Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 101

À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan

À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan

(Éfésù 4:3)

  1. 1. Ọlọ́run ti yà wá sọ́tọ̀

    Nínú ayé burúkú yìí.

    Ó fi wá sínú ètò rẹ̀

    Ká lè wà lálàáfíà.

    À ń ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan;

    Ó dára, ó dùn!

    Jèhófà ti yan Ọmọ rẹ̀

    Láti darí iṣẹ́ tá à ń ṣe.

    A gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn.

    Ká ṣiṣẹ́ nírẹ̀ẹ́pọ̀.

  2. 2. À ń gbàdúrà s’Ọ́lọ́run pé

    Kíṣọ̀kan gbilẹ̀ láàárín wa.

    Yóò mú kífẹ̀ẹ́ wa gbòòrò sí i,

    Ká sì túbọ̀ láyọ̀.

    Àlàáfíà wa ń pọ̀ sí i,

    Ó ń mára tù wá.

    Jèhófà yóò máa bù kún wa

    Bá a ṣe ń fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn.

    Yóò mú ká máa wà níṣọ̀kan.

    A ó máa sìn ín títí láé.