Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 18

A Mọyì Ìràpadà

A Mọyì Ìràpadà

(Lúùkù 22:20)

  1. 1. A wá síwájú rẹ

    lónìí yìí, Jèhófà,

    Torí ìfẹ́ tó ga jù

    tí o fi hàn sí wa.

    O fọmọ rẹ ọ̀wọ́n rúbọ,

    ká lè ríyè.

    Ẹ̀bùn tó ga jù lọ táa lè

    rí gbà lèyí jẹ́.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ̀jẹ̀ tó ṣe iyebíye

    ni Jésù fi rà wá pa dà.

    Títí ayé,

    la ó máa dúpẹ́ oore ńlá tóo ṣe yìí.

  2. 2. Ikú àtẹ̀ṣẹ̀ sọ wá

    d’aláìnírètí.

    Torí ìfẹ́ ni Jésù

    ṣe fẹ̀mí rẹ̀ rúbọ.

    A ti wá nírètí

    ìyè àìnípẹ̀kun.

    Ó ti dá wa nídè,

    a ti bọ́ lọ́wọ́ ikú.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ̀jẹ̀ tó ṣe iyebíye

    ni Jésù fi rà wá pa dà.

    Títí ayé,

    la ó máa dúpẹ́ oore ńlá tóo ṣe yìí.