Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 20

O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Ọ̀wọ́n

O Fún Wa Ní Ọmọ Rẹ Ọ̀wọ́n

(1 Jòhánù 4:9)

  1. 1. Nígbà tó dà bíi pé

    Kò sírètí fún wa,

    Jèhófà fi ẹ̀jẹ̀

    Ọmọ rẹ̀ rà wá!

    Gbogbo ìgbé ayé

    Wa lá ó máa fi sìn ọ́;

    A ó sì sọ fáráyé,

    Kí ìfẹ́ rẹ lè ṣẹ.

    (ÈGBÈ)

    Títí ayérayé,

    A ó pa ohùn wa pọ̀

    Láti máa kọrin ọpẹ́

    pó o fún wa lọ́mọ rẹ ọ̀wọ́n.

  2. 2. Àánú rẹ, inúure,

    Ń mú kí a sún mọ́ ọ.

    À ń fi orúkọ rẹ

    Pè wá, ó wù wá.

    Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tó ga,

    Tó ṣeyebíye jù

    Ni ikú Ọmọ rẹ

    Tó jẹ́ ká lè ríyè.

    (Ègbè)

    Títí ayérayé,

    A ó pa ohùn wa pọ̀

    Láti máa kọrin ọpẹ́

    pó o fún wa lọ́mọ rẹ ọ̀wọ́n.

    (ÌLÀ ÀKỌPARÍ)

    À ń fàdúrà dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà.

    O ṣeun tí o fún wa ní Ọmọ rẹ ọ̀wọ́n.

(Tún wo Jòh. 3:16; 15:13.)