Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Bí Ìgbésí Ayé Mi Ṣe Rí Kò Mú Inú Mi Dùn, Ṣé Ìsìn, Ọlọ́run Tàbí Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?

Bí Ìgbésí Ayé Mi Ṣe Rí Kò Mú Inú Mi Dùn, Ṣé Ìsìn, Ọlọ́run Tàbí Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì tí í ṣe ìwé ọgbọ́n tó ti wà tipẹ́tipẹ́ dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí ayé, yóò mú kí inú rẹ dùn, ara á sì tù ọ́ pẹ̀sẹ̀. Wo díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí Bíbélì dáhùn.

  1.   Ǹjẹ́ ẹnì kan wà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá? Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “ni ó dá ohun gbogbo.” (Ìṣípayá 4:11) Ọlọ́run tó dá wa, mọ àwọn nǹkan tí a nílò tó máa múnú wa dùn tó sì máa jẹ́ kí ìgbésí-ayé wa nítumọ̀.

  2.   Ṣé Ọlọ́run bìkítà nípa mi? Bíbélì kò sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run bí ẹni tó rorò tí kì í sì í fẹ́ kí àwa èèyàn sún mọ́ òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ, ọ̀rọ̀ rẹ sì jẹ ẹ́ lógún gan-an torí ó fẹ́ ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe àṣeyọrí nígbèésí ayé rẹ.—Aísáyà 48:17, 18; 1 Pétérù 5:7.

  3.   Tí mo bá mọ Ọlọ́run, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kí n láyọ̀? Ọlọ́run dá “àìní . . . ti ẹ̀mí” mọ́ wa, ìyẹn ni pé ó máa ń wù wá láti mọ ìdí tá a fi wà láyé. (Mátíù 5:3) Ara ohun tí àìní nípa ti ẹ̀mí tá a ní wé mọ́ ni pé kó máa wù wá láti mọ Ẹlẹ́dàá wa ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Inú Ọlọ́run máa dùn gan-an tó o bá ń sapá láti mọ̀ ọ́n, torí Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.

 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ti wá rí i pé bí àwọn ṣe ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run ló jẹ́ kí ìgbésí ayé àwọn nítumọ̀, tó sì jẹ́ kí ọkàn àwọn balẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tó o bá mọ Ọlọ́run, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé o kò ní ní ìṣòro rárá, àmọ́ ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì yóò jẹ́ kí o

 Ọ̀pọ̀ ìsìn ni kì í tẹ̀ lé ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì. Àmọ́ ìsìn tòótọ́ tó ń tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run.