Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 129

A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó

A Ó Máa Fara Dà Á Nìṣó

(Mátíù 24:13)

  1. 1. Jésù Aṣáájú

    Wa fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀.

    Ó nífaradà,

    Ìrètí tó ní fún un láyọ̀.

    Ó ń retí bí ‘lérí

    Bàbá rẹ̀ yóò ṣe ṣẹ.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ jẹ́ ká máa fara dà á,

    Ká fìwà jọ Jésù.

    Jèhófà wà pẹ̀lú wa,

    Ká máa fara dà á títí dé òpin.

  2. 2. Ọ̀pọ̀ àdánwò

    Là ńdojú kọ bá a ṣe ńsin Jáà.

    Ká máa fara dà á;

    Ayọ̀ ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.

    Ká má ṣe rẹ̀wẹ̀sì,

    Ìgbà ọ̀tun dé tán.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ jẹ́ ká máa fara dà á,

    Ká fìwà jọ Jésù.

    Jèhófà wà pẹ̀lú wa,

    Ká máa fara dà á títí dé òpin.

  3. 3. A fẹ́ máa bá a lọ

    Láti fara da àdánwò.

    Ká máa fòótọ́ sìn,

    Ká má bẹ̀rù, ká má fòyà.

    Ká jẹ́ olótìítọ́;

    Ká fara dà á dópin.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ jẹ́ ká máa fara dà á,

    Ká fìwà jọ Jésù.

    Jèhófà wà pẹ̀lú wa,

    Ká máa fara dà á títí dé òpin.