Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Atúmọ̀ Èdè Méjì Dá Orúkọ Ọlọ́run Pa Dà Sínú Májẹ̀mú Tuntun

Àwọn Atúmọ̀ Èdè Méjì Dá Orúkọ Ọlọ́run Pa Dà Sínú Májẹ̀mú Tuntun

 Ọ̀kan lára àdúrà tọ́pọ̀ èèyàn kọ́kọ́ mọ̀ ni Àdúrà Olúwa tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀. Àdúrà yìí wà nínú apá Bíbélì táwọn èèyàn sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun. Ohun tí Jésù fi bẹ̀rẹ̀ àdúrà náà ni: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti túmọ̀ orúkọ Ọlọ́run sí “Jehovah” tàbí “Yahweh” lédè Gẹ̀ẹ́sì, síbẹ̀ ó ṣọ̀wọ́n kẹ́ ẹ tó rí orúkọ náà nínú apá Májẹ̀mú Tuntun nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tí wọ́n ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ohun tó yani lẹ́nu ni pé àwọn ìtumọ̀ Bíbélì yìí lo orúkọ àwọn òrìṣà bíi Súúsì, Hẹ́mísì, àti Átẹ́mísì. Torí náà, ṣé kò wá yẹ kí wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ tó jẹ́ pé òun gan-an ló ni Bíbélì?​—Ìṣe 14:12; 19:35; 2 Tímótì 3:16.

Tí orúkọ àwọn òrìṣà mélòó kan bá lè wà nínú Májẹ̀mú Tuntun, ṣé kò wá yẹ kí orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ náà wà níbẹ̀?

 Àwọn atúmọ̀ èdè méjì tó túmọ̀ Bíbélì sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn Lancelot Shadwell àti Frederick Parker gbà pé ó yẹ kí wọ́n dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sínú Májẹ̀mú Tuntun. Kí nìdí tí wọ́n fi sọ pé kí wọ́n dá a “pa dà”? Ìdí ni pé wọ́n gbà pé orúkọ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì àtijọ́, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n yọ ọ́ kúrò. Kí ló mú kí wọ́n gbà bẹ́ẹ̀?

 Shadwell àti Parker mọ̀ pé èdè Hébérù ni wọ́n fi kọ apá ti Májẹ̀mú Láéláé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà ni orúkọ Ọlọ́run sì fara hàn níbẹ̀. Ìyẹn wá mú kí wọ́n máa ronú pé tí orúkọ Ọlọ́run bá wà nínú Májẹ̀mú Láéláé, kí nìdí tí ò fi sí nínú Májẹ̀mú Tuntun. a Bákan náà, Shadwell kíyè sí i pé nígbà tí Májẹ̀mú Tuntun bá lo àwọn ọ̀rọ̀ kan tó sábà máa ń fara hàn nínú Májẹ̀mú Láéláé irú bí “áńgẹ́lì Jèhófà,” ṣe làwọn tó ṣe àdàkọ Májẹ̀mú Tuntun lédè Gíríìkì á fi àwọn ọ̀rọ̀ bíi Kyʹri·os, tó túmọ̀ sí “Olúwa”rọ́pò orúkọ Ọlọ́run.​—2 Àwọn Ọba 1:3, 15; Ìṣe 12:23.

Orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù

 Kódà, kí Shadwell àti Parker tó ṣe ìtumọ̀ Bíbélì wọn lédè Gẹ̀ẹ́sì, àwọn atúmọ̀ èdè míì ti dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sínú Májẹ̀mú Tuntun nínú àwọn Bíbélì kan tí wọ́n túmọ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì, àmọ́ àwọn ibi mélòó kan péré lorúkọ náà ti fara hàn. b Ṣáájú kí Parker tó ṣe Bíbélì A Literal Translation of the New Testament lọ́dún 1863, kò sí atúmọ̀ èdè kankan tó dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sí ọ̀pọ̀ àwọn ibi tó ti fara hàn nínú Májẹ̀mú Tuntun. Àmọ́ ta tiẹ̀ ni Lancelot Shadwell àti Frederick Parker?

Lancelot Shadwell

 Agbẹjọ́rò àgbà ni Lancelot Shadwell (1808-1861), òun sì ni ọmọ Sir Lancelot Shadwell tó jẹ́ adájọ́ àgbà orílẹ̀-èdè England. Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lò ń dara pọ̀ mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó nígbàgbọ́ nínú Mẹ́talọ́kan, ó bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run, kódà ó pè é ní “orúkọ ológo ti JÈHÓFÀ.” Nínú ìtumọ̀ ìwé The Gospels of Matthew, and of Mark tó ṣe, ìgbà méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ni orúkọ náà “Jèhófà” fara hàn nínú ẹ̀, ìgbà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti márùndínláàádọ́rin (465) ló sì fara hàn nínú àwọn àlàyé etí ìwé.

 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú Májẹ̀mú Láéláé tí wọ́n kọ lédè Hébérù ni Shadwell ti rí orúkọ Ọlọ́run. Ó wá sọ pé “àwọn atúmọ̀ èdè tí kì í ṣe olóòótọ́” ló fi ọ̀rọ̀ náà Kyʹri·os rọ́pò orúkọ Ọlọ́run nínú Májẹ̀mú Láéláé tí wọ́n kọ lédè Gíríìkì.

Ìwé The Gospel according to Matthew tí wọ́n tú sí èdè Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú àlàyé etí ìwé, látọwọ́ L. Shadwell (1859), nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Bodleian Libraries. Lábẹ́ àṣẹ CC BY-NC-SA 2.0 UK. Modified: Text highlighted

Ìtumọ̀ Bíbélì Shadwell, Mátíù 1:20 hàn níbẹ̀

 Nínú ìtumọ̀ tí Shadwell ṣe, inú Mátíù 1:20 ló ti kọ́kọ́ lo orúkọ “Jèhófà.” Nínú àlàyé etí ìwé tó wà fún ẹsẹ yẹn, ó sọ pé: “JÈHÓFÀ ni ọ̀rọ̀ náà [Kyʹri·os] nínú ẹsẹ yìí àti nínú ọ̀pọ̀ àwọn ẹsẹ míì nínú Májẹ̀mú Tuntun túmọ̀ sí, orúkọ yìí gan-an sì ni orúkọ Ọlọ́run: ó sì ṣe pàtàkì gan-an pé ká dá orúkọ yìí pa dà sínú àwọn Bíbélì tí wọ́n tú lédè Gẹ̀ẹ́sì.” Ó tún sọ pé: “A gbọ́dọ̀ máa lo orúkọ yìí ká lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún un. Ó ti jẹ́ ká mọ̀ pé JÈHÓFÀ ni orúkọ òun: orúkọ yìí ló sì yẹ ká máa lò nígbàkigbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.” Ó wà sọ pé: “Nínú Bíbélì King James Version, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lo orúkọ JÈHÓFÀ . . . Kàkà kí wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run, wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà Olúwa rọ́pò rẹ̀.” Shadwell sọ pé: ‘Kò bá a mu rárá bí wọ́n ṣe fi orúkọ oyè náà Olúwa rọ́pò orúkọ Ọlọ́run.’ Ìdí ni pé àwọn èèyàn máa ń pe òun fúnra òun ní “Olúwa” tóun bá wà nílé.

“[Ọlọ́run] ti jẹ́ ká mọ̀ pé JÈHÓFÀ ni orúkọ òun: orúkọ yìí ló sì yẹ ká máa lò nígbàkigbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.”​—Lancelot Shadwell

 Lọ́dún 1859, Shadwell mú ìtumọ̀ ìwé Mátíù jáde, nígbà tó sì dọdún 1861, ó mú àpapọ̀ ìwé Mátíù àti Máàkù jáde. Àmọ́ ibi tí iṣẹ́ rẹ̀ parí sí nìyẹn torí pé ó kú ní January 11, 1861, lẹ́ni ọdún méjìléláàádọ́ta (52). Ṣùgbọ́n, ìsapá rẹ̀ ò já sásán.

Frederick Parker

 Oníṣòwò kan tó lówó ni Frederick Parker (1804-1888), ìlú London ló sì ń gbé. Nígbà tó rí ìtumọ̀ ìwé Mátíù tí Shadwell ṣe, inú rẹ̀ dùn gan-an torí pé àtìgbà tó ti wà lọ́mọ ogún (20) ọdún ló ti pinnu pé òun máa túmọ̀ Májẹ̀mú Tuntun. Àmọ́ Parker ò gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́ bíi ti Shadwell. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó kọ̀wé pé: “Ǹjẹ́ kí gbogbo Kristẹni . . . gba òótọ́ yìí gbọ́ tọkàntọkàn . . . kí wọ́n sì jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè.” Parker tún gbà pé àwọn ìwé Májẹ̀mú Tuntun tó lo Kyʹri·os fún Ọlọ́run àti Jésù mú kó ṣòro láti rí i pé àwọn méjèèjì yàtọ̀ síra. Torí ẹ̀, inú ẹ̀ dùn gan-an láti rí i pé Shadwell lo “Jèhófà” láwọn ibì kan tí wọ́n ti lo Kyʹri·os.

 Báwo ni Parker ṣe mọ̀ pé orúkọ Ọlọ́run wà nínú Májẹ̀mú Tuntun? Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa èdè Gíríìkì, ó sì kọ onírúurú ìwé nípa gírámà èdè Gíríìkì. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Anglo-Biblical Institute tó máa ń ṣagbátẹrù àwọn tó ń ṣèwádìí nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́, torí kí wọ́n lè túmọ̀ Bíbélì lọ́nà tó péye sí èdè Gẹ̀ẹ́sì. Lọ́dún 1842, Parker bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àkọ́kọ́ nínú Májẹ̀mú Tuntun tó ṣe jáde ní apá kéékèèké. c

Ìtumọ̀ Májẹ̀mú Tuntun látọwọ́ Parker (Heinfetter)

Akitiyan Parker Láti Dá Orúkọ Ọlọ́run Pa Dà

 Ó ti tó bí ọdún mélòó kan tí Parker ti kọ̀wé nípa àwọn ìbéèrè bíi: “Báwo la ṣe máa mọ̀ bóyá Jésù ni Kyʹri·os tí wọ́n lò nínú ẹsẹ Bíbélì kan túmọ̀ sí àbí Ọlọ́run?” “Kí nìdí tí wọ́n fi sábà máa ń lo Kyʹri·os bí orúkọ dípò kó jẹ́ oyè ẹni tí wọ́n ń tọ́ka sí?”

 Nígbà tí Parker rí ìtumọ̀ ìwé Mátíù tí Shadwell ṣe lọ́dún 1859 àti àlàyé tó ṣe nípa Kyʹri·os, ó túbọ̀ dá a lójú pé láwọn ibì kan tí wọ́n bá ti lo Kyʹri·os, “ṣe ló yẹ kí wọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí Jèhófà.” Torí náà, ó ṣàtúnṣe gbogbo Májẹ̀mú Tuntun tó ti túmọ̀ tẹ́lẹ̀, ó sì fi “Jèhófà” sí gbogbo ibi tó gbà pé àyíká ọ̀rọ̀ náà àti gírámà èdè Gíríìkì fi hàn pé ó yẹ kó wà. Nípa bẹ́ẹ̀, ìgbà ọgọ́sàn-án ó lé méje (187) ni orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú ìwé A Literal Translation of the New Testament tí Parker ṣe lọ́dún 1863. Kódà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwé yìí ni ìwé tó máa kọ́kọ́ lo orúkọ Ọlọ́run jálẹ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. d

Ojú ìwé àkọ́kọ́ nínú ìtumọ̀ Májẹ̀mú Tuntun tí Parker ṣe lọ́dún 1864

 Lọ́dún 1864, Parker tẹ ìwé A Collation of an English Version of the New Testament . . . With the Authorized English Version. Ìdí tó fi tẹ ìwé Májẹ̀mú Tuntun méjèèjì náà sójú kan ni pé, ó fẹ́ káwọn èèyàn rí àwọn ibi tí ìtumọ̀ tiẹ̀ ti yàtọ̀ sí táwọn míì. e

 Kí Parker lè tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n dá orúkọ Ọlọ́run pa dà, ó tọ́ka sáwọn ẹsẹ mélòó kan nínú Bíbélì Authorized Version. Bí àpẹẹrẹ, ó mẹ́nu kan Róòmù 10:13 tó sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” Parker wá béèrè pé: “Báwo lèèyàn ṣe fẹ́ mọ̀ pé Jèhófà ni ẹsẹ yìí àtàwọn míì nínú Bíbélì Authorized English Version ń sọ dípò Ọmọ rẹ̀, ìyẹn Jésù Olúwa”?

Róòmù 10:13 nínú Bíbélì King James Version (lókè) àti ìtumọ̀ tí Parker ṣe lọ́dún 1864

 Owó kékeré kọ́ ni Parker ná láti tẹ onírúurú ìwé, kó sì polówó àwọn ìwé náà. Kódà, ní ọdún kan ṣoṣo, ó ná ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) pounds, ìyẹn ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìléláàádóje (132,000) owó dọ́là lónìí. Ó tún fi ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tó tẹ̀ ránṣẹ́ lọ́fẹ̀ẹ́ sáwọn ọ̀jọ̀gbọ́n àtàwọn bíṣọ́ọ̀bù tó lẹ́nu láwùjọ, kí wọ́n lè yẹ̀ ẹ́ wò.

 Ìwọ̀nba díẹ̀ láwọn ìwé Parker tí wọ́n tẹ̀ jáde. Kódà, ó dunni pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan bẹnu àtẹ́ lu àwọn ìwé tó kọ àtàwọn ìtumọ̀ Májẹ̀mú Tuntun tó ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n náà ò mọrírì gbogbo akitiyan tí Parker, Shadwell àtàwọn míì ṣe láti dá orúkọ Ọlọ́run pa dà sínú Májẹ̀mú Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì.

 Ó tún lè wo fídíò oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́wàá yìí kó o lè mọ púpọ̀ sí i: Warwick Museum Tours: “The Bible and the Divine Name.”

a “Jáà,” ni ìkékúrú “Jèhófà,” ó sì wà nínú Ìfihàn 19:1, 3, 4, 6 nínú gbólóhùn náà “Halelúyà,” tó túmọ̀ sí “Ẹ yin Jáà!”

b Shadwell kọ́ ló túmọ̀ gbogbo Májẹ̀mú Tuntun. Àwọn atúmọ̀ èdè míì tí wọ́n ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀ ni Philip Doddridge, Edward Harwood, William Newcome, Edgar Taylor, àti Gilbert Wakefield.

c Kó lè fi ìyàtọ̀ sáàárín òwò tó ń ṣe àti iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì, Parker máa ń lo orúkọ náà Herman Heinfetter nínú àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì àti ìtumọ̀ Bíbélì tó kọ. Orúkọ yìí fara hàn nígbà mélòó kan nínú àwọn àfikún tó wà lẹ́yìn Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

d Lọ́dún 1864, Parker mú Bíbélì An English Version of the New Testament jáde. Ìgbà ọgọ́sàn-án ó lé mẹ́fà (186) ni orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú ẹ̀.

e Kí Parker tó ṣe ìtumọ̀ Bíbélì ẹ̀ jáde, ọ̀pọ̀ àwọn ìwé Májẹ̀mú Tuntun tí wọ́n kọ lédè Hébérù lo orúkọ Ọlọ́run láwọn ẹsẹ Bíbélì kan. Bákan náà lọ́dún 1795, Johann Jakob Stolz tẹ ìtumọ̀ Bíbélì kan jáde lédè German, orúkọ Ọlọ́run sì fara hàn ní ohun tó ju àádọ́rùn-ún (90) ìgbà lọ nínú ìwé Mátíù sí Júùdù.