Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

“Àwọn Ètò Orí Tẹlifíṣọ̀n JW Ti Lọ Wà Jù!”

“Àwọn Ètò Orí Tẹlifíṣọ̀n JW Ti Lọ Wà Jù!”

NÍ October 6, 2014, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ètò kan lọ́lẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì èyí tá a pè ní ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW. Èdè Gẹ̀ẹ́sì la kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀ ká lè mọ bó ṣe máa rí. * Àmọ́ láti August 2015 la ti tú ètò orí Tẹlifíṣọ̀n yìí sí èdè tó jú àádọ́rin [70] lọ káwọn ará tó pọ̀ sí i lè gbádùn àwọn ètò tó ń gbéniró náà. Àìmọye èèyàn tó ń wo ètò yìí kárí ayé ló ti kọ̀wé láti dúpẹ́ fún àrànṣe ńlá yìí. Àmọ́, báwo la ṣe bẹ̀rẹ̀ ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW?

A kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wá ibi tá a máa lò fún ètò orí Tẹlifíṣọ̀n náà. A rí àyè tó dáa nínú ilé tó wà ní 30 Columbia Heights, ní Brooklyn, New York tí oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà. Láàárín ọ̀sẹ̀ kan péré, a palẹ̀ gbogbo nǹkan tó wà níbẹ̀ mọ́. Ẹ̀ka tó ń ṣàtúnṣe ilé bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bí a ò ṣe máa gbé ohùn àti àwòrán jáde, ẹ̀ka tó ń yàwòrán ilé sì ń wá bí yàrá ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà á ṣe bójú mu táá sì bágbà mu. Ọ̀pọ̀ ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó wà káàkiri ilẹ̀ Amẹ́ríkà ló ṣiṣẹ́ tọ̀sán-tòru tí wọ́n ń yàwòrán bí yàrá náà ṣe máa rí àti bí wọ́n á ṣe tètè parí gbogbo ìṣètò náà. Àwọn ìwádìí tí ì bá gba ọ̀pọ̀ oṣù làwọn ará parí láàárín ọjọ́ mélòó kan péré. Kíá ni ẹ̀ka tó ń ra nǹkan ti bẹ̀rẹ̀ sí í ra ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ohun èlò tá a nílò.

Wáyà iná tí wọ́n lò fún iṣẹ́ yìí pọ̀ gan-an, gbogbo wọn sì so kọ́ra lọ, bẹ́ẹ̀ wọ́n gbọ́dọ̀ rí i pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wáyà náà wà láyè tiẹ̀ kí àwọn ẹ̀rọ lè máa ṣiṣẹ́ geerege. Gbogbo bí ìyẹn ṣe ń lọ lọ́wọ́ ni àwọn ará tó ń bá wa kọrin ń ṣiṣẹ́ lọ ní pẹrẹu níbi tí wọ́n ti ń gba ohùn orin tá a maa máa lò fún ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW sílẹ̀. Àwọn yàrá tá a ti ń gba ohùn àti fídíò sílẹ̀ ní Patterson ni wọ́n lò. Àwọn ará lọ́kùnrin àtí lóbìnrin tó wá látàwọn orílẹ̀-èdè míì ràn wọ́n lọ́wọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀tọ̀ lorin táwọn wá kọ nígbà yẹn. Ó wá ku àwọn fídíò tá a máa lò. Kíá, a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn ọ̀rọ̀ fídíò sílẹ̀ lóríṣiríṣi, a ṣètò bá a ṣe máa ṣàṣefihàn àwọn ìrírí, ẹ̀yìn ìyẹn làwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ká tó ń gba ohùn àti fídíò sílẹ̀ láwọn ọ́fíìsì wa tó wà ní Brooklyn, Patterson, Wallkill àti kárí ayé ṣiṣẹ́ lórí àwọn fídíò náà títí tó fi parí. Nígbà tá a rí i pé yàrá ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ti wà ní sẹpẹ, tí a sì ti fi gbogbo ohun èlò tá a nílò síbi tó yẹ, a bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ fún àwọn ètò tá a máa gbé sáfẹ́fẹ́ lóṣù àkọ́kọ́ àtàwọn oṣù tó máa tẹ̀ lé e.

Yàrá ìgbóhùn-sáfẹ́fẹ́ tá à ń lò fún Tẹlifíṣọ̀n JW tó wà ní ìlú Brooklyn, New York

A béèrè lọ́wọ́ ẹnì kan tó jẹ́ ìjìnmì nínú béèyàn ṣe ń múra yàrá ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ sílẹ̀, pé báwo ló ṣe máa ń pẹ́ tó láti ṣètò yàrá ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tó tòbi tó irú tiwa yìí, ó ní á tó ọdún kan ààbọ̀. Àmọ́, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé oṣù méjì péré làwọn akínkanjú arákùnrin àti arábìnrin wa fi ṣe é.

Iṣẹ́ takuntakun yìí sì tì méso rere jáde. Bí àpẹẹrẹ, lóṣooṣù, àwọn èèyàn ń wo ètò oṣoòṣù tá a máa ń gbé jáde ní gbogbo Monday àkọ́kọ́ ní ohun tó ju mílíọ̀nù méjì ìgbà lọ. Wọ́n sì ń wo gbogbo àwọn fídíò tá à ń gbé jáde ní èyí tó ju mílíọ̀nù mẹ́wàá ìgbà lọ.

“Àwọn ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW jẹ́ kí ń túbọ̀ sún mọ́ ètò Jèhófà àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí gan-an. Mo mọ̀ pé mo wà nínú ìdílé tí ìfẹ́ ti jọba.”—Kẹ́ńyà

Ojú wo láwọn èèyàn Jèhófà fi wo ọ̀nà tuntun tá à ń gbà gbé oùnjẹ tẹ̀mí jáde yìí? Ẹ gbọ́ díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ táwọn ara sọ:

  • “Alẹ́ yìí jẹ́ ọ̀kan lára ọjọ́ tí inú mi dùn jù láyé mi! Lẹ́yìn témi àti ìyàwó mi wo ètò ti oṣù May 2015 lórí Tẹlifíṣọ̀n JW lálẹ yìí, béèyàn bá gẹṣin nínú mi kò ní kọsẹ̀. Ọ̀kan lára ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tí Jèhófà fún mi nìyí. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí àtàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ṣe ká lè jànfààní nínú ìṣètò tẹ̀mí tó gọntiọ yìí.”—Indonéṣíà.

  • “Kó tó di pé a bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW jáde, ọ̀pọ̀ àwọn ará ni ò tíì gbọ́ àsọyé tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ rí láyé wọn. Àmọ ní báyìí, kì í ṣe pé wọ́n ń gbọ́ nìkan, wọ́n tún ń rí wọn sójú pàápàá. Inú wa dùn pé àwa náà wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Olùdarí àti ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé.”—Kẹ́ńyà.

  • “Torí pe ọkọ mi kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, kò rọrùn fún mi láti ṣe ìjọ̀sìn ìdílé pẹ̀lú àwọn ọmọ mi méjì tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́. Àmọ́ ṣe ló dà bíi pé èmi ni wọ́n ṣe àwọn ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW yẹn fún. Ó jẹ́ kí ń nímọ̀lára pé mo wà lára ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé, àwọn ètò náà sì máa ń ran àwọn ọmọ mi lọ́wọ́ gan-an. Ní ti gidi, ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà lèyí.”—Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

  • “Àwọn ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW ti lọ wà jù! Ìgbà tí ètò Ọlọ́run wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé e jáde ní oríṣiríṣi èdè, ṣe ló dà bíi pé àdúrà wa ló gbà. Bí ẹ̀yin ará ṣe ń fi inúure àti àyọ ṣe iṣẹ́ Jèhófà ń fún wa níṣìírí gan-an. Àtìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW la ti ń nímọ̀lára pé a sún mọ́ ètò Jèhófà tó kárí ayé ju ti ìgbàkigbà rí lọ.”—Czech Republic.

  • “Bí mo ṣe ń gbọ́ táwọn Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń bá mi sọ̀rọ̀ ní èdè mi jẹ́ kí ń túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.”—Brazil.

  • “Ọdún kẹrìndínlógún [16] rèé tí mo ti ń sin Jèhófà bọ̀, àmọ́ irú ayọ̀ tí mo ní lónìí ò wọ́pọ̀. Ṣe ló dà bíi tọjọ́ tí mo ṣèrìbọmi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀yin ará fún ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW.”—Brazil.

Lágbára Jèhófà, a gbà pé ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW á jẹ́ ká túbọ̀ máa sún mọ́ ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé. Yàtọ̀ síyẹn, ètò yìí á mú kí ìyìn àti ògo Jèhófà máa pọ̀ sí i.

^ ìpínrọ̀ 1 A máa ń gbé ètò orí Tẹlifíṣọ̀n JW jáde lórí ìkànnì tv.isa4310.com.