Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Àìsáyà 42:8​—“Èmi Ni OLÚWA”

Àìsáyà 42:8​—“Èmi Ni OLÚWA”

 “Èmi ni Jèhófà. Orúkọ mi nìyẹn; èmi kì í fi ògo mi fún ẹlòmíì, èmi kì í sì í fi ìyìn mi fún àwọn ère gbígbẹ́.”—Àìsáyà 42: 8, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Emi li Oluwa: eyi ni orukọ mi: ogo mi li emi kì yio fi fun ẹlòmiran, bẹni emi kì yio fi iyìn mi fun ere gbigbẹ́.”—Àìsáyà 42:8, Bibeli Mimọ.

Ìtumọ̀ Àìsáyà 42:8

 Ọlọ́run sọ orúkọ rẹ̀ fún wa, ó tún sọ pé a ò lè fi ère sin òun.

 Ọlọ́run fún ara ẹ̀ ní orúkọ kan. Ohun tí wọ́n sábà máa ń túmọ̀ orúkọ náà sí ni “Jèhófà.” a (Ẹ́kísódù 3:14, 15) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé orúkọ Ọlọ́run fara hàn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà nínú Májẹ̀mú Láéláé (Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù àti Árámáíkì), síbẹ̀ àwọn atúmọ̀ èdè kan fi orúkọ oyè náà “OLÚWA” (ní lẹ́tà gàdàgbà) rọ́pò orúkọ Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ ohun tá à ń sọ wà ní Sáàmù 110:1, ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jèhófà àti Jésù. Nínú Bibeli Mimọ, ẹsẹ náà kà pé: “OLUWA [Jèhófà] wi fun Oluwa mi [Jésù] pe.” (Ìṣe 2:34-36) Àmọ́, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun fi ìyàtọ̀ hàn láàárín “Olúwa” méjèèjì ní ti pé ó fi orúkọ Ọlọ́run síbi tó yẹ kó wà. Ẹsẹ Bíbélì náà wá kà pé: “Jèhófà sọ fún Olúwa mi pé: ‘Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.’”

 Àwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà pé ohun tí orúkọ náà túmọ̀ sí ni “Ó Ń Mú Kí Ó Di.” Ọlọ́run tòótọ́ nìkan ló lè jẹ́ orúkọ yìí torí pé òun nìkan ló lè di ohunkóhun tó bá fẹ́ tó sì tún lé mú kí ìṣẹ̀dá rẹ̀ èyíkéyìí di ohunkóhun kó lè mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ.

 Òun ni Ẹlẹ́dàá wa, òun nìkan sì ni Ọlọ́run tòótọ́. Torí náà, Jèhófà nìkan ṣoṣo ló yẹ ká máa sìn. Kò yẹ ká máa jọ́sìn ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni, títí kan àwọn òrìṣà àtàwọn ère.—Ẹ́kísódù 20:2-6; 34:14; 1 Jòhánù 5:21.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Àìsáyà 42:8

 Nínú àwọn ẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ Àìsáyà orí 42, Jèhófà sọ iṣẹ́ tí “àyànfẹ́” rẹ̀ máa ṣe. Ọlọ́run sọ nípa ẹni tó tẹ́wọ́ gbà yìí pé, “ó máa mú ìdájọ́ òdodo wá fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Àìsáyà 42:1) Nígbà tí Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ nípa ìlérí yìí, ó ní: “Ní báyìí, mò ń kéde àwọn nǹkan tuntun. Kí wọ́n tó rú yọ, mo sọ fún yín nípa wọn.” (Àìsáyà 42:⁠9) Àsọtẹ́lẹ̀ nípa “àyànfẹ́” yìí rú yọ, tàbí nímùúṣẹ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yin náà, ìyẹn nígbà tí Mèsáyà tàbí Kristi dé, kó lè wá ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.​—Mátíù 3:16, 17; 12:15-21.

Àìsáyà 42:8 Nínú Àwọn Ìtumọ̀ Bíbélì Míì

 “Èmi ni Jèhófà, orúkọ mi nìyẹn; ògo mi ni èmi kì í fún ẹlòmíì, èmi kì í sì í fi ìyìn mi fún àwọn ère gbígbẹ́.”​—Bíbélì The ‘Holy Scriptures,’ látọwọ́ J. N. Darby.

 “Èmi ni Jèhófà; orúkọ Mi nìyẹn; Èmi kì í fi ògo Mi fún ẹlòmíì, Èmi kì í sì í fi ìyìn Mi fún àwọn ère gbígbẹ́.”—Bíbélì A Literal Translation of the Bible.

a Kọ́ńsónáǹtì mẹ́rin náà YHWH ni wọ́n sábà máa ń lò lédè Gẹ̀ẹ́sì, fún lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run. Àwọn Bíbélì kan lédè Gẹ̀ẹ́sì pè é ní “Yahweh.” Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i, wo Àfikún A4 tó ní àkòrí náà “Orúkọ Ọlọ́run Lédè Hébérù” tó wà nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.