Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Àwọn Ọmọdé àti Fóònù​—Apá Kejì: Kọ́ Àwọn Ọmọdé Bí Wọ́n Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Fóònù

Àwọn Ọmọdé àti Fóònù​—Apá Kejì: Kọ́ Àwọn Ọmọdé Bí Wọ́n Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Fóònù

 Ohun èlò tó gbẹgẹ́ gan-an ni fóònù jẹ́, bó o bá ṣe lò ó máa pinnu bóyá á ràn ẹ́ lọ́wọ́ tàbí á pa ẹ́ lára. Báwo lo ṣe lè kọ́ ọmọ rẹ lọ́nà tó máa jẹ́ kó lè ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání tó bá ń lo ohun èlò tó gbẹgẹ́ yìí? Bí àpẹẹrẹ, báwo ló ṣe yẹ kí wọ́n pẹ́ tó tí wọ́n bá ń lo fóònù lojoojúmọ́? a

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  •   Fóònù lè fi ẹni tó ń lò ó sínú ewu. Bó ṣe wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọmọdé àti Fóònù—Apá Àkọ́kọ́: Ṣó Yẹ Kí Ọmọ Mi Ní Fóònù?” fóònù ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí gbogbo ohun tó wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, yálà ó dáa tàbí kò dáa.

     “Tá ò bá ṣọ́ra, a lè gbàgbé pé fóònù lè mú káwọn ọmọ wa kó sọ́wọ́ àwọn èèyàn burúkú tàbí kó jẹ́ kí wọ́n máa ronú bíi tiwọn.”—Brenda.

  •   Àwọn ọmọdé nílò ìtọ́sọ́nà. Láti kékeré làwọn ọ̀dọ́ ti ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé, ṣùgbọ́n kò tíì pẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó. Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé àwọn òbí ò mọ ẹ̀rọ ìgbàlódé lò, kò sì túmọ̀ sí pé àwọn ọmọdé tóótun ju àwọn òbí wọn lọ láti pinnu bí wọ́n ṣe lè lo fóònù wọn àtìgbà tí wọ́n lè lò ó.

     Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ rẹ lè mọ fóònù lò jù ẹ́ lọ, àmọ́ ìyen ò túmọ̀ sí pé wọ́n mọ bí wọ́n lè fọ́gbọ́n lò ó jù ẹ́ lọ. Kódà, àwọn ọmọdé tó mọ tìfun-tẹ̀dọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé nílò kí àwọn òbí kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè lo fóònù lọ́nà tó dára.

     “Tó o bá fún ọmọ rẹ ní fóònù láìjẹ́ pé o kọ́kọ́ dá a lẹ́kọ̀ọ́, ṣe ló dà bí ìgbà tó o fún un ní kọ́kọ́rọ́ ọkọ̀ kan láìjẹ́ pé o kọ́kọ́ kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń wakọ̀, tó o wá ní kó jókòó sáyè dírẹ́bà, lo bá ṣíná sọ́kọ̀, o wá sọ fún un pé ‘Jọ̀ọ́ rọra o.’”—Seth.

 Ohun tó o lè ṣe

  •   Mọ àwọn nǹkan tí fóònù ọmọ rẹ lè ṣe. Rí i pé o mọwọ́ àwọn ohun èlò tó lè jẹ́ kọ́mọ rẹ lo fóònù rẹ̀ dáadáa. Bí àpẹẹrẹ:

     Kí láwọn nǹkan táwọn òbí lè tẹ̀ lórí fóònù náà tó máa jẹ́ kí wọ́n lè dín àkókò táwọn ọmọ wọn ń lò lórí fóònù kù, tí kò sì ní jẹ́ kí wọ́n lọ sorí àwọn ìkànnì kan?

     Ṣé o mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àwọn ohun tó lè dènà ìsọfúnni tí kò bójú mu lórí íntánẹ́ẹ̀tì máa ń ṣiṣẹ́ dáadáa?

     Bó o bá ṣe mọwọ́ fóònù tọ́mọ rẹ ń lò sí ló máa jẹ́ kó o lè túbọ̀ ràn án lọ́wọ́ láti lo fóònù náà lọ́nà tó dáa.

     Ìlànà Bíbélì: ‘Ìmọ̀ ni èèyàn fi ń mú kí agbára rẹ̀ pọ̀ sí i.’—Òwe 24:5.

  •   Fi ààlà sí i. Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ohun tó o máa fàyè gbà àtàwọn ohun tí o kò ní fàyè gbà. Bí àpẹẹrẹ:

     Ṣé o máa jẹ́ kí ọmọ rẹ mú fóònù wá síbi tẹ́ ẹ ti ń jẹun tàbí kó máa tẹ̀ ẹ́ nígbà tẹ́ ẹ bá lọ sọ́dọ̀ mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́?

     Ṣé o fẹ́ kí fóònù àwọn ọmọ rẹ wà lódọ̀ wọn mọ́jú?

     Àwọn ètò ìṣiṣẹ́ wo lo fẹ́ kí wọ́n lò?

     Ìṣẹ́jú tàbí wákàtí mélòó ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi máa lo fóònù wọn?

     Ṣé wàá yan àkókò tí wọ́n gbọ́dò fi lò fóònù lójúmọ́?

     Jẹ́ kí wọ́n mọ òfin tó o ṣe, kó o sì múra tán láti bá àwọn ọmọ rẹ wí tí wọn ò bá pa òfin náà mọ́.

     Ìlànà Bíbélì: “Má fawọ́ ìbáwí sẹ́yìn fún ọ̀dọ́.”—Òwe 23:13, àlàyé ìsàlẹ̀.

  •   Máa yẹ fóònù ọmọ rẹ wò. Ríi pé o mọ ọ̀rọ̀ ìwọlé fóònù ọmọ rẹ, kó o sì máa wo àwọn ohun tó wà nínú fóònù náà nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, títí kan àtẹ̀jíṣẹ́, ètò ìṣiṣẹ́, fọ́tọ̀ àtàwọn ìkànnì tó lọ.

     “A sọ fún ọmọbìnrin wa pé àtìgbàdégbà ni àá máa yẹ fóònù rẹ̀ wò láìjẹ́ pé a sọ fún un tẹ́lẹ̀. Tá a bá kíyè sí i pé ó ti ń kọjá àyè pẹ̀lú fóònù náà, a máa gbà á lọ́wọ́ ẹ̀ tàbí ká dín àkókò tó fi ń lò ó kù.”—Lorraine.

     Àwọn òbí létọ̀ọ́ láti mọ báwọn ọmọ wọn ṣe ń lo fóònù wọn.

     Ìlànà Bíbélì: “Èèyàn lè fi ìṣe ọmọdé pàápàá dá a mọ̀, Bóyá ìwà rẹ̀ mọ́, tí ó sì tọ́.”—Òwe 20:11.

  •   Kọ́ ọmọ rẹ ní ìwà rere. Jẹ́ kọ́ wu ọmọ rẹ láti máa ṣe ohun tó tọ́. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé tí ọmọ kan bá fẹ́ fi ohun kan pamọ́ fun òbí rẹ̀, ó máa wá gbogbo ọ̀nà láti ṣe bẹ́ẹ̀ láìkà bí òbí rẹ̀ ṣe sapá tó. b

     Nítorí náà, kọ́ ọmọ rẹ ní àwọn ànímọ́ tó dára, bíi kéèyàn jẹ́ olóòótọ́, kó máa kó ara ẹ̀ níjàánu, kó sì mọ̀ pé gbogbo ohun téèyàn bá ṣe ló ní èrè. Tí ọmọ kan bá níwà rere, ìyẹn lè mú kó túbọ̀ máa fọgbọ́n lo fóònù rẹ̀.

     Ìlànà Bíbélì: “Àwọn tó dàgbà . . . ti kọ́ agbára ìfòyemọ̀ wọn nípa bí wọ́n ṣe ń lò ó láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:14.

a “Fóònù“ tá à ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí ni àwọn fóònù tó lè lọ sórí Íntánẹ́ẹ̀tì. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn fóònù yìí máa ń ṣiṣẹ́ bíi kọ̀ǹpútà kékeré.

b Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan máa ń fi ètò ìṣiṣẹ́ kan téèyàn ò lè tètè fura sí sínú fóònù kí wọ́n bàa lè fi àwọn nǹkan tí wọn ò fẹ́ kawọn òbí wọn rí pamọ́.