Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Ètò Ìṣiṣẹ́ Tó Ní Gbogbo Ohun Tá A Nílò

Ètò Ìṣiṣẹ́ Tó Ní Gbogbo Ohun Tá A Nílò

SEPTEMBER 1, 2021

 Nígbà tí Arákùnrin Geoffrey Jackson ń sọ̀rọ̀ nínú fídíò Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2020 #6, ó sọ pé: “Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, ó lè ṣòro láti ronú kan ohun tá à ń ṣe báyìí, ìyẹn bá a ṣe ń gbé oúnjẹ tẹ̀mí jáde lórí ẹ̀rọ.” Ó wá fi kún un pé: “Àmọ́ ní báyìí, kí la à bá ṣe pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn tó gbòde yìí ká sọ pé a ò ní ètò ìṣiṣẹ́ JW Library? Ohun kan ni pé, ó ti pẹ́ tí Jèhófà ti ń múra wa sílẹ̀ fáwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí.”

 Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti ń gbà múra wa sílẹ̀? Àwọn nǹkan wo la ṣe ká tó lè gbé JW Library jáde? Àwọn nǹkan wo la sì ṣe kí ètò ìṣiṣẹ́ náà lé máa ṣiṣẹ́ dáadáa, kó sì sunwọ̀n sí i?

Bá A Ṣe Bẹ̀rẹ̀

 Ní May 2013, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ní kí ẹ̀ka tó ń bójú tó ètò ìṣiṣẹ́ MEPS lóríléeṣẹ́ wa ṣe ètò ìṣiṣẹ́ kan táá ní Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe. Arákùnrin Paul Willies tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀ka tó ń bójú tó ètò ìṣiṣẹ́ MEPS sọ pé: “Ṣáájú ìgbà yẹn, a ò tíì ní ètò ìṣiṣẹ́ kankan táwọn èèyàn lè wà jáde sórí fóònù wọn. Torí náà ká lè ṣiṣẹ́ yìí, a ṣètò àwọn ará mélòó kan kí wọ́n lè jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀, a dá àwọn iṣẹ́ kan dúró, a sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka míì ká lè pawọ́ pọ̀ ṣiṣẹ́ náà. Gbogbo ìgbà la máa ń fọ̀rọ̀ náà sínú àdúrà, Jèhófà sì ràn wá lọ́wọ́ gan-an torí pé ètò Ọlọ́run gbé JW Library jáde ní ìpàdé ọdọọdún tá a ṣe lóṣù márùn-ún péré lẹ́yìn tá a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà!”

 Ohun tó wá kàn ni bá a ṣe máa kó ọ̀pọ̀ ìwé sórí JW Library, tí àá sì tún jẹ́ kó wà ní ọ̀pọ̀ èdè. Nígbà tó fi máa di January 2015, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìwé wa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ti wà lórí JW Library lédè Gẹ̀ẹ́sì. Oṣù mẹ́fà péré lẹ́yìn náà, àwọn ará ti lè wa àwọn ìwé náà jáde ní oríṣiríṣi èdè.

 Látìgbà yẹn la ti ń mú kí JW Library sunwọ̀n sí i. Bí àpẹẹrẹ, a ti gbé àwọn fídíò sórí ẹ̀, a máa ń kó ìwé, orin àti fídíò tá a máa lò fún ìpàdé sójú kan. Bákan náà, àwọn ará lè rí àlàyé tí Ìwé Ìwádìí ṣe lórí ẹsẹ Bíbélì kan ní tààràtà.

Ohun Tá A Máa Ń Ṣe Kí JW Library Lè Máa Ṣiṣẹ́ Dáadáa

 Àwọn èèyàn máa ń ṣí JW Library lórí fóònù àti kọ̀ǹpútà tó tó mílíọ̀nù mẹ́jọ lójoojúmọ́, iye yẹn sì máa ń tó mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lóṣooṣù! Kí la máa ń ṣe kí JW Library lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa lórí àwọn fóònù àtàwọn kọ̀ǹpútà yìí? Arákùnrin Willies sọ pé: “Àtìgbàdégbà lèèyàn gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ lórí àwọn ètò ìṣiṣẹ́ táwọn èèyàn ń lò lórí fóònù. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú JW Library, gbogbo ìgbà la gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ lé e lórí, kó lè túbọ̀ rọrùn fáwọn ará láti lò. Ohun míì ni pé, àtìgbàdégbà ni wọ́n máa ń mú kí ètò ìṣiṣẹ́ táwọn fóònù ń lò sunwọ̀n sí i, torí náà àwa náà gbọ́dọ̀ máa mú kí JW Library sunwọ̀n sí i kó lè bá àwọn ètò ìṣiṣẹ́ tuntun náà ṣiṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé àwọn ìwé, orin àti fídíò tá à ń gbé sórí JW Library túbọ̀ ń pọ̀ sí i, ó gba pé ká máa ṣiṣẹ́ lórí àwọn ètò ìṣiṣẹ́ tá à ń lò láwọn ọ̀fíìsì wa, ká sì máa mú kó sunwọ̀n sí i.” Àwọn ìwé tó wà lórí JW Library lóríṣiríṣi èdè pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì (200,000), àwọn fídíò àtàwọn àtẹ́tísí tó sì wà níbẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600,000)!

 JW Library tó lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa, àwọn nǹkan míì wà tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ètò ìṣiṣẹ́ kan wà tá a máa ń sanwó fún. A máa ń san nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ (1,500) owó dọ́là fún ọ̀kan lára àwọn ètò ìṣiṣẹ́ yìí lọ́dọọdún. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀ka tó ń bójú tó ètò ìṣiṣẹ́ MEPS máa ń ná nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) owó dọ́là lọ́dọọdún lórí oríṣiríṣi fóònù àti kọ̀ǹpútà tuntun, kí wọ́n lè rí i dájú pé JW Library máa ṣiṣẹ́ dáadáa lórí wọn.

Ó Ti Dín Ìnáwó Wa Kù

 JW Library ti jẹ́ kówó tá à ń ná lórí bá a ṣe ń tẹ̀wé àti bá a ṣe ń kówèé ránṣẹ́ dín kù gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀dà ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ tọdún 2013 tá a tẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méjìlá (12). Àmọ́ mílíọ̀nù márùn-ún péré la tẹ̀ fún tọdún 2020, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ti ní àwọn akéde tuntun tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje (700,000). Kí nìdí tí iye tá à ń tẹ̀ fi dín kù tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé orí JW Library lọ̀pọ̀ àwọn ará wa ti ń ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ báyìí. a

“Ẹ̀bùn Àrà Ọ̀tọ̀ Gbáà Ni”

 JW Library tún ti ran àwọn tó ń lò ó lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹ̀ẹrẹ, Geneviève tó ń gbé ní Kánádà gbà pé JW Library ti jẹ́ kóun túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé. Ó sọ pé: “Kí n sòótọ́, ká sọ pé mo máa ní láti kówèé jọ kí n tó kẹ́kọ̀ọ́ ni, bóyá ni màá lè máa kẹ́kọ̀ọ́ láràárọ̀. Àmọ́ JW Library ti mú kó rọrùn fún mi, torí gbogbo ohun tí mo nílò ló wà nínú ẹ̀. Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ déédéé ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi lágbára sí i, kí n sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.”

Geneviève

 JW Library wúlò gan-an pàápàá lásìkò àrùn Corona. Charlyn tó ń gbé ní Amẹ́ríkà sọ pé: “Torí àrùn Corona tó gbayé kan, mi ò tíì rí ìtẹ̀jáde tuntun gbà fún ohun tó lé ní ọdún kan báyìí. Àmọ́ ọpẹ́lọpẹ́ JW Library, ó ti jẹ́ ká ní gbogbo ohun tá a nílò láti mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ yìí.”

 Faye tó ń gbé ní Philippines sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn, ó ní: “Gbogbo ohun tí mo nílò láti mú kí ìgbàgbọ́ mi lágbára kí n sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà ló wà lórí JW Library. Òun ni mo máa ń kọ́kọ́ ṣí tí mo bá jí láàárọ̀. Òun ni mo máa ń tẹ́tí sí tí mo bá ń ṣiṣẹ́ ilé. Òun ni mo máa ń lò tí mo bá ń múra ìpàdé sílẹ̀. Òun náà ni mo máa ń fi múra àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi. Mo máa ń wo fídíò lórí ẹ̀ tọ́wọ́ mi bá dilẹ̀. Tí mo bá sì lọ ra nǹkan bóyá tí mo tò sórí ìlà, mo máa ń ka Bíbélì tàbí àwọn ìtẹ̀jáde míì lórí ẹ̀. Ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ gbáà ni.”

 JW Library tún wúlò gan-an lẹ́nu ìṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń gbé ní Kamẹrúùnù wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lọ́jọ́ kan, ó sì fẹ́ ka ẹsẹ Bíbélì kan tí arábìnrin míì lò lọ́sẹ̀ méjì ṣáájú ìgbà yẹn. Àmọ́ kò rántí ẹsẹ Bíbélì náà mọ́. Arábìnrin náà sọ pé: “Inú mi dùn pé mo rántí ọ̀rọ̀ kan nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn. Torí náà, mo ṣí JW Library, mo lọ sínú Bíbélì, mo wá tẹ ọ̀rọ̀ tí mo rántí síbẹ̀. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo rí ẹsẹ Bíbélì tí mò ń wá. JW Library ti jẹ́ kó rọrùn fún mi láti wá àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo bá gbàgbé.”

 Àwọn ọrẹ tẹ́ ẹ fi ń ránṣẹ́ lórí ìkànnì donate.isa4310.com ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti gbé JW Library jáde àti láti mú kó sunwọ̀n sí i, kó lè rọrùn fáwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kárí ayé láti rí i lò. Ẹ ṣeun gan-an fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín.

Bá A Ṣe Ń Mú Kí JW Library Sunwọ̀n Sí I

  1. October 2013—A gbé JW Library jáde, a sì fi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe sínú ẹ̀

  2. January 2015—A fi àwọn ìtẹ̀jáde míì sínú ẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì, nígbà tó sì yá, a fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè kún un

  3. November 2015—A mú kó ṣeé ṣe láti kun ọ̀rọ̀

  4. May 2016—A fi apá tá a pè ní Meetings sí i

  5. May 2017—A fi apá téèyàn ti lè ṣe àkọsílẹ̀ kún un

  6. December 2017—A fi Bíbélì tó wà fún Ìdákẹ́kọ̀ọ́ sínú ẹ̀

  7. March 2019—Àwọn ará lè wa àwọn àtẹ́tísí jáde, wọ́n lè wo fídíò lórí ẹ̀, wọ́n sì lè rí àlàyé tí Ìwé Ìwádìí ṣe lórí ẹsẹ Bíbélì kan

  8. January 2021—A mú kí JW Library sunwọ̀n sí i torí ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!

a Gbogbo ìgbà táwọn èèyàn bá wa ohun kan jáde lórí JW Library ni ètò Ọlọ́run máa ń san owó táṣẹ́rẹ́ kan. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún tó kọjá, ohun tó lé ní mílíọ̀nù kan ààbọ̀ owó dọ́là la ná ká lè gbé ìwé àtàwọn fídíò táwọn ará lè wà jáde sórí ìkànnì jw.org àti JW Library. Síbẹ̀, owó tá a ná yìí ò tó nǹkan kan rárá tá a bá fi wé iye tá a máa ń ná láti tẹ̀wé àti láti fi wọ́n ránṣẹ́.