Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 98

Ọlọ́run Ló Mí sí Ìwé Mímọ́

Ọlọ́run Ló Mí sí Ìwé Mímọ́

(2 Tímótì 3:​16, 17)

  1. 1. Ọ̀r’Ọlọ́run tàn bí ‘mọ́lẹ̀

    Láyé tó ṣókùnkùn yìí.

    Tá a bá ń jẹ́ kó ṣamọ̀nà wa,

    Òótọ́ rẹ̀ yóò dá wa sílẹ̀.

  2. 2. Ọlọ́run mí s’Ìwé Mímọ́,

    Láti darí ‘ṣísẹ̀ wa.

    Ó fi ń kọ́ wa, ó ńbá wa wí.

    Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ń gbé wa ró.

  3. 3. Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

    Lójoojúmọ́ ayé wa,

    A ó máa túbọ̀ sún m’Ọ́lọ́run,

    Ìfẹ́ tá a ní yóò máa pọ̀ sí i.