Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 15

Ẹ Yin Àkọ́bí Jèhófà!

Ẹ Yin Àkọ́bí Jèhófà!

(Hébérù 1:6)

  1. 1. Ẹ yin Jésù Kristi,

    Àkọ́bí Ọlọ́run wa.

    Jèhófà ti fi jọba,

    Yóò sì bù kún aráyé.

    Yóò jẹ́ kó hàn gbangba pé

    Jèhófà l’Aláṣẹ.

    Yóò dá Jèhófà láre

    Torí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ yin Jésù Kristi,

    Àkọ́bí Ọlọ́run wa!

    Ìjọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀.

    Ó ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in!

  2. 2. Ẹ yin Jésù Kristi,

    Tó kú ká lè ní ìyè.

    Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ rà wá

    Ká lè rí ‘dáríjì gbà.

    Jésù máa tó gbéyàwó,

    Aya rẹ̀ ti ṣe tán.

    Gbogbo ẹ̀dá yóò wá mọ̀

    P’Ọ́lọ́run laláṣẹ.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ yin Jésù Kristi,

    Àkọ́bí Ọlọ́run wa!

    Ìjọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀.

    Ó ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in!