Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Kólósè 3:23—“Ohunkóhun Tí Ẹ Bá Ń Ṣe, Ẹ Ṣe É Tọkàntọkàn”

Kólósè 3:23—“Ohunkóhun Tí Ẹ Bá Ń Ṣe, Ẹ Ṣe É Tọkàntọkàn”

 “Ohunkóhun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ ṣe é tọkàntọkàn bíi pé Jèhófà lẹ̀ ń ṣe é fún, kì í ṣe èèyàn.”​—Kólósè 3:23, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Ohunkóhun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ ṣe é tọkàntọkàn, bí ẹni pé Oluwa ni ẹ̀ ń ṣe é fún, kì í ṣe fún eniyan.”​—Kólósè 3:23, Yoruba Bible.

Ìtumọ̀ Kólósè 3:23

 Ó yẹ kí àwọn Kristẹni máa ṣiṣẹ́ kára, torí ọwọ́ tí wọ́n bá fi mú iṣẹ́ máa kan ìjọsìn wọn sí Jèhófà Ọlọ́run.

 “Ohunkóhun tí ẹ bá ń ṣe.” Àwọn tó bá fẹ́ jọ́sìn Jèhófà gbọ́dọ̀ sapá láti máa tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì bá sọ nínú gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Wọ́n máa ń sapá láti ṣiṣẹ́ kára, kí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ àti ẹni tó ṣeé fọkàn tán nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe, ì báà jẹ́ nínú ilé, níbi iṣẹ́ tàbí nílé ìwé.​—Òwe 11:13; Róòmù 12:11; Hébérù 13:18.

 “Ẹ ṣe é tọkàntọkàn.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “tọkàntọkàn” túmọ̀ sí pé “kéèyàn pinnu láti fi gbogbo okun rẹ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.” a

 Irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń lo gbogbo okun rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá ní kó ṣe, ó sì máa ń ṣe é tọkàntọkàn. Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì túmọ̀ gbólóhùn náà sí “gbogbo ọkàn” (Bíbélì New Catholic) àti “látọkàn wá” (Bíbélì King James).​—Wo “ Bí Wọ́n Ṣe Túmọ̀ Kólósè 3:23 Látinú Àwọn Ìtumọ̀ Bíbélì Míì.”

 “Jèhófà lẹ̀ ń ṣe é fún, kì í ṣe èèyàn.” Ọwọ́ pàtàkì làwọn Kristẹni fi máa ń mú iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá ń ṣe, torí wọ́n mọ̀ pé ó kan àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Ohun tó jẹ wọ́n lógún ni bí wọ́n ṣe máa mú inú Jèhófà dùn, kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa mú inú ọ̀gá tàbí ẹnikẹ́ni míì dùn. Tí Kristẹni kan bá ṣe iṣẹ́ ẹ̀ bó ṣe yẹ, èyí á mú káwọn èèyàn fi ojú tó dáa wò ó, inú Ọlọ́run á sì dùn sí i. Torí náà, Kristẹni kan gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe “kí àwọn èèyàn má bàa sọ̀rọ̀ àbùkù nípa orúkọ Ọlọ́run.”​—1 Tímótì 6:1; Kólósè 3:22.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Kólósè 3:23

 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló kọ ìwé Kólósè sí àwọn Kristẹni tó ń gbé nílùú Kólósè. b Ó kọ ọ́ ní nǹkan bíi 60 sí 61 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí àsìkò tó máa lò lẹ́wọ̀n fún ìgbà àkọ́kọ́ nílùú Róòmù ń parí lọ.

 Àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Kólósè lè ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti máa sin Ọlọ́run níṣọ̀kan láìka ibi tí wọ́n ti wá àti ipò tí wọ́n wà sí. (Kólósè 3:11) Ìwé yìí gbà wọ́n níyànjú láti ní àwọn ànímọ́ Ọlọ́run bí ìfẹ́, inú rere àti àánú. (Kólósè 3:12-14) Bákan náà, ó sọ bí ìjọsìn Ọlọ́run ṣe kan gbogbo apá ìgbésí ayé wa.​—Kólósè 3:18–4:1.

 Bí Wọ́n Ṣe Túmọ̀ Kólósè 3:23 Nínú Àwọn Ìtumọ̀ Bíbélì Míì

 “Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá ń ṣe, ẹ máa fi tọkàntọkàn ṣe é fún Olúwa, kí í ṣe fún ènìyàn.”​—Bíbélì Mímọ̀ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

 “Ohunkohun ti ẹnyin ba nṣe, ẹ mã fi tọkàntọkàn ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa, kì si iṣe fun enia.”​—Bibeli Mimọ.

 “Ohunkohun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ ṣe é tọkàntọkàn, bí ẹni pé Oluwa ni ẹ̀ ń ṣe é fún, kì í ṣe fún eniyan.”​—Bibeli Ìròyìn Ayọ̀

 Wo fídíò kékeré yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Kólósè.

a Látinú ìwé Exegetical Dictionary of the New Testament, 1993, Ìdìpọ̀ Kẹta, ojú ìwé 502.

b Orílẹ̀-èdè Turkey ló wà lónìí.