Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | DÈBÓRÀ

“Mo Dìde Gẹ́gẹ́ Bí Ìyá ní Ísírẹ́lì”

“Mo Dìde Gẹ́gẹ́ Bí Ìyá ní Ísírẹ́lì”

DÈBÓRÀ ń wo àwọn ọmọ ogun tó péjọ sórí Òkè Ńlá Tábórì. Bí wọ́n ṣe péjọ síbẹ̀ wú u lórí gidigidi. Ilẹ̀ ti mọ́ báyìí, Dèbórà wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ìgboyà àti ìgbàgbọ́ Bárákì tó jẹ́ ọ̀gá àwọn ọmọ ogun náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] làwọn ọmọ ogun yìí, wọ́n máa tó rí ohun tó máa dán ìgbàgbọ́ àti ìgboyà wọn wò. Àwọn ọ̀tá tó jẹ́ ọ̀dájú ni wọ́n fẹ́ lọ bá jà, àwọn ọ̀tá yìí sì pọ̀ jù wọ́n lọ fíìfíì. Kódà wọn ò ní ohun ìjà ogun tí wọ́n lè fi kojú wọn. Àmọ́ wọn ò ka gbogbo ìyẹn sí, torí pé Dèbórà ti kì wọ́n láyà.

Fojú inú wo bí atẹ́gùn ṣe ń fẹ́ aṣọ Dèbórà nígbà tí òun àti Bárákì ń wo ilẹ̀ tó fẹ̀ lọ salalu. Ńṣe ni orí Òkè Ńlá Tábórì yìí tẹ́jú pẹrẹsẹ. Téèyàn bá wà lórí òkè yìí, á máa rí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Esdraelon, tó jìn tó irinwó [400] mítà látorí òkè náà, tó sì fẹ̀ lọ sí apá gúúsù ìwọ̀ oòrùn. Odò Kíṣónì sì ń ṣàn gba gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Kámẹ́lì lọ sínú Òkun Ńlá. Ó ṣeé ṣe kí odò náà ti gbẹ lásìkò yìí, àmọ́ nǹkan míì wà tó ń dán gbinrin lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú pẹrẹsẹ náà. Àwọn ọmọ ogun Sísérà ti ń sùn mọ́ tò sí. Irin tó wà lára aṣọ wọn sì ń kọ mọ̀nà. Àwọn tó jẹ́ akínkanjú lára àwọn ọmọ ogun Sísérà ló ń bọ̀ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] kẹ̀kẹ́ ẹṣin. Dòjé irin tó mú bérébéré sì wà lára àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà. Gbogbo èrò Sísérà ni pé kí òun kàn máa fi ṣá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì balẹ̀ láìjanpata!

Dèbórà mọ̀ pé Bárákì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ń retí pé kí òun sọ ohun tí wọ́n máa ṣe. Ṣé òun nìkan ni obìnrin tó wà láàárín wọn? Báwo ni iṣẹ́ bàǹtàbanta tó já lé e léjìká yìí ṣe máa rí lára rẹ̀? Ǹjẹ́ bó ṣe wà láàárín wọn tiẹ̀ yà á lẹ́nu? Rárá o! Ìdí ni pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ti sọ fún un pé kó ja ogun yìí, ó sì tún sọ fún un pé obìnrin ni òun máa lò láti ṣẹ́gun. (Àwọn Onídàájọ́ 4:9) Kí ni Dèbórà àtàwọn ọmọ ogun onígboyà yìí kọ́ wa nípa ohun tó túmọ̀ sí láti ní ìgbàgbọ́?

“LỌ, KÍ O SÌ TAN ARA RẸ KÁ ORÍ ÒKÈ ŃLÁ TÁBÓRÌ”

Nígbà tí Bíbélì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Dèbórà, ó pè é ní “wòlíì obìnrin.” Èyí mú kí Dèbórà dá yàtọ̀ nínú àwọn obìnrin tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn, àmọ́ ṣá o, kì í ṣe òun nìkan ni wòlíì obìnrin. * Ọlọ́run tún gbé iṣẹ́ míì lé Dèbórà lọ́wọ́. Òun ló máa ń yanjú aáwọ̀ tó bá jẹyọ nílùú, á sì sọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ṣe sí ìṣòro náà.Àwọn Onídàájọ́ 4:4, 5.

Ilẹ̀ olókè Éfúráímù tó wà láàárín ìlú Bẹ́tẹ́lì àti Rámà ni Dèbórà ń gbé. Ó máa ń jókòó sábẹ́ igi ọ̀pẹ, á sì máa ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn bí Jèhófà bá ṣe darí rẹ̀. Iṣẹ́ yìí kò rọrùn rárá, àmọ́ Dèbórà kò jẹ́ kí ìyẹn dẹ́rù bà á. Àwọn èèyàn nílò rẹ̀ lójú méjèèjì. Kódà, ó wà lára àwọn tó ṣe àkójọ orin kan tó fi sọ nípa ìwà àìṣòótọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yan àwọn ọlọ́run tuntun. Ìgbà náà ni ogun wà ní àwọn ẹnubodè.” (Àwọn Onídàájọ́ 5:8) Jèhófà yọ̀ǹda fún àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá láti fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí pé wọ́n di abọ̀rìṣà. Jábínì Ọba Kénáánì lo ọ̀gágun Sísérà láti fòòró ẹ̀mí wọn.

Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá gbọ́ orúkọ Sísérà, ńṣe ni wọ́n á máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Ìwà ìkà tó burú jáì kún inú ẹ̀sìn àti àṣà àwọn ọmọ Kénáánì, wọ́n máa ń fi àwọn ọmọ rúbọ, wọ́n sì máa ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó nínú tẹ́ńpìlì. Báwo ni nǹkan ṣe rí nílẹ̀ Ísírẹ́lì nígbà tí ọ̀gágun ọmọ ilẹ̀ Kénáánì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ń fòòró ẹ̀mí wọn? Orin tí Dèbórà kọ fi hàn pé ó ṣòro fún wọn láti rìnrìn àjò, abúlé pàápàá kò ṣeé gbé. (Àwọn Onídàájọ́ 5:6, 7) A lè fojú inú wo bí jìnnìjìnnì ṣe máa bá àwọn tó sá pamọ́ sínú igbó, tí ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n láti lọ sóko tàbí gbé nínú abúlé tí kò ní odi. Wọ́n tún ń bẹ̀rù láti rìnrìn àjò, kí wọ́n má báa ṣe wọ́n ní jàǹbá lójú ọ̀nà, tàbí kí wọ́n jí àwọn ọmọ wọn gbé, kí wọ́n sì tún fipá bá àwọn obìnrin wọn lò pọ̀. *

Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olórí kunkun yìí ti jìyà fún ogún [20] ọdún, Jèhófà rí i pé wọ́n ṣe tán láti yíwà pa dà. Ìdí nìyẹn tí Dèbórà àti Bárákì fi kọrin pé, “Títí èmi, Dèbórà, fi dìde, títí mo fi dìde gẹ́gẹ́ bí ìyá ní Ísírẹ́lì.” Lápídótù lorúkọ ọkọ Dèbórà, àmọ́ a kò mọ̀ bóyá Dèbórà bímọ tàbí kò bí, ṣùgbọ́n bí a ṣe pè é ní ìyá jẹ́ àfiwé. Lọ́rọ̀ kan, ńṣe ni Jèhófà yan Dèbórà láti dáàbò bo ìlú náà, bí ìyá ṣe máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀. Ọlọ́run ní kó yan ọkùnrin kan tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára, ìyẹn Bárákì, láti lọ gbéjà ko Sísérà.Àwọn Onídàájọ́ 4:3, 6, 7; 5:7.

Dèbórà fún Bárákì ní ìṣírí pé kó ṣe gírí láti gba àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀

Jèhófà tipasẹ̀ Dèbórà sọ fún Bárákì pé “lọ, kí o sì tan ara rẹ ká orí Òkè Ńlá Tábórì.” Ó ní kí Bárákì kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ọkùnrin jọ látinú ẹ̀yà méjì ní Ísírẹ́lì. Dèbórà sọ fún wọn pé Ọlọ́run ti ṣèlérí pé wọ́n máa ṣẹ́gun Sísérà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án [900] kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀! Ìlérí yìí ya Bárákì lẹ́nu. Ìdí ni pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kò ní àwọn ọmọ ogun àti ohun ìjà kankan. Síbẹ̀, Bárákì gbà láti lọ ja ogun náà. Ṣùgbọ́n ó ní àfi kí Dèbórà tẹ̀ lé wọn lọ sí orí Òkè Ńlá Tábórì.Àwọn Onídàájọ́ 4:6-8; 5:6-8.

Àwọn kan pe Bárákì ní aláìnígbàgbọ́ nítorí ohun tí ó béèrè yìí, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, kò béèrè ohun ìjà ogun lọ́wọ́ Ọlọ́run. Torí pé Bárákì ní ìgbàgbọ́, ó mọ̀ pé ó máa dáa kí aṣojú Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn, kó lè fún wọn ní ìṣírí. (Hébérù 11:32, 33) Jèhófà ṣe ohun tí Bárákì fẹ́. Ó gbà kí Dèbórà bá wọn lọ. Àmọ́, Jèhófà mí sí Dèbórà láti sọ tẹ́lẹ̀ pé kì í ṣe ọkùnrin ló máa ṣẹ́gun Sísérà. (Àwọn Onídàájọ́ 4:9) Obìnrin ni Ọlọ́run máa lò láti gbẹ̀mí rẹ̀!

Lóde òní, àwọn kan máa ń rẹ́ àwọn obìnrin jẹ, wọ́n máa ń hùwà ipá sí wọn tàbí kí wọ́n ṣe wọ́n níkà. Wọn kì í buyì kún àwọn obìnrin bí Ọlọ́run ṣe fẹ́. Àmọ́, ojú kan náà ni Ọlọ́run fi ń wo gbogbo wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. (Róòmù 2:11; Gálátíà 3:28) Àpẹẹrẹ Dèbórà jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run máa ń gbé iṣẹ́ ńlá fún àwọn obìnrin, èyí jẹ́ àmì pé ó kà wọ́n sí, ó sì fọkàn tán wọn. Torí náà, kò yẹ ká máa ronú pé àwọn obìnrin kò wúlò.

“ILẸ̀ AYÉ MÌ JÌGÌJÌGÌ, Ọ̀RUN PẸ̀LÚ KÁN TÓTÓ”

Bárákì kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ọkùnrin tó ní ìgboyà jọ láti lọ kojú àwọn ọmọ ogun Sísérà tó ń dẹ́rù bà wọ́n. Bí Bárákì ṣe ń darí àwọn ọkùnrin yìí lọ sí orí Òkè Ńlá Tábórì, inú rẹ̀ dùn pé Dèbórà wà pẹ̀lú wọn láti fọkàn wọn balẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Dèbórà sì gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀.” (Àwọn Onídàájọ́ 4:10) Fojú inú wo bí ọkàn wọn ṣe máa balẹ̀ tó pé Dèbórà akínkanjú obìnrin wà láàárín wọn bí wọ́n ṣe ń gún Òkè Ńlá Tábórì lọ. Dèbórà múra tán láti fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu torí pé ó ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀!

Nígbà tí Sísérà gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbójú-gbóyà dìde ogun sí òun, lòun náà bá pa kítí mọ́ra. Àwọn ọba mélòó kan nílẹ̀ Kénáánì wá da ọmọ ogun wọn pọ̀ mọ́ ti Jábínì Ọba, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọba tó lágbára jù nínú wọn. Bí àwọn ọmọ ogun Sísérà àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun wọn ṣe ń rọ́ bọ̀, ni ariwo ẹsẹ wọn ń milẹ̀ jìgìjìgì. Àwọn ọmọ ogun Kénáánì gbà pé ọwọ́ kan làwọn máa ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.Àwọn Onídàájọ́ 4:12, 13; 5:19.

Kí ni Bárákì àti Dèbórà máa ṣe báyìí bí àwọn ọ̀tá ṣe ń sún mọ́ wọn? Tí wọ́n bá dúró sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Ńlá Tábórì yẹn, ìyẹn lè jẹ́ kí wọ́n rọ́wọ́ mú, torí pé àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun àwọn ọmọ Kénáánì kò lè gun àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ náà. Àmọ́, torí pé ohun tí Jèhófà bá sọ ni Bárákì máa tẹ̀ lé, ó ní láti dúró gbọ́ ọ̀rọ̀ látẹnu Dèbórà. Àsìkò tó báyìí! Dèbórà wá sọ pé: “Dìde, nítorí èyí ni ọjọ́ tí Jèhófà yóò fi Sísérà lé ọ lọ́wọ́ dájúdájú. Jèhófà ha kọ́ ni ó ti jáde lọ níwájú rẹ?” Lẹ́yìn náà, “Bárákì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ láti orí Òkè Ńlá Tábórì pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin lẹ́yìn rẹ̀.”Àwọn Onídàájọ́ 4:14. *

Àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì sọ̀ kalẹ̀ látorí òkè náà síbi tí ilẹ̀ ti tẹ́jú, wọ́n sì lọ dojú kọ àwọn ọmọ ogun apániláyà náà. Ǹjẹ́ Jèhófà ṣíwájú wọn bí Dèbórà ti sọ? A máa rí ìdáhùn ìbéèrè yẹn láìpẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ilẹ̀ ayé mì jìgìjìgì, ọ̀run pẹ̀lú kán tótó.” Ńṣe ni gbogbo nǹkan dojú rú fún àwọn ọmọ ogun Sísérà. Òjò bẹ̀rẹ̀ sí i ya bolẹ̀! Ọ̀gbàrà sì ń ya mù ún-mù ún, ni gbogbo ilẹ̀ bá di ẹrẹ̀. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun wọn rì sínú ẹrẹ̀, kò sì wúlò mọ́.Àwọn Onídàájọ́ 4:14, 15; 5:4.

Òjò náà kò dẹ́rù bá Bárákì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ló ń jà fáwọn. Ni wọ́n bá dojú ìjà kọ àwọn ọmọ ogun Kénáánì. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe sọ, wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọ ogun Sísérà tán pátá láìku ẹyọ kan. Òkú wọn sì kún Odò Kíṣónì débi pé odò náà kún dẹ́múdẹ́mú, ó sì wọ́ àwọn òkú náà lọ sínú Òkun Ńlá.Àwọn Onídàájọ́ 4:16; 5:21.

Bí Dèbórà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Jèhófà gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀, ó ṣẹ́gun Sísérà àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀

Lónìí, Jèhófà kì í rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ jagun. Àmọ́, ó ń fẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ máa ja ogun tẹ̀mí. (Mátíù 26:52; 2 Kọ́ríńtì 10:4) Tá a bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run nínú ayé yìí, ogun tẹ̀mí là ń jà yẹn. A nílò ìgboyà, torí pé gbogbo àwọn tó bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ló máa kojú àtakò tó le koko. Àmọ́, Jèhófà kò yí padà. Ó ṣì máa ń jà fún àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ tí wọ́n sì gbọ́kàn lé e, bó ṣe jà fún Dèbórà, Bárákì àti àwọn ọmọ ogun onígboyà tó wà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì.

“OBÌNRIN ALÁBÙKÚN JÙ LỌ”

Èyí tó burú jù lọ lára àwọn ọ̀tá náà rí ọ̀nà sá lọ, ìyẹn Sísérà ọ̀gá àwọn ọmọ ogun tó ń ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lára. Kójú má ríbi, gbogbo ara loògùn ẹ̀! Ó fi àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sílẹ̀ láti kú sínú ẹrẹ̀ níbẹ̀, ó sì yọ́ gba àárín àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì kọjá lọ sórí ilẹ̀ tó gbẹ kó lè wá ibi fara pamọ́ sí. Bó ṣe ń sáré lọ nínú pápá gbalasa, ẹ̀rù ń bà á kí ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì má tẹ òun. Ló bá kọrí sí àgọ́ Hébà, ìyẹn ọmọ Kénì tó yapa lára àwọn èèyàn rẹ̀, tó sì lọ tẹ̀dó sí apá gúúsù. Hébà àti Jábínì Ọba sì jọ mọwọ́ ara wọn dáadáa.Àwọn Onídàájọ́ 4:11, 17.

Ó ti rẹ Sísérà tẹnutẹnu nígbà tó fi máa dé ilé Hébà. Kò bá Hébà nílé, àmọ́ ó bá Jáẹ́lì ìyàwó Hébà. Sísérà wò ó pé Jáẹ́lì máa wo ti àjọṣe tó wà láàárín Hébà ọkọ rẹ̀ àti Jábínì Ọba mọ òun lára. Kò tiẹ̀ lè ronú pé obìnrin kan lè ní èrò tó yàtọ̀ sí ti ọkọ rẹ̀. Sísérà kò kúkú mọ Jáẹ́lì tẹ́lẹ̀! Jáẹ́lì ti rí bí àwọn ará Kénáánì ṣe ń ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára, ó sì rí i pé òun ní láti ṣe nǹkan sí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀. Bóyá kó dáàbò bo ọkùnrin yìí tàbí kó ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, kó sì ṣá ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run balẹ̀. Àmọ́, báwo ló ṣe máa ṣe é? Báwo ni obìnrin lásánlàsàn ṣe máa pa ọ̀dájú jagunjagun yìí?

Jáẹ́lì kò gbọ́dọ̀ fi àkókò falẹ̀. Ó sọ fún Sísérà pé kó wá sinmi. Sísérà sì pàṣẹ fún un pé kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ pé òun wà níbẹ̀. Sísérà bá dùbúlẹ̀, Jáẹ́lì sì dáṣọ bò ó mọ́lẹ̀. Sísérà sọ fún Jáẹ́lì pé kó fún òun lómi, àmọ́ wàrà ni Jáẹ́lì gbé wá fún un. Ó mú un tán ló bá sùn lọ gbári. Jáẹ́lì wá mú ohun èlò ilé kan tó dàbí ìṣó tí àwọn obìnrin tó ń gbé inú àgọ́ máa ń lò, ìyẹn ni ìkànlẹ̀ àgọ́ àti òòlù. Ó kúnlẹ̀ síbi orí Sísérà, iṣẹ́ ńlá ló délẹ̀ yìí, ó fẹ́ ṣojú fún Jèhófà láti mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣe lára Sísérà. Ewu ńlá ló máa jẹ́ fún un tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́ra níbi tọ́rọ̀ dé báyìí. Kí ló lè máa rò lọ́kàn? Ṣé bí ọkùnrin yìí ṣe ti hùwà ìkà sáwọn èèyàn Ọlọ́run fún ohun tó lé lógún ọdún ni, àbí àǹfààní tó ní láti ṣojú fún Jèhófà? Àkọsílẹ̀ náà kò sọ. Àmọ́, kò pẹ́ tó fi gbẹ̀mí Sísérà.Àwọn Onídàájọ́ 4:18-21; 5:24-27.

Lẹ́yìn náà, Bárákì wá Sísérà dé àgọ́ Hébà. Àmọ́ kó tó débẹ̀, Jáẹ́lì ti gbá ìkànlẹ̀ àgọ́ mọ́ agbárí rẹ̀, ó sì fi òkú rẹ̀ han Bárákì. Ìgbà náà ni Bárákì rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ Dèbórà ti ṣẹ. Obìnrin ló pa Sísérà akínkanjú ológun. Àwọn alárìíwísí lóde òní ti pé Jáẹ́lì ní onírúurú orúkọ, àmọ́ Bárákì àti Dèbórà mọ bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́. Nínú orin tí wọ́n kọ, Ọlọ́run mí sí wọn láti yin Jáẹ́lì, wọ́n ní ó jẹ́ “alábùkún jù lọ láàárín àwọn obìnrin,” nítorí ìgboyà tó ní. (Àwọn Onídàájọ́ 4:22; 5:24) Ẹ ò rí i pé Dèbórà kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan. Kò jowú Jáẹ́lì rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ inú rẹ̀ dùn pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣẹ.

Ní báyìí tí Sísérà ti kú, Jábínì Ọba kò lè halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́. Gbogbo gìràgìrà àwọn ará Kénáánì dópin. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ní ìfọkànbalẹ̀ fún ogójì ọdún. (Àwọn Onídàájọ́ 4:24; 5:31) Jèhófà Ọlọ́run bù kún Dèbórà, Bárákì àti Jáẹ́lì torí pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Dèbórà, tá à ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, tá a sì ń fún àwọn ẹlòmíì ní ìṣírí láti ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa jẹ́ kí àwa náà ṣẹ́gun, ọkàn wa á sì balẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 7 Àwọn míì tó tún jẹ́ wòlíì obìnrin ni Míríámù, Húlídà àti ìyàwó Aísáyà.Ẹ́kísódù 15:20; 2 Àwọn Ọba 22:14; Aísáyà 8:3.

^ ìpínrọ̀ 9 Orin tí Dèbórà kọ fi hàn pé Sísérà máa ń kó oríṣiríṣi nǹkan bọ̀ látojú ogun, títí kan àwọn ọmọbìnrin. Nígbà míì ọmọ ogun kan lè gba ju ọmọbìnrin kan lọ. (Àwọn Onídàájọ́ 5:30) “Ilé ọlẹ̀” ni ẹsẹ Bíbélì yìí pe àwọn “ọmọbìnrin” tí wọ́n bá kó lẹ́rú. Èyí fi hàn pé torí kí wọ́n lè bá wọn lò pọ̀ ni wọ́n ṣe ń kó wọn lẹ́rú. Ìdí nìyẹn tí ìfipábánilòpọ̀ fi wọ́pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ náà.

^ ìpínrọ̀ 17 Ìgbà méjì ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ogun yìí. Àkọ́kọ́ wà nínu ìwé Àwọn Onídàájọ́ orí 4, èkejì sì wà nínú orin tí Dèbórà àti Bárákì kọ ní orí 5. Ńṣe ni orí méjèèjì yìí so kọ́ra torí pé ọ̀kọ̀ọ̀kan ṣe àlàyé tí èkejì kò ṣe.