Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 63

Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ni Wá

Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ni Wá

(Àìsáyà 43:10-12)

  1. 1. Àwọn èèyàn ń bọ̀rìṣà

    Wọn kò m’Ọlọ́run tòótọ́.

    Olódùmarè ni;

    Iṣẹ́ rẹ̀ ń fi hàn.

    Àwọn ọlọ́run èké

    Kò lè mọ ọjọ́ ọ̀la.

    Kò sí ẹlẹ́rìí kankan fún wọn.

    Wọ́n kéré sí Ọlọ́run wa.

    (ÈGBÈ)

    Ẹlẹ́rìí Jáà ni àwa.

    À ń wàásù lọ láìbẹ̀rù.

    Ọlọ́run wa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀;

    Gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ń ṣẹ.

  2. 2. À ń kéde orúkọ rẹ̀.

    À ń jẹ́rìí rẹ̀ fáráyé.

    À ń fìgboyà wàásù

    Nípa ‘jọba rẹ̀.

    À ń jẹ́ kọ́pọ̀ èèyàn mọ

    Bóòótọ́ ṣe ń túni sílẹ̀.

    Bá a ṣe ń kọ́ wọn, ó ńwọ̀ wọ́n lọ́kàn.

    Àwọn náà wá ń yin Ọlọ́run.

    (ÈGBÈ)

    Ẹlẹ́rìí Jáà ni àwa.

    À ń wàásù lọ láìbẹ̀rù.

    Ọlọ́run wa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀;

    Gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ń ṣẹ.

  3. 3. Bá a ṣe ńgbórúkọ rẹ̀ ga

    Ń mú kí ẹ̀gàn rẹ̀ kúrò.

    À ń kìlọ̀ fẹ́ni ‘bi

    Tó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn.

    Ṣùgbọ́n tó bá yí pa dà,

    Jọ̀wọ́ Bàbá, dárí jì í.

    Bí a ṣe ń sìn ọ́ látọkàn wá,

    À ń láyọ̀, a sì nírètí.

    (ÈGBÈ)

    Ẹlẹ́rìí Jáà ni àwa.

    À ń wàásù lọ láìbẹ̀rù.

    Ọlọ́run wa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀;

    Gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ń ṣẹ.