Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

À Ń Ṣèpàdé Látorí Ẹ̀rọ Ayélujára

À Ń Ṣèpàdé Látorí Ẹ̀rọ Ayélujára

JUNE 26, 2020

 Ọ̀pọ̀ ìjọba kárí ayé ti ṣòfin pé káwọn èèyàn jìnnà síra wọn, wọ́n sì ti fagi lé e pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa pàdé pọ̀. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé òfin yìí, síbẹ̀ à ń ṣèpàdé lọ́nà tí kò ní hu wá léwu. Ohun tó mú kíyẹn ṣeé ṣe ni pé àwọn ará wa ń ṣèpàdé látorí ẹ̀rọ ayélujára, irú bíi Zoom.

 Kó lè rọrùn fún àwọn ará wa láti máa gbádùn ìpàdé, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká lò lára àwọn ọrẹ tá a gbà láti san owó àdéhùn káwọn ìjọ lè lo ètò ìṣiṣẹ́ Zoom. Àwọn ìjọ kan sì ti ń gbádùn ìpàdé nítorí ètò tá a ṣe yẹn, pàápàá àwọn tí ò ní owó tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà sí mẹ́jọ náírà ($15-$20) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láti san owó àdéhùn fún ètò ìṣiṣẹ́ yìí. Ṣáájú ká tó ṣe ètò yìí, ètò ìṣiṣẹ́ ọ̀fẹ́ ni ọ̀pọ̀ ìjọ ń lò, ìyẹn sì mú kó nira fún wọn láti máa gbádùn ìpàdé dáadáa tàbí kó jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn ló lè máa ṣe ìpàdé lẹ́ẹ̀kan náà. Àmọ́ àwọn ìjọ tó ń lo ètò ìṣiṣẹ́ Zoom tá a sanwó fún yìí ti ń gbádùn ìpàdé dáadáa, ó sì jẹ́ kó rọrùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti wọlé sórí ètò ìṣiṣẹ́ yìí kí wọ́n lè ṣèpàdé pa pọ̀. Ní báyìí, ìjọ tó ju ẹgbẹ̀rún márùnlélọ́gọ́ta (65,000) ní orílẹ̀-èdè tó ju àádọ́sàn-án (170) ti ń lo ètò ìṣiṣẹ́ yìí.

 Bí àpẹẹrẹ lórílẹ̀-èdè Indonesia, ètò ìṣiṣẹ́ ọ̀fẹ́ ni Ìjọ Kairagi tó wà nílùú Manado, ní North Sulawesi ń lò tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ètò ìṣiṣẹ́ Zoom tá a sanwó fún. Arákùnrin Hadi Santoso tó wà níjọ yìí sọ pé: “Kódà àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ bí wọ́n ṣe ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé ti wá ń gbádùn ìpàdé lórí ètò ìṣiṣẹ́ yìí torí pé wọn ò nílò láti máa wọlé léraléra sórí ètò ìṣiṣẹ́ tí wọ́n fi ń ṣèpàdé bíi ti tẹ́lẹ̀.”

 Alàgbà kan tó ń jẹ́ Lester Jijón, Jr. ní ìjọ Guayacanes Oeste nílùú Guayaquil lórílẹ̀-èdè Ecuador sọ pé: “Ká sọ pé àwọn ará la ní kó tu owó jọ fún ètò ìṣiṣẹ́ Zoom, ó dájú pé kò ní lè ṣeé ṣe torí pé ọ̀pọ̀ ni ò lówó. Àmọ́ ní báyìí tí ètò Ọlọ́run ti bá wa san owó yìí, a lè gbádùn ìpàdé, kódà a tún lè pe àwọn míì láìbẹ̀rù pé èèyàn máa pọ̀ jù.”

 Alàgbà míì lórílẹ̀-èdè Zambia tó ń jẹ́ Johnson Mwanza ní ìjọ Ngwerere North nílùú Lusaka sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn arákùnrin àti arábìnrin ti sọ pé, ‘yàtọ̀ sí pé ètò ìṣiṣẹ́ Zoom yìí ti jẹ́ káwa ará túbọ̀ sún mọ́ ara wa, ó tún ti jẹ́ ká túbọ̀ rí ọwọ́ ìfẹ́ Jèhófà.’”

 Díẹ̀ lára owó tá a yà sọ́tọ̀ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá la lò láti san owó fún ètò ìṣiṣẹ́ yìí. Ìtìlẹyìn táwọn ará wa ń ṣe kárí ayé ló sì ń jẹ́ ká rí owó yìí. Ọ̀pọ̀ lára ẹ̀ ló jẹ́ pé orí ìkànnì donate.isa4310.com ní wọ́n ti fi ránṣẹ́. Ẹ ṣeun o ẹ̀yin ará wa fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yìn, ẹ ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wá láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ kárí ayé.​—2 Kọ́ríńtì 8:14.