Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Ọlọ́run Ń Fẹ́?

Kí Ni Ọlọ́run Ń Fẹ́?

Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbé ní àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé títí láé!

Àmọ́, o lè máa wò ó pé, ‘Ǹjẹ́ ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ láé?’ Bíbélì sọ pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú kó ṣeé ṣe, Ọlọ́run sì fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ nípa Ìjọba yẹn àti ohun tí òun fẹ́ ṣe fún aráyé.​—Sáàmù 37:11, 29; Àìsáyà 9:7.

Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe ara wa láǹfààní.

Bó ṣe jẹ́ pé bàbá rere máa ń fẹ́ ohun tó dára jù lọ fún àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe wu Bàbá wa ọ̀run pé ká máa láyọ̀ títí lọ. (Àìsáyà 48:17, 18) Ó ti ṣèlérí pé “ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló máa wà títí láé.”​—1 Jòhánù 2:17.

Ọlọ́run fẹ́ ká máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.

Bíbélì sọ pé Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ “kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀” ká lè “máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.” (Àìsáyà 2:2, 3) Ó ti ṣètò ‘àwọn èèyàn kan fún orúkọ rẹ̀,’ kí wọ́n lè máa sọ ohun tó fẹ́ fún àwọn èèyàn kárí ayé.​—Ìṣe 15:14.

Ọlọ́run ń fẹ́ ká máa sin òun ní ìṣọ̀kan.

Ìjọsìn mímọ́ Jèhófà kì í pín àwọn èèyàn níyà, ńṣe ló ń mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. (Jòhánù 13:35) Lónìí, àwọn wo ló ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin níbi gbogbo kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe máa sin Ọlọ́run níṣọ̀kan? A fẹ́ kó o ka ìwé yìí kó o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà.