Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àdéhùn Lílò Ìkànnì

Àdéhùn Lílò Ìkànnì

Ẹ káàbọ̀!

Ìkànnì yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run, Bíbélì àti nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófa. Ó lè kà, wò tàbí kó o wa ohun tó o bá fẹ́ jáde. A fẹ́ kí ìkànnì yìí ṣe àwọn míì náà láǹfààní, àmọ́ má ṣe kó ohun tó wà lórì ìkànnì yìí lọ sórí ìkànnì míì tàbí sórí ètò ìṣiṣẹ́ èyíkéyìí. Tó o bá fẹ́ kí àwọn míì jàǹfààní látinú ohun tó o ti kọ́ lórí ìkànnì yìí, ó lè darí wọn sórí ìkànnì yìí kó o sì tẹ̀ lé Àdéhùn Lílò Ìkànnì tá a tò sí ìsàlẹ̀ yìí tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀.

 Ẹ̀tọ́ Àdàkọ

© 2024 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. All rights reserved.

Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. (ìyẹn “Watchtower”) ló ni ìkànnì yìí, àwọn ló sì ń bójú tó o. Bá ò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ọ̀rọ̀ àti àwọn ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì yìí jẹ́ ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania (ìyẹn “Watch Tower”).

 Àmì Oní-nǹkan

Ọ̀rọ̀ náà, “Adobe,” àti àmì “Adobe,” ọ̀rọ̀ náà “Acrobat,” àti àmì “Acrobat” jẹ́ ti ilé iṣẹ́ Adobe Systems Incorporated. Ilé iṣẹ́ Apple Inc. ló ni àmì “iTunes” àti “iPod.” Bákan náà, ọ̀rọ̀ náà “Microsoft”, àmì “Microsoft” àti orúkọ àwọn ohun tí ilé iṣẹ́ Microsoft ṣe, irú bíi “Microsoft Office” àti “Microsoft Office 365”, jẹ́ ti ilé iṣẹ́ Microsoft Inc. Gbogbo àwọn àmì oní-nǹkan àti àwọn àmì oní-nǹkan tó ti lóǹtẹ̀ ìjọba yòókù jẹ́ tí àwọn ilé iṣẹ́ tó ni wọ́n.

 Àdéhùn Lílo Ìkànnì àti Àṣẹ Láti Lo Ìkànnì

Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí ló máa sọ bó ṣe yẹ kó o lo ìkànnì yìí. Lílò tó ò ń lo ìkànnì yìí fi hàn pé o fara mọ́ Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí láìkù síbì kan (ìyẹn gbogbo ohun tó wà ní abala “Àdéhùn Lílo Ìkànnì” lórí ìkànnì yìí). Àmọ́, bí o kò bá fara mọ Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí tàbí apá èyíkéyìí lára Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí, má ṣe lo ìkànnì yìí.

Kí lo túmọ̀ sí láti lo ìkànnì yìí lọ́nà tó tọ́? Àwọn ohun tó o le fi ìkànnì yìí ṣe àti àwọn ohun tí o kò lè fi ṣe la tò sí ìsàlẹ̀ yìí. O lè:

  • Wò, wà jáde, kí o sì tẹ àwọn àwòrán, àwọn ìtẹ̀jáde, orin, fọ́tò, ọ̀rọ̀ àti fídíò tó ní ẹ̀tọ́ àdàkọ láti orí ìkànnì yìí fún ìlò ara rẹ àti fún ète tí kò la ìṣòwò lọ.

  • Fi ìlujá sí àwọn ìtẹ̀jáde wa lórí ìkànnì yìí ráńṣẹ́ sí ẹlòmíì tàbí kó o fi àwọn ìtẹ̀jáde, fídíò àti àwọn àtẹ́tísí tó ṣe é wà jáde lórí ìkànnì yìí ráńṣẹ́ sí ẹlòmíì.

O kò lè:

  • Gbé àwòrán, àwọn ìtẹ̀jáde, àmì, orin, fọ́tò, fídíò tàbí àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lórí ìkànnì yìí sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì (ìkànnì èyíkéyìí, ìkànnì tí wọ́n tí ń wa fáìlì jáde, ìkànnì tí wọ́n ti ń wo fídíò tàbí ìkànnì ajọlò èyíkéyìí).

  • Fi àwòrán, àwọn ìtẹ̀jáde, àmì, orin, fọ́tò, fídíò tàbí àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lórí ìkànnì yìí sínú ètò ìṣiṣẹ́ èyìkéyìí (títí kan títọ́jú ẹ̀ pa mọ́ láti fi ṣe ètò ìṣiṣẹ́ èyíkéyìí).

  • Ṣe àdàkọ, pín kiri tàbí lo àwòrán, ìwé orí ìkànnì, àmì oní nǹkan, orin, fọ́tò, ọ̀rọ̀ tàbí fídíò tó wà lórí ìkànnì yìí fún ètè ìṣòwò tàbí fún owó (kódà tí o kò bá jèrè nínú ẹ̀ pàápàá).

  • Ṣe ètò ìṣiṣẹ́ tó o ṣe é pín kiri tó máa lè máa wa ìsọfúnni bíi HTML, àwòrán tàbí ọ̀rọ̀ tó wà lórí ìkànnì yìí jáde tàbí tá a máa ṣe àdàkọ rẹ̀. (Èyí ò túmọ̀ sí pé èèyàn ò lè lo àwọn ètò ìṣiṣẹ́ bíi EPUB, PDF, MP3 àti MP4 tó jẹ́ pé ọ̀fẹ́ ni wọ́n tí wọ́n sì ń fi wọn ṣí àwọn fáìlì tí èèyàn wà jáde lórí ìkànnì yìí.)

  • Lo ìkànnì yìí tàbí àwọn ètò tó wà níbẹ̀ fún ètè tí kò dáa, irú bíi ṣíṣe màdàrú ọ̀nà tó tọ́ láti wọlé sórí ìkànnì tàbí lílo àwọn ọgbọ́n àyínìke míì láti wọlé sórí ìkànnì yìí tàbí àwọn ètò orí rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn ọ̀nà tó ṣe kedere tí a ti pèsè.

  • Lo ìkànnì yìí lọ́nà èyíkéyìí tó lè ba ìkànnì yìí jẹ́ tàbí tó lè mú kó má ṣiṣẹ́ dáadáa, tó lè da nǹkan rú tí ò sì ní jẹ́ káwọn èèyàn lè wọlé tàbí rí ìkànnì náà lò; tàbí lọ́nà èyíkéyìí tí kò bá òfin mu, tó tàpá sófin, fún lílu jìbìtì, tó lè pani lára, tàbí tó kan ìgbòkègbodò èyíkéyìí tí kò bá òfin mu, tó tàpá sófin, tí wọ́n fi ń luni ní jìbìtì, tàbí tó lè ṣe ìpalára.

  • Fi ìkànnì yìí tàbí àwọn àwòràn, ìwé, orin, fọ́tò, ọ̀rọ̀ tàbi fídíò tó wà lórí rẹ̀ ṣe ohunkohun tó la ìṣòwò lọ.

 Abala Ìṣègùn

Ìsọfúnni lásán ni gbogbo àwọn nǹkan tó wà ní abala ìṣègùn lórí ìkànnì yìí (“Abala Ìṣègùn”) wà fún kìí ṣe àbá lórí ọ̀rọ̀ ìtọ́jú ìṣègùn. A ò ṣe é pé kó dípò lílọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ògbógi lẹ́nu ìṣègùn, tàbí lílọ ṣe àwọn àyẹ̀wò tó yẹ. Abala Ìṣègùn ò fọwọ́ sọ̀yà lórí àyẹ̀wò, dọ́kítà, òògùn, ọ̀nà ìtọ́jú, èrò tàbí ìsọfúnni èyíkéyìí tá a mẹ́nu bà ní abala yìí.

Ṣe ni kó o lọ bá dọ́kítà tàbí oníṣègùn tó kúnjú ìwọ̀n nípa ìbéèrè èyíkéyìí tó o bá ní nípa àìsàn kan tàbí ìtọ́jú kan.

A gbìyànjú láti rí i pé ìsọfúnni tó jóòótọ́ tó sì bágbàmu ló wà ní Abala Ìṣègùn yìí. Àmọ́, “BÍ WỌ́N ṢE FÚN WA” la ṣe kọ ọ́ síbẹ̀, a ò fọwọ́ sọ̀yà lórí ohun tí wọ́n sọ. A ò lè fọwọ́ sọ̀yà pé gbogbo ìsọfúnni tó wà ní abala yìí ló ṣeé gbára lé, jẹ́ òótọ́, bágbà mu, wúlò, tó sì pé pérépéré délẹ̀délẹ̀. Tí àṣìṣe kan bá wà nínú ìsọfúnni tó wà ní Abala Ìṣègùn yìí, ìkànni yìí kọ́ ló lẹ̀bi. Tó o bá gbára lé ìsọfúnni tó wà ní Abala Ìṣègùn yìí, ṣe ni kó o fara mọ́ ohun tó bá tìdí ẹ̀ yọ. Tí ẹnì kan bá lo ìsọfúnni tó wà ní abala yìí, tó wá yọrí sí wàhálà tàbí gbèsè èyíkèyìí, a ò ní mú ìkànnì yìí.

 Bí Wọ́n Ṣe Fún Wa Ní Ìsọfúnni La Ṣe Gbé E Síbí, Kò Sí Lọ́rùn Wa

Watchtower ló pèsè gbogbo ohun tó wà lórí ìkànnì yìí. “Bí wọ́n ṣe fún wa” la ṣe gbé e síbẹ̀. A ò fọwọ́ sọ̀yà lórí àwọn ìsọfúnni náà.

Watchtower ò fọwọ́ sọ̀yà pé kò sí virus tàbí àwọn ohun míì tó lè pa kọ̀ǹpútà lára nínú àwọn ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì yìí. Watchtower kò ní dáhùn fún ìjábá tàbí gbèsè tó bá tìdíi lílo ìsọfúnni tàbí àwọn ohun tó wà lórí ìkànnì yìí.

 Yíyẹ Àdéhùn Lílo Ìkànnì

Láìní fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ẹ̀tọ́ míì tí Watchtower ní lábẹ́ Àdéhùn Lílo Ìkànnì, tó o bá yẹ Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí lọ́nàkọnà, Watchtower ò ní kùnà láti gbé ìgbésẹ̀ bó bá ṣe tọ́ lójú Watchtower láti bójú tó títẹ àdéhùn lójú. Lára irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé, wọ́n ò ní gbà ọ́ láyè láti wọlé sórí ìkànnì yìí fún àkókò kan, wọn ò ní jẹ́ kó o rí ìkànnì yìí lò mọ́, wọn ò ní jẹ́ kí àwọn kọ̀ǹpútà tó ń lo àdírẹ̀sí ìwọlé sórí íńtánẹ́ẹ́tì, ìyẹn “IP address” kan náà pẹ̀lú rẹ wọlé sí ìkànnì yìí, wọ́n sì máa kàn sí ilé iṣẹ́ tó ń pèsè íńtánẹ́ẹ̀tì fún ẹ pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kó o wọlé sórí ìkànnì yìí àti/tàbí kí wọ́n pè ẹ́ lẹ́jọ́.

 Àtúnṣe

Watchtower lè ṣe àtúnṣe sí Àdéhùn Lílo Ìkànnì látìgbàdégbà. Ọjọ́ tí Àdéhùn Lílo Ìkànnì tí wọ́n tún ṣe bá dé orí ìkànnì yìí ni àdéhùn náà tí di àmúlò fẹ́ni tó bá fẹ́ lo ìkànnì yìí. Torí náà, jọ̀wọ́, máa wo abala tó o wà yìí déédéé kó o lè mọ àwọn àtúnṣe tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe.

 Òfin àti Ibi Tí Wọ́n Ti Lè Gbọ́ Ẹjọ́

Òfin ìpínlẹ̀ New York ní Amẹ́ríkà la gbé Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí kà. Òfin míì kò sì lè dá wa lọ́wọ́ kọ́. Ilé ẹjọ́ ìpínlẹ̀ tàbí ti ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìpínlẹ̀ New York ní Amẹ́ríkà ló máa gbọ́ ẹjọ́ èyíkéyìí tó jẹ mọ́ yíyẹ Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí.

 Tí Ilé Ẹjọ́ Kò Bá Fara Mọ́ Abala Kan

Tí ilé ẹjọ́ kan tó lẹ́tọ̀ọ́ láti gbọ́ irú ẹjọ́ yìí bá dájọ́ pé abala kan lára Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí kò ṣeé pe ẹjọ́ lé lórí, kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, a ò lè fipá múni tẹ̀ lé e, tàbí pé kò bófin mu, àwọn abala tó kù á ṣì lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Tí Watchtower kò bá fòfin gbé ẹnì kan tó yẹ abala kan lára Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé wọ́n ti gbójú fo abala yẹn tàbí pé Watchtower ò lẹ́tọ̀ọ́ láti pe èèyàn lẹ́jọ́ lórí abala yẹn.

 Àdéhùn Náà Látòkèdélẹ̀

Àdéhùn Lílo Ìkànnì yìí jẹ́ àjọgbà láàárín ìwọ àti Watchtower lórí lílo ìkànnì yìí àti pé àdéhùn yìí borí àwọn àdéhùn tó ti wà tẹ́lẹ̀ nípa lílo ìkànnì yìí.