Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 91

Iṣẹ́ Tá A Fìfẹ́ Ṣe

Iṣẹ́ Tá A Fìfẹ́ Ṣe

(Sáàmù 127:1)

  1. 1. Jèhófà, ọjọ́ ti pé.

    A ti parí ilé tá à ń kọ́.

    Torí orúkọ rẹ la ṣe kọ́ ọ,

    Inú wa sì ń dùn!

    A rí ẹ̀rí tó dájú,

    Pé o bù kún iṣẹ́ tá a ṣe.

    À ń gbàdúrà sí ọ,

    Látọkàn, jọ̀wọ́ tẹ́wọ́ gbà á.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà, Bàbá wa onífẹ̀ẹ́,

    A dúpẹ́ pé o kà wá yẹ

    Pé kí a kọ́ ilé yìí fún ọ; a ó máa yìn ọ́.

    Títí láé la ó máa jọ́sìn rẹ.

  2. 2. Ojú wa rẹwà púpọ̀.

    Ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni gbogbo wa.

    Bá a ṣe jọ wà pa pọ̀, táà ń láyọ̀,

    A ò lè gbàgbé láé!

    Ẹ̀mí rẹ ràn wá lọ́wọ́,

    Ó mú ká ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan.

    Iṣẹ́ tá a sì ṣe yìí

    Mú ìyìn bá orúkọ rẹ.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà, Bàbá wa onífẹ̀ẹ́,

    A dúpẹ́ pé o kà wá yẹ

    Pé kí a kọ́ ilé yìí fún ọ; a ó máa yìn ọ́.

    Títí láé la ó máa jọ́sìn rẹ.