Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ǹjẹ́ Ibì Kan Wà Tí Ọlọ́run Ń Gbé?

Ǹjẹ́ Ibì Kan Wà Tí Ọlọ́run Ń Gbé?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀run ni Ọlọ́run ń gbé. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí:

 Sólómọ́nì Ọba sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé: “kí ìwọ alára fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ń gbé.”—1 Àwọn Ọba 8:43.

 Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà sí “Bàbá [wọ́n] tí ń bẹ́ ní ọ̀run.”—Mátíù 6:9.

 Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó wọlé sí “ọ̀run, nísinsìnyí láti fara hàn níwájú Ọlọ́run.”—Hébérù 9:24.

 Àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn fi hàn kedere pé Jèhófà Ọlọ́run jẹ ẹni kan, kì í gbé ibi gbogbo, ọ̀run ló ń gbé.