ̀tọ̀?

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù

Àkọsílẹ̀ Jòhánù jẹ́ ká rí i pé Jésù nífẹ̀ẹ́ gbogbo aráyé, ó tún sọ̀rọ̀ nípa ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Jésù àtàwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé òun ni Mèsáyà, Ọba Ìjọba Ọlọ́run.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì

Àwọn Kristẹni ìjímìjí ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè sọ àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn. Ìwé Ìṣe lè mú kí ìtara àti ọ̀yàyà tó o fi ń ṣe iṣé òjíṣẹ́ rẹ túbọ̀ pọ̀ sí i.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Róòmù

Àwọn ìtọ́ni onímìísí tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kì í ṣe ojúṣàájú àti ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Kọ́ríńtì

Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ yìí la ti rí àwọn ìmọ̀ràn onímìísí lórí ọ̀rọ̀ ìṣọ̀kan, ìṣekúṣe, ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Kọ́ríńtì Kejì

Jèhófà, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun, ó sì máa ń gbé wọn ró.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Gálátíà

Lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Gálátíà ṣì wúlò lónìí bíi ti ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ ọ́. Ó sì lè ran àwa Kristẹni tòótọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Éfésù

Lẹ́tà tí Ọlọ́run mí sí yìí ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ lo Jésù Kristi láti mú àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wá.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Fílípì

Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin lábẹ́ àdánwò, àá fún àwọn míì níṣìírí láti dúró gbọin-in.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Kólósè

A lè múnú Jèhófà dùn tá a bá ń fi ohun tá à ń kọ́ sílò, tá à ń dárí ji ara wa fàlàlà, tá a sì gbà pé Jésù lórí ìjọ Kristẹni.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Tẹsalóníkà Kìíní

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará tó wà ní Tẹsalóníkà níyànjú pé kí wọ́n wà lójúfò nípa tẹ̀mí, ‘kí wọ́n máa wádìí ohun gbogbo dájú,’ ‘kí wọ́n máa gbàdúrà nígbà gbogbo,’ kí wọ́n sì máa gba ara yín níyànjú.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Tẹsalóníkà Kejì

Pọ́ọ̀lù tún èrò àwọn ará ṣe nípa ìgbà tí ọjọ́ Jèhófà máa dé, ó sì gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Tímótì Kìíní

Pọ́ọ̀lù kọ Tímótì Kìíní kó lè ṣàlàyé bó ṣe yẹ kí nǹkan máa lọ nínú ìjọ, kó sì kìlọ̀ nípa ẹ̀kọ́ èké àti ìfẹ́ owó.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Tímótì Kejì

Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé kó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láìkù síbì kan.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Títù

Lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Títù sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó jẹ yọ láwọn ìjọ tó wà ní Kírétè, ó sì sọ ohun tó máa mú kẹ́nì kan kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Fílémónì

Lẹ́tà yìí kéré, àmọ́ ó kún fún ẹ̀kọ́ nípa bá a ṣe lè ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, àánú àti ẹ̀mí ìdáríjì.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Hébérù

Ohun tí ìjọsìn àwọn Kristẹni dá lé lórí sàn ju tẹ́ńpìlì àti ẹran táwọn Júù fi ń rúbọ.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jémíìsì

Jémíìsì fi àwọn ohun tó ṣeé fojú rí ṣàlàyé àwọn ìlànà Kristẹni tó ṣe pàtàkì.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Pétérù Kìíní

Lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pétérù kọ gbà wá níyànjú pé ká múra láti ṣiṣẹ́, ká sì kó gbogbo àníyàn wa lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Pétérù Kejì

Lẹ́tà kejì tí Pétérù kọ gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ olóòótọ́ bá a ṣe ń fojú sọ́nà fún ọ̀run tuntun àti ayé tuntun.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù Kìíní

Lẹ́tà Jòhánù kìlọ̀ fún­ wa nípa aṣòdì sí Kristi, ó sì jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àtohun tí kò yẹ ká nífẹ̀ẹ́.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù Kejì

Lẹ́tà kejì tí Jòhánù kọ rán wa létí pé ká máa rìn nínú òtítọ́, ká sì yẹra fáwọn ẹlẹ́tàn.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù Kẹta

Lẹ́tà kẹta yìí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì nípa ẹ̀mí aájò àlejò.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Júùdù

Júùdù ṣàlàyé onírúurú ọ̀nà táwọn apẹ̀yìndà ń gbà tan àwọn Kristẹni jẹ, kí wọ́n lè da ìjọ rú.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìfihàn

Àwọn ìran àgbàyanu tó wà nínú ìwé Ìfihàn jẹ́ ká mọ bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwa èèyàn àti ayé yìí ṣẹ.

O Tún Lè Wo

ÌWÉ ŃLÁ ÀTI ÌWÉ PẸLẸBẸ

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

Kí ni lájorí ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ nínú Bíbélì?