Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 24

Ẹ Wá sí Òkè Jèhófà

Ẹ Wá sí Òkè Jèhófà

(Àìsáyà 2:2-4)

  1. 1. Bojú wòkè, kó o rí

    Òkè ilé Jèhófà.

    Ó ga ju gbogbo òkè

    Mìíràn tó wà lónìí.

    Láti ibi gbogbo

    Jákèjádò ayé yìí,

    Àwọn èèyàn ń pera wọn

    Wá jọ́sìn Ọlọ́run.

    Ọlọ́run ń darí wa,

    Ó sì ń bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀.

    A sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i;

    A ti di orílẹ̀-èdè ńlá.

    Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé

    Jèhófà lọba ‘láṣẹ.

    Wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin,

    Wọ́n rọ̀ mọ́ Jèhófà.

  2. 2. Jésù ti pàṣẹ pé

    Ká wàásù ìhìnrere.

    Ká jẹ́ kí gbogbo èèyàn

    Gbọ́rọ̀ Ìjọba náà.

    Kristi ń jọba lọ́run,

    Ó ń pe gbogbo aráyé.

    Ó ń fi Bíbélì darí

    Àwọn ẹni yíyẹ.

    Gbogbo wa là ń sapá

    Láti jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀.

    Ayọ̀ kún inú wa,

    Torí ogunlọ́gọ̀ ńlá ń pọ̀ sí i.

    Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa

    Pe àwọn èèyàn wá sí

    Òkè ilé Jèhófà;

    Kí wọ́n má kúrò láé.