Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 28

Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà

Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà

(Sáàmù 15)

  1. 1. Ta lọ̀rẹ́ rẹ, Baba,

    Táá máa gbé ilé rẹ;

    Ẹni tí Ìwọ gbẹ̀rí rẹ̀ jẹ́,

    Tó sì mọ̀ ọ́ dunjú?

    Àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ,

    Tí wọ́n sì nígbàgbọ́;

    Àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin,

    Tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́.

  2. 2. Ta ni yóò dọ̀rẹ́ rẹ,

    Tó sì lè sún mọ́ ọ;

    Táá mú kó o láyọ̀, kínú rẹ dùn,

    Tíwọ sì mọ̀ dunjú?

    Àwọn olódodo

    Tó ń gbórúkọ rẹ ga;

    Àwọn tó máa ń ṣègbọràn sí ọ,

    Tó máa ń sọ òtítọ́.

  3. 3. Gbogbo àníyàn wa

    La gbé síwájú rẹ.

    Ojoojúmọ́ lò ń fà wá mọ́ra;

    Ò ń fìfẹ́ ṣìkẹ́ wa.

    A fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ

    Títí ayérayé.

    Kò sọ́rẹ̀ẹ́ míì tó dáa jù ọ́ lọ;

    Kò sọ́rẹ̀ẹ́ míì bíi rẹ.